Alaafin Oyo: Níbo ni Olorí Anu àti Dami wà?

Olori Anu ati Olori Dami

Oríṣun àwòrán, Instagram/Queen Anu/Queen Dami

Iroyin kan to n lọ lori ayelujara ni pe, olori meji tun ti kuro ni aafin Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta.

A gbọ pe meji lara awọn 'ẹlẹ daddy' ọhun, Olori Damilola ati Olori Anu, lo sa kuro ni aafin Oyo.

Ohun ti iroyin naa sọ ni pe Olori Damilola, to jẹ iyawo kekere, lo tapa si ọkan lara awọn ofin to de ihuwasi wọn ni aafin, eyi to mu ki wọn o ti i mọ yara ibawi to wa ninu aafin Oyo.

Ko tan sibẹ o, iroyin naa sọ pe fun bi ọsẹ kan ni Olori Damilola, to bi ibeji fun alaafin, fi wa ninu ẹwọn naa, to si jẹ pe gbogbo dukia rẹ ni wọn gba lọwọ rẹ.

Ko si aworan ikini ku ayẹyẹ ọjọ ibi fun Alaafin loju opo Instagram Olori Anu, amọ o wa ni oju opo ti Dami

Oríṣun àwòrán, Instagram/officialqueen_dami

Àkọlé àwòrán, Ko si aworan ikini ku ayẹyẹ ọjọ ibi fun Alaafin loju opo Instagram Olori Anu, amọ o wa ni oju opo ti Dami

Bakan naa ni iroyin sọ pe, lọgan ti wọn fun ni ominira, lo sa kuro ni aafin pẹlu akẹẹgbẹ rẹ, Olori anu, ti wọn si sa lọ si ipinlẹ Eko.

Koda, iroyin sọ pe aarin oru ni wọn fi sa kuro nilu Oyo lọ si Eko.

Lootọ ni BBC Yoruba ko ti i le sọ pato otitọ to wa ninu iroyin yii, amọ awọn akiyesi kan ti a ri lori ayelujara Instagram Olori Anu re e:

Iyatọ to ba oju opo Instagram olori Anu lẹyin iroyin pe o kọ Alaafin:

  • Ayẹwo si oju opo naa fihan pe, ko si aworan kankan to ya pẹlu Ọba Adeyẹmi, tabi ti kabiesi nikan, mọ loju opo naa (Gbogbo awọn olori lo ni aworan Alaafin si oju opo ayelujara wọn).
  • Ko si ikini ayẹyẹ ọjọ ibi, paapaa fun Oba Adeyemi nibẹ, nitori ọsẹ mẹta sẹyin ni ọjọ ibi Kabiesi, ti ko si han pe Olori Anu ki Kabiyesi ku ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ gẹgẹ bi awọn olori yoku ti se.
  • Awọn ọrọ kan to n kọ sori ayelujara rẹ lẹnu ọjọ mẹta yii n jọ ti ẹni to ti la oriṣiriṣi nkan ti ko dara kọja, to si n fi ọrọ tu ara rẹ ninu, ni ireti pe ọjọ ọla yoo dara.
  • Bẹ ba si ranti, bi Olori Badra naa se maa n kọ ọrọ itunu soju opo ayelujara rẹ naa ree lasiko to la rogbodiyan kọja ni Aafin Oyo.
  • Yatọ si eyi, a tun ṣakiyesi pe imura rẹ ti yatọ si ti tẹlẹ, pẹlu awọn aworan to n fi sita bayii, nitori awọn asọ to fi bi igun ara rẹ se ri lo n wọ, ti ko we gele sori mọ gẹgẹ bi ayaba.
Olori Anu

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen Anu

Idahun Olori Anu fun BBC Yoruba lati mọ boya o si wa laafin Oyo abi o ti kuro:

Awọn arigbamu yii lo mu ki BBC Yoruba kan si Olori Anu lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ, lati fi idi ootọ ọrọ nipa iroyin yii to n lọ lori ayelujara mulẹ, lati mọ boya o si wa ni aafin Oyo abi o ti kuro.

Nigba to n dahun ibeere wa lori aago, Olori Anu sọ pe ọrọ igbesi aye oun ni, ati pe oun ko ni ohunkohun sọ nipa iroyin naa.

O ni "ọrọ igbeyawo mi pẹlu Alaafin ni, ko kan ẹnikẹni, ọrọ ara mi ni."

Bẹẹ ba si gbagbe, BBC Yoruba ti se ifọrọwanilẹnuwo ri fun Olori Anu, ẹni to yonbo Ọba Adeyemi pupọ, to si ni o n kẹ oun loju-nimu, eyi ti ọdọkunrin miran ko le se.

O ni ifẹ nla lo wa laarin oun ati Ọba naa, ti oun ko si kabamọ rara pe oun fẹ Alaafin, tii se ẹni ọdun mejilelọgọrin ni ọkọ.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Ni ti Olori Dami, a ko ṣakiyesi ayipada kankan loju opo Instagram rẹ.

Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni iroyin nipa igbeyawo rẹ pẹlu Alaafin jade sita, bo tilẹ jẹ pe o ti n gbe ni aafin tipẹ, to si ti bi ọmọkunrin kan fun baba.

Olori Dami

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen_Dami

Olori akọkọ to kuro ni aafin Oyo lọdun 2020:

Ṣe ẹ o gbagbe pe ninu ọdun 2020 yii kan naa, ni iroyin sọ pe, wọn ti le ọkan lara awọn olori alaafin to gbajumọ julọ lori ayelujara, Olori Badirat, kuro ni aafin.

Ẹsun ti iroyin sọ pe wọn fi kan nigba naa ni pe, o n ni ifẹ ikọkọ pẹlu gbaju-gbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde, K1.

Bo tilẹ jẹ pe Badirat tabi aafin ilu Ọyọ ko fi idi iroyin naa mulẹ titi di asiko yii, awọn akiyesi kan nipa nkan ti Badirat n fi sori ayelujara Instagram rẹ n fihan pe, o ṣe e ṣe ko jẹ ootọ ni iroyin naa.

Bakan naa lo fi oju han pe ilu Eko ni Olori Badra n gbe bayii, to si ti si ile itaja nla kan si adugbo Ikeja nilu Eko eyi to si losu kẹwaa ọdun 2020.

Olori Badirat

Oríṣun àwòrán, Instagram/queenola2

Ninu ile itaja naa lo ti n ta aṣọ, ati ohun ẹsọ iṣaraloge, to si tun sọ lọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to kọja pe, awọn nkan to ṣẹlẹ si oun lọdun 2020 ba oun lọkan jẹ, to si jẹ ki oun mọ pe ohun gbogbo to n dan kọ ni wura.