General Adeniyi video: Iléeṣẹ́ ológun rẹ ipò ọ̀gágun Olusegun Adeniyi sílẹ̀ lẹ́yìn tó jẹ̀bi títú àṣírí kùdiẹ-kudiẹ rẹ̀ lórí ayélujára

Segun Adeniyi

Oríṣun àwòrán, @News_Channel247

Ile ẹjọ awọn ologun kan niluu Abuja ti sọ pe adari ikọ ọmọ ogun Naijiria si ipinlẹ Bornu labẹ asia Operation Lafia Dole, Ọgagun Olusegun Adeniyi jẹbi ẹsun titu aṣiri kudiẹ-kudiẹ ileeṣẹ ologun lori ayelujara.

Ile ẹjọ naa sọ pe bi ọgagun Adeniyi ṣe ke gbajare ninu fidio kan to lu sita lori ayelujara tako ilana ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria.

Lẹyin naa lo ni ki wọn rẹ ipo rẹ silẹ nile iṣẹ ọmọ ogun ni wọn ọdun mẹta ṣeyin.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Adeniyi farahan ninu fidio kan lawọn oṣu diẹ sẹyin, nibi to ti ke si awọn lọgalọga nileeṣẹ ọmọ ogun pe ki wọn gba awọn sọja sile nitori bi awọn ẹgbẹ agbesumọmi ṣe n pa wọn ni ipakupa.

Ninu fidio ọhun lo ti ba awọn ọga rẹ rẹ sọrọ pe awọn ọmọ ogun ti oun ko sọdi ko jaya, wọn si n doju ija kọ awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram, bẹẹ ni wọn ko si sa kuro loju ogun.

Ile ẹjọ ọhun ṣe ẹjọ Adeniyi pẹlu amugbalẹgbẹ rẹ, Tokunbo Obanla, ti wọn sọ pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ti wọn si ni ko lọ fi ẹwọn jura fun ọjọ mejidinlọgbọn pẹlu iṣẹ aṣekara.

Iroyin ni Adeniyi sọ fun ile ẹjọ naa pe oun gba pe lootọ ni oun jẹbi ẹsun mẹta ti wọn fi kan oun, lara eyii ti aṣilo oju opo ayelujara wa.

Ileeṣẹ ologun ṣe idajọ Adeniyi lẹyin oṣu mẹjọ ti fidio naa lu sori ayelujara, nibi to ti sọrọ pe awọn ọmọ ogun to wa lẹyin oun ko ni irinṣẹ to to lati kọju ija si awọn ẹgbẹgun Boko Haram.

Bakan naa lo tun sọ ninu fidio ọhun pe oun ija awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram pọ, o si tun lagbara ju ti awọn ikọ ọmọ ogun Naijiria lọ.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oṣù tí òjò kò rọ̀ ní orílẹ̀èdè Cuba, Ọba ilẹ̀ Yorùbá ló

Fidio naa ko dun mọ ileeṣẹ ologun ninu, ko si pẹ si asiko naa ti wọn fi iwe gbe kuro ni oju ija ọhun.

Ṣugbọn Adeniyi sọ pe oun ko ṣe ohun ti ko dara, ati pe oun kọ lo gbe fidio naa jade lori ayelujara bo tilẹ jẹ pe o ti kọkọ sọ pe aṣiṣẹ ni oun fi gbe fidio naa jade si ojukaye.

Ẹwẹ, agbẹjọro ọgagun naa ti sọ pe oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lodi si idajọ ọhun.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí wọ́n sọ nípa Owa Ale ìlú Ikare, Ọba Samule Kolapo Adegbite Adedoyin tó wàjà