Olufon ti Ifon Murder: Àwọn agbébọn tó pá Olufon ti Ifon ti ṣe ohun èèwọ̀ ní ilẹ̀ Yoruba

Gomina Akeredolu ati Olufon ti Ifon, Ọba Isreal Adewusi

Oríṣun àwòrán, flashinfoNg12/twitter

Awọn lọbalọba nipinlẹ Ondo ti ni ohun eewọ ni awọn agbebọn to ba Olufọn ti Ifọn, Oba Isreal Adeusi ṣe lẹyin ti yinbọn pa.

Awọn lọbalọba naa sọrọ gba ẹnu alaga awọn lọbalọba nipinlẹ Ondo, Ọba Frederick Akinruntan to jẹ Olugbo ti Ugbo.

Oba Akinruntan ṣe apejuwe iṣekupani Oba Adeusi gẹgẹ bi ohun to bani ninu jẹ, ti awọn si tako patapata.

Oba Akinruntan ni iṣeeṣe awọn lọbalọba lorilẹede ko di atẹmẹrẹ nitori eto aabo to dẹnukọlẹ lorilẹede Naijiria.

Oba Olugbo ti Ugbo wa rọ Gomina Oluwarotimi Akeredolu lati lo gbogbo ohun to wa ni ikawọ rẹ lati gbogun ti awọn aṣekupani ni ipinlẹ Ondo.

O rọ Gomina Akeredolu lati pese eto aabo fun awọn lọbalọba lati ri wi pe iru iṣẹlẹ yii ko waye mọ.

Oba Akinruntan wa gbadura fun awọn iyawo, ẹbi ati ọrẹ ti Ọba Olufon fi silẹ, wi pe iru ibanujẹ bẹẹ ko ni kangun si wọn mọ.

Awọn agbebọn yinbọn lu Oba Adeusi ni agbegbe Elegbeka ni opopona Owo-Ifọn ni ipinlẹ Ondo.

Amọ, ẹpa ko boro mọ nitori nigba ti yoo fi de ileewosan ijọba ni Owo, Oba ti tẹri gbasọ.

Wo ohun tí Ọọ̀ni, Sultan Sokoto sọ nípa ọta ìbọn tó gbẹ̀mí Ọba Olúfọ́n

Awọn ọbalaye kanrinkanrin meji lorilẹede Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu bi ọrọ abo ṣe dẹnukọlẹ lorilẹede Naijiria eyi to ṣokunfa iṣekupa ọbaalaye, Olufọn ti ilu Ifọn-Owo ni ipinlẹ Ondo.

Ọọniriṣa, Alayeluwa Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja II ati Sultan ti ilu Sokoto, Sa'ad Abubakar kẹta ṣalaye pe ohun to banininu jẹ gidi ni pe awon avbenipa lee gba ẹmi ọbalaye lorilẹede Naijiria.

Nibi idanilẹkọ kan ti wọn fi sọri ayẹyẹ ọdun karun Ọọni Ogunwusi lori itẹ, eyi to waye nilu Ibadan ni wọn ti sọrọ yii.

Bakan naa ni wọn tun duro idakẹjẹ iṣẹju kan ni iranti Ọbaalaye naa, kabiyesi Olufọn ti ilu Ifọn-Ọwọ,

Gomina Akeredolu ati Olufon ti Ifon, Ọba Isreal Adewusi

Oríṣun àwòrán, flashinfoNg12/twitter

Àràbà nlá tó wó nípìnlẹ̀ Ondo jẹ́ ká mọ̀ pé inú ìpèníjà ètò ààbò tó kọjá ojú lásán la wà - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo

Ijọba ipinlẹ Ondo ti kẹdun iṣẹlẹ to waye ni agbegbe Elegbeka, ni oju ọna Ifon si Owo.

Ninu atẹjade ti Kọmisanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ, Donald Ojogo, fi sita, o fidirẹ iṣẹlẹ sọ pe àràbà nla kan lo wo ninu iṣẹlẹ naa.

O ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ọgbẹ to wọ to jin, to si jẹ ibanujẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ naa "yoo bọwọ fun aṣa ati iṣe ilu naa, ti ko si ni sọ nkankan nipa orukọ àràbà nla to wo nipinlẹ naa", iroyin to n lọ nipe Olufon ti Ifon, Ọba Isreal Adewusi ni awọn afurasi ajinigbe pa.

Bakan naa lo ni Gomina Rotimi Akeredolu, ati awọn olori ijọba kan ti ṣe abẹwo si agbegbe naa, lati ba wọn kẹdun.

Olufọn

Oríṣun àwòrán, Other

Ijọba ipinlẹ Ondo sọ pe iṣẹlẹ naa tọka si pe ipenija eto aabo to kọja oju lasan, lo n ba 'wa' finra.

"Eyi to si n pe fun igbesẹ to tayọ."

Alẹ Ọjọbọ ni iroyin naa jade sori ayelujara.

Iroyin sọ pe lasiko ti ọba naa nn pada si ilu rẹ, lẹyin ipade awọn lọba-lsba to lọ fun nilu Akure, ni awọn ajinigbe naa kọlu.

A gbọ pe ni agbegbe Elegbeka, ni awọn agbebọn naa ti jade lati inu igbo, ti wọn si yinbọn mọ ọkọ rẹ laimọye igba.

Boti lẹ jẹ pe ao ti mọ koko bi ọrọ ṣe jẹ, iroyin sọ pe awọn ajinigbe naa bẹrẹ si ni yinbọn ọkọ rẹ, lati da a duro.

Awọn miran sọ pe bi ọkọ Kabiesi ṣe n lọ, ni awọn afurasi ajinigbe naa da ọkọ duro, amọ awakọ rẹ to fura si wọn gbiyanju lati salọ. Eyi si lo mu wọn bẹrẹ si ni yinbọn mọ ọkọ naa.

Lara awọn ọta ibọn ti wọn yin lo ba Kabiesi.

Wọn gbe e de ileewosan ijọba apapọ to wa nilu Owo, nibi to ti dagbere faye.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Ijinigbe jẹ nkan to n waye ni ipinlẹ Ondo, lati bi ọdun diẹ.