Katsina Child sale: Obìnrin olówònààbì ta ọmọ rẹ̀ tuntun jòjòlò ní N300,000

Oríṣun àwòrán, KATSINA POLICE COMMAND
Ọwọ sinku ọlọpaa ti tẹ obinrin olowo naabi to ta ọmọ oṣu mẹrin fun iye owo to to ẹgbẹrun lọna ọọdunrun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọwọ awọn tẹ Zainab Justina Adamu to jẹ ẹni ọdun marundinlọgbọn to gbimọ pọ pẹlu ọrẹ rẹ Ruth Kenneth lati ta ọmọ rẹ jojolo.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Katsina, Gambo Isah ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Kofar Kaura Layout, nipinlẹ Katsina.
- Oluwatobi Adeigba, Ọkọ mi ń lọ siṣẹ́ fún àjọ INEC ló kàgbákò ikú - Opó Adeigba
- Ìdí tí a fi pa àwọn àgbẹ̀ onírẹ̀sì ní Borno, Boko Haram ṣàlàyé nínú fídíò tuntun
- Èèyàn 281 ló kó covid-19 lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, 123 wá láti ìpínlẹ̀ Eko nìkan
- Wọ́n ti rẹ ipò ọ̀gágun Olusegun Adeniyi sílẹ̀ lẹ́yìn tó jẹ̀bi títú àṣírí kùdiẹ-kudiẹ iléeṣẹ́ ológun lórí ayélujára
Iwadii fihan pe o fẹ ta ọmọ naa fun arabinrin Chinwindi Omeh to n gbe ni ilu Anambra.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ri iye to to ẹgbẹrun lọna marundinlaadosan to jẹ owo to ṣẹku lara owo ti wọn gba lẹyin ti wọn ta ọmọ naa.










