Ondo Kidnap: Ọlọ́pàá ní ìyàwó adarí òṣìṣẹ́ Ondo tì gba òmìnira lẹ́yìn ọjọ́ méjì ní páńpẹ́ àwọn agbébọn

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @OndoFirstBorn

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo lawọn ti ribi doola ẹmi iyawo adari oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo to wa ni ọdọ awọn ajinigbepawo.

Ọjọ meji gbako ni Arabinrin Ale ati arabinrin kan ti wọn ko darukọ rẹ lo nigbekun awọn alaburu yi.

Alukoro ọlọpaa Teo-Leo Ikoro ṣalaye fun BBC pe awọn ọlọpaa pẹlu fijilante ni wọn jijọ ṣawari awọn meji wọn yi.

O tun ṣalaye pe awọn ko san owo ẹmi fawọn ajinigbe naa nitori wọn salọ ni nigba ti wọn ri pe awọn agbofinro ti n sunmọ awọn.

''Awọn mejeeji ta doola wa lalaafia ti wọn si ti pada sọdọ mọlẹbi wọn.Ninu igbo tawọn aṣebi yi gbe wọn lọ la ti ri wọn.''

Lọjọbọ ni awọn ajinigbe wọn yi da ọkọ arabinrin Ale lọna lopopona Ondo-Akure nigba ti wọn dari pada si Akure lati Eko.

Ninu ọrọ rẹ Leo sọ pe inu awọn dun pe awọn ko doju ija kọ awọn ajinigbe yi nitori o le ṣakoba fẹmi awọn ti wọn ji gbe.

Kí ilẹ̀ òní tó ṣú, ìyàwó adarí òṣìṣẹ́ nípìnlẹ̀ Ondo tí wọ́n jígbé yóò padà wálé- Ọlọ́pàá Ondo

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti fi da awọn eniyan loju wi pe ki ọjọ oni to pari awọn a doola ẹmi iyawo adari awọn oṣiṣẹ ti wọn jigbe lọ pada.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Teo-Leo Ikoro lo sọ bẹẹ fun BBC News Yoruba lasiko ifọrọwanilẹuwo lori iṣẹlẹ ijinigbe naa.

Ikoro ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Owena ni ipinlẹ Ondo, eleyii to sunmọ ibugbe awọn ologun ni ipinlẹ Ondo.

''Ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn agbebọn naa dasi wọn lọna, ti wọn si gba ọkọ lọwọ wọn pẹlu awọn to wa ninu ọkọ''

''Awọn meji jajabọ ninu ọkọ naa, ti wọn si pe ọlọpaa.''

''Lẹsẹkẹsẹ ni awọn ọlọpaa ati soja ti tọ ipaṣẹ awọn ajinigbe naa lọ, amọ wọn ti sa wọ inu igbo rere''

''Nibayii, awọn ọlọpaa pẹlu awọn ikọ ọmọogun to wa ni ipinlẹ Ondo ti n wa wọn, to si da wa loju pe ki ilẹ oni to ṣu wọn yoo gba itusilẹ''

Ni Ọjọbọ oṣẹ yii ni iroyin gbe e pe awọn ajinigbe ti ji ọkan lara awọn iyawo Adari Oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo, Arakunrin Olugbenga Ale lọ lasiko to n bọ lati ilu Eko to ti lọ ra ọja.

Àwọn ajínigbé ti jí ìyàwó adarí òṣìṣẹ́ nípìnlẹ̀ Ondo, Olugbenga Ale gbé lọ ní Owena

Ọkan lara awọn iyawo Adari Oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo, Arakunrin Olugbenga Ale ni awọn agbebọn ti jigbe lọ nipinlẹ Ondo.

Odaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arabinrin naa ni awọn agbebọn dasi ni agbegbe Owena, ni opopona Ondo si Akure lasiko ti oun ati obinrin miran to wa ninu ọkọ rẹ n bọ lati ipinle Eko ti wọn ti lọ ra ọja.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni alẹ Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti awọn agbebọn naa pa ọba Olufọn ti Ifọ ni agbegbe Elegbeka ni opopona Ọwọ si Ifọn.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ọkan lara awọn to wa ninu ọkọ naa to jẹ obinrin sa mọ awọn ajinigbe naa lọwọ.

Bakan naa ni wọn wi pe awọn ajinigbe naa yọnda awakọ ọkọ iyawo adari oṣiṣẹ nipinlẹ Ondo naa.

Wọn fikun wi pe Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu mọ nipa iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti lọ si ranṣẹ ibanikẹdun si wọn ni ile wọn.

Ọlọ́pàá dóòlà ẹ̀mí èèyàn 10 nínú àwọn 16 tí ajínigbépawó jí gbé l'Óǹdó

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni ọwọ awọn ti tẹ afurasi ajinigbepawo mẹrin, ti awọn si doola ẹmi awọn eeyan mẹwaa ninu eeyan mẹrindinlogun ti wọn ji gbe nipinlẹ naa.

Ile ise ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijinigbe ti a n wi yi waye l'Ọjọbọ ni opopona marose Akure si Owo gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa Ondo, ọgbẹni Tee-Leo Ikoro ṣe sọ .

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, o ṣalaye pe lootọ lawọn eeyan mẹrindinlogun ti ọkunrin ati obinrin si wa ninu wọn ko si ọwọ awọn ajinigbe wọnyi.

Ikoro ni ''A ti mu eeyan mẹrin ti a fura si pe wọn mọ si iṣẹlẹ yi; ti a si tun doola ẹmi awọn mẹwaa ti wọn ji gbe. O ku eeyan mẹfa ti a ko ti ri ninu wọn''

Awọn iwe iroyin Naijiria kan jabọ pe awọn ti o kagbako awọn ajinigbe wọnyi n dari bọ pada lati ipade oloṣooṣu awọn iyalọja Akure ni.

Ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe ninu awọn ti wọn ji gbe ni iyalọja Isua Akoko, arabinrin Helen Edward wa.

Nigba ti BBC beere lọwọ Leo-Ikoro boya lootọ ni iyalọja naa wa lara awọn ti wọn ribi doola o ni oun ko le sọ pato nitori awọn ti ọlọpaa doola pọ.

''Ati ọkunrin ati obinrin la ribi doola. Mi o mọ boya ẹni ti wọn n pe ni Iyalọja wa lara wọn ṣugbọn mo maa ṣe iwadii lori rẹ''

Alukoro ọlọpaa ni awọn ṣi n gbiyanju lati ṣawari awọn eeyan mẹfa to ku.

Àkọlé fídíò, 'Bí aya bá kọ ọkọ rẹ̀ silẹ̀, kó wà láì lọ́kọ̀'