Soun Ogbomoṣo pàdánù ọmọkùnrin rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Inside Oyo
Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ, Alayeluwa Ọba, Alhaji Dr. Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungnade III, ti padanu ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Alufa Olumide Oyewumi.
Ọmọọba Oyewumi re ibi agba n re l'ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2020 lẹyin aisan ranpẹ.
Ẹwẹ, Minisita fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya lorilẹede yii, Arakunrin Sunday Dare ti ba Ọba Alade naa kẹdun lori ipapoda ọmọ rẹ.
Ninu atẹjade ti wọn fi lede, Minisita naa ni, "Mo gbọ iroyin ijaya to ba ni ninu jẹ nipa ipapoda Alufa Olumide. Adanu nla ni iku ẹni ti o jẹ awokọṣe rere fun awọn ọdọ naa jẹ.
O jẹ ẹnikan ti mo mọ gẹgẹ bi i oniwa pẹlẹ ati aladura nigba aye rẹ. Ki Eleduwa ba wa tẹẹ si afẹfẹ rere".
Dare tun gba adura pe ki Ọlọrun tu awọn eeyan oloogbe naa ati gbogbo eeyan ilu Ogbomọṣọ ninu lori iku ojiji naa, gẹgẹ bi o ṣe n tọrọ ẹmi gigun ati itunu fun Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ.















