EndSARS Protest Update: Sowore ní ikọ̀ ọlọ́pàá yìnbọn fún òun lọ́jọ́ Ajé

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oludije fun ipo aarẹ Naijiria ninu eto idibo gbogboogbo to waye lọdun 2019, Omoyele Sowore, ti pariwo sita lori ayelujara pe, awọn kan n lepa ẹmi oun.

Ninu ọrọ kan to kọ si oju opo twitter rẹ ni alẹ Ọjọru lo ti sọ pe, oun ri iroyin gbọ pe ileeṣẹ eleto abo ni Naijiria ti kede pe, wọn gbọdọ mu oun tabi pa oun laarin wakati mẹrinlelogun si asiko yii, nitori pe oun ko ni gba ki wọn fi ofin gbe oun.

O ni olu ileeṣẹ ologun nilu Abuja, ni igbesẹ naa ti fẹ ẹ waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A mọ ki ẹ mọ pe eyi ko ni i di ijagbara fun ominira lọwọ."

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

O fikun pe ikọ ọlọpaa to wa nile asofin apapọ ilẹ wa sina ibọn fun oun lọjọ Aje, ti wọn si tun ji ọkan lara ọkọ ayọkẹlẹ oun lọ.

O ni wọn fi aake kọri lati da ọkọ naa pada lai naani pe oun fi n sisẹ iroyin ni, ti Kọmisana ọlọpaa nilu Abuja, Bala Ciroma si sọ fun oun pe ọkọ naa huwa ọdaran ni, ti wọn yoo si gbe lọ sile ẹjọ eyi to ba oun lojiji.

"Laarin ọsẹ kan pere, awọn alatilẹyin wọn kọ oniruuru atẹjade sita, wọn kọwe sawọn ileesẹ asoju ilẹ okeere lorisirisi.

Awọn oluwọde ENDSARS

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore

Koda, ileesẹ itẹwe The Nation gan ni awọn ojulowo oluwọde EndSARs fẹ ki wọn ti mi mọle, ti ileesẹ ologun gan si ni awọn alasọdun loju opo Twitter, ti wọn n kede pe pipa lo yẹ ki wọn pa mi."

Sowore wa figbe bọnu pe, iditẹ mọ oun ti doju rẹ bayii lati bii ọsẹ diẹ sẹyin, ti wọn si ti ransẹ sawọn ileesẹ agbofinro, eyi ti asiri rẹ tu si oun lọwọ.

O ni eyi ko sẹyin ijọba aarẹ Muhammadu Buhari, ẹni to ti n dunkooko mọ oun lati ọsẹ diẹ, paapa lati igba ti iwọde EndSARS ti bẹrẹ.

Agbẹjọ́ro ọ̀dọ́ sọ́rọ́ ilẹ̀ kún nìjókòó ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́ro ọ̀dọ́ fèsì níbi ìjókòó ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí ìfìyàjẹni nìpínlẹ̀ Eko

Ọkan lara awọn ti banki apapọ Naijiria, CBN, gbẹsẹ le apo asunwọn wọn nile ifowopamọ, Adegoke Pamilerin, sọ pe o ti le ni ọsẹ meji ti oun ko ti le ṣe ohunkohun lori apo asunwọn wọn.

Ninu ọrọ kan to kọ sori ayelujara Twitter, o ni ṣaaju aṣẹ ile ẹjọ ni wọn ti gbẹsẹ le apo asunwọn naa.

Ọjọ Ẹti ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abuja paṣẹ pe ki banki naa gbẹsẹ le apo asunwọn eeyan mọkandinlogin ati ileesẹ kan, fun ipa ti wọn ko ninu iwọde ENDSARS to waye l'oṣu Kẹwaa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ile ẹjọ paṣẹ fun CBN lati gbẹsẹ le e titi di oṣu Kinni, ọdun 2021.

Gẹgẹ bi akọsilẹ idajọ naa ṣe fihan, Onidajọ Ahmed Mohammed lo fun CBN ni aṣẹ naa, ogunjọ oṣu Kẹwaa, si ni banki apapọ ọhun gbe iwe ẹbẹ lọ sile ẹjọ.

Oṣu to kọja ni iwọde #ENDSARS waye ni awọn ipinlẹ kan ni Naijiria, ati nilẹ okeere, eyi to mi ilẹ jakejado.

Iwọde naa ni ọpọlọpọ ọdọ ni Naijiria fi polongo fun fifi ofin de ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale, Special Anti-Robbery Squard, SARS.

Awọn ẹsun ifiyajẹni, ipaniyan, ati iwa ilọnilọwọ gba ni wọn fi kan awọn ọlọpaa SARS.

Awọn oluwọde ENDSARS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwọde naa ti kọkọ n lọ ni irọwọ-rọsẹ, ko to o dipe awọn janduku ja a gba kaakiri awọn ipinlẹ to ti n waye.

Koda, wọn dana sun awọn ileeṣẹ ọlọpaa, ile itaja, ati ọkọ ni awọn ipinlẹ bi Oyo, Eko, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Awọn kan lara wọn si tun ko awọn oniṣowo ni ẹru lọ lẹyin ti ijọba kede konile-o-gbele.

Àkọlé fídíò, Àwọn jàndùkú ṣe yabò àwọn olùwọ́de #ENDSARS ní Alausa l'Eko

Awọn ti banki apapọ gbẹsẹ le apo aṣunwọn wọn niyii:

•Bolatito Rachael Oduala

•Chima David Ibebunjoh

•Mary Doose Kpengwa

•Gatefield Nigeria Limited

•Saadat Temitope Bibi

•Bassey Victor Israel

•Wisdom Busaosowo Obi

•Nicholas Ikhalea Osazele

•Ebere Idibie

•Akintomide Lanre Yusuf

•Uhuo Ezenwanyi Promise

•Mosopefoluwa Odeseye

•Adegoke Pamilerin Emmanuel

•Umoh Grace Ekanem

•Babatunde Victor Segun

•Mulu Louis Teghenan

•Mary Oshifowora

•Winifred Akpevweoghene Jacob

•Victor Solomon

•Idunu A. Williams

Kini aṣẹ ile ẹjọ sọ lori apo asunwọn wọn?

Ile ẹjọ paṣẹ fun awọn banki pe ko gbọdọ si sisan owo wọle tabi gbigba owo jade ninu apo asunwọn ogun to wa ninu iwe ẹbẹ ti CBN kọ sile ẹjọ.

Ọgọsan ọjọ si ni awọn eeyan naa ko fi ni i ni anfaani si apo asunwọn wọn, titi CBN yoo fi pari iwadii ati ayẹwo to n ṣe.

Awọn banki bi i of Access, Fidelity, First Bank Nigeria, Guaranty Trust Bank, United Bank of Africa, ati Zenith, ni ile ẹjọ fi iwe aṣẹ ranṣẹ si i.

O si tun sun igbẹjọ lori ọrọ naa si ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun 2021.

Bakan naa lo sọ pe ẹnikẹni ti aṣẹ naa ba bawi, le kọwe sile ẹjọ lati gbọ awijare rẹ.