Assistant Commissioner of Police: Àwọn afurasí ṣá ìgbákejì kọmísọ́nà ọ̀gá ọlọ́pàá láàké dójú ikú

ỌLỌPAA

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police force

Iroyin ti jade awọn afurasi kan ti fi aake ṣa igbakeji kọmisọna ọlọpaa, ACP. Egbe Eko Edum, to jẹ oludari to wa ni No. 73 PMF Squadron, Magumeri ni ipinlẹ Borno

ACP Egbe Eko Edum ni kọmisọna to n ṣakoso No. 73 PMF Squadron, ni agbegbe Magumeri.

Ikọlu naa waye lafẹmọjumọ Ọjọbọ ọjọ keji oṣu kejila ni nkan bii ago kan oru ọganjọ lopopona Murtala Mohammed Highway lẹbaa ileeṣẹ Pepsi.

Iroyin sọ pe igbakeji ọlọpaa to n ṣiṣẹ ni ipinlẹ Borno n bọ lati ilu Calabar nibi to ti lọ ṣebẹwo si awọn mọlẹbi rẹ nigba ti ọkọ rẹ dede taku lẹgbẹ ọna to si n gbiyanju lati pe awọn mọlẹbi rẹ lori ẹrọ ibanisọrọ pe ki wọn wa gbe e, lasiko yii gan ni awọn kan ṣaadede kọ lu u ti wọn si ṣa a laake pa.

Àkọlé fídíò, 'Ọkọ mi wa ọkọ̀ tẹ "Poly Bag" lásán, àfi gbùùàà! Àdó okoró búrẹ́kẹ'

Nigba ti awọn oniroyin kan si alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Irene Ugbo ni "bi emi naa ṣe gbọ iroyin naa ree mo si n mura ati jade kuro nile lati lọ fidi ọrọ naa mulẹ ni ọfiisi rẹ".

Amọ o ni eeyan kan ṣẹṣẹ pe oun ni to sọ fun oun pe iru nkan bẹẹ ṣẹlẹ.

Nigba ti wọn bere orukọ igbakeji kọmisọna naa, alukoro ọlọpaa ni nkan ṣoiṣo ti oun gbọ ni pe wọn ṣa a lada; "mi o mọ orukọ rẹ, iwadii kikun yoo si bẹrẹ laipẹ".

Ẹwẹ, ṣe ni awọn olugbe adugbo naa dede taji sinu ipaya pẹlu bi awọn ọkọ to taku ṣe pọ loju titi pẹlu ẹjẹ lara awọn ọkọ naa.

Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, wọn ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si.