Buhari Fake Wedding: Ilé ẹjọ́ ní fọ́nrán àwòrán náà dá ìjà sílẹ̀ nínú ẹbí ààrẹ

Ọkùnrin tó ṣe fọ́ran ìgbéyàwó òfégè ààrẹ Buhari ti d'èrò ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Buhari/instagram

Wọ́n ti pe ọkunrin ti wọ́n fẹ̀sùn kan pé, ó ń gbé iròyìn ofégé pẹ̀lú fọ́nran àwòrán tó ń pín kiri pé, ààrẹ Buhari fẹ́ ṣe ìgbéyàwó.

Wọ́n pe ọkunrin náà sí Ilé ẹjọ́ kan ní ìpínlẹ̀ Kano lórí ìtànkálẹ̀ ìròyìn òfégè pé, ààrẹ̀ Muhammadu Buhari yóò ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó pẹ̀lú mínísítà obìnrin nínú ìjọba rẹ̀.

Fọ́nran náà ṣe àfihàn ààrẹ àti mínísítà tó n rí sí ètò ìrànwọ́ ará ìlú, Sadiya Umar Farouq àti ààrẹ Buhari, tí wọn ń ṣe ìgbéyàwó.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Láti oṣù kínní ọdún ni ilé iṣẹ́ ọ̀tẹ́lẹ̀múyẹ́ tí mu Kabiru Mohammed sùgbọ́n wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbe lọ sí ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ Iṣegun ni.

Àkọlé fídíò, Sickle Cell In Nigeria: Makinde ní ìgbàgbọ́ ninú ìdílé òun ṣèdíwọ́ láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀

Ilé iṣẹ́ ọ̀tẹ̀lẹ̀múyẹ́ ni lóòtọ́ ni Kabiru gba pe òun lòun ṣe fọ́nran náà jáde, ní bi tó ti sàfihan ìgbéyàwò láàrìn àarẹ àti obinrin náà.

Ilé ẹjọ́ ní, fọ́nran òfégè náà ba àwọn ènìyàn tọ́rọ̀ náà kàn lórúkọ jẹ́ , tí ó sì ti fa èdè àìyedè láàrìn ẹbi wọn àti ọ̀rẹ́.

Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà ní kí ilé ẹjọ́ maa gba onídùróó fún Mohammed títí tí ìwádìí àwọn yóò fi pari àti tí àwọn yóò fi rí ìmọ̀ràn gbà láti ilé iṣẹ́ tó n rí sí ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tí ìpińlẹ̀ Kano.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Sùgbọ́n ilé ẹjọ́ tí gba onídùró olùjẹ́jọ́ lẹ́yìn ti agbẹjọ́rò sàlàyé pé, ó ní ẹtọ́ láti gba oníduro nítori irú ẹ̀sùn tíwọ́n fi kàn.

Wọ́n ti wá sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ sí ọjọ́ kaarùn, oṣù kejì, ọdún 2021.