Queen Badra Olaitan: Ọ̀pọ̀ nnkan tó bàmí nínú jẹ́ ni ojú mi rí lọ́dún 2020

Oríṣun àwòrán, Instagram/@queenola2
Ilé ọkọ, ilé ẹ̀kọ́ ni àwọn Yoruba gba pe o jẹ́.
Lẹyin ti Alaafin Oyo to jẹ́ olowoori olori badira tẹlẹ ko to ko kuro laafin darapọ mọ awọn Alaseku ni iroyin ti n jade nipa olori naa lori ayelujara.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
Oba Lamidi Adeyemi kẹta ni Eledaa jogun awọn olori to pọ fun ni eyi ti wọn ọpọ n pe ni 'ẹ̀lẹ̀ daddy'.Wo àwọn òrékelẹ́wà tí yóò ṣe opó lẹ́yìn Aláàfin Oba Adeyemi tó papòdà
Saaju ki Oba Atanda to waja ni Olori yii ti kuro ni aafin to si salaye ohun to sele si oju opo ayelujara re gege bi o se wa nisale iroyin yii
- Wo ohun tó yẹ kó mọ nípa Baràá ibùgbé ìkẹyìn Aláàfin Olayiwola Adeyemi
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olòrì Alaafin Adeyemi àtàwọn tó bá fẹ́ fẹ́ wọn
- "Kòríkòsùn lèmi àti Alaafin ṣùgbọ́n kété táwọn kan kẹ́ẹ́fín pé èmi láàyò ni gbogbo nǹkan dojúrú." Badirat Ajoke, olorì tẹ́lẹ̀ kẹ́dùn Alaafin
- Wo àwọn òrékelẹ́wà tí yóò ṣe opó lẹ́yìn Aláàfin Oba Adeyemi tó papòdà
- Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamidi Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà
- 'Aláàfin ti rí ikú rẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó wàjà, ó sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó tó kú'
- Òrumọ́jú ní ara Oba Lamidi Adeyemi wọ káà ilẹ̀ lọ ní Báárà gẹ́gẹ́ bí ìṣe ìran Yorùbá ṣe làá kalẹ̀
Bawo ni ọ̀rọ̀ ohun to ṣẹlẹ laarin Olori Badira ati Kabiesi ṣe jẹ́ nigba naa?
Yoruba ni oju ẹni maa la, a ri to, oju ẹni maa la, a ri iyọnu, bẹẹ si ni ẹni ti yoo ba ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin.
Awọn asamọ ọrọ yii lo n se apejuwe itan igbe aye Olori Badrat Olaitan Aajoke Adeyemi, gẹgẹ bo se salaye loju opo Instagram rẹ, lasiko to n se ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.
Olori Badrat to bi ọmọ mẹta fun Ọba Adeyemi, rọra se ajọyọ ọjọ ibi ọdun Kọkanlelọgbọn rẹ lori ayelujara naa ni lẹwọlẹ.
A o ranti pe ni ọdun to kọja ni Ayaba Badra se ayẹyẹ ọgbọn ọdun ni aafin Oyo tilu tifọn, to si n pokiki rẹ lori awọn oju opo ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Instagram/@queenola2
Amọ nigba to n sọrọ lori ọjọ ibi rẹ naa, to waye lọjọ Kẹta osu Kọkanla ọdun 2020, Olori Badra ni oju oun ti ri nnkan lọdun 2020 ta wa yii.
O ni "Oju mi ti ri ọpọ nnkan lọdun yii, Mo ja aimọye ija, wọn ja mi kulẹ, ọkan mi rẹwẹsi, wọn parọ mọ mi, ti mo la ipo ibanujẹ kọja."
Olori Badra fikun pe, oun tun ka ọpọ iroyin lawọn oju opo ayelujara nipa ara oun, ti oun gan alara ko mọ nipa rẹ rara, eyi to se ajeji si oun alara.
O wa fikun pe oun gbogbo lo n sisẹ pọ fun rere ni, nitori pe ko ye oun lasiko ti oun n la awọn isẹlẹ naa kọja pe oun fẹ lọ sipo to tun ga ju ipo ti oun wa lọ ni.

Oríṣun àwòrán, queenola2 Instagram
"Ti mo ba sọ itan igbesi aye mi fun yin, o seese kẹ ba mi sọkun, o si ti wa ye mi bayii pe gbogbo ohun to n dan kọ ni wura, sugbọn Alihamdulilahi, mo ti ri iwosan ọkan."
Ayaba Adeyemi naa wa rọ awọn ololufẹ rẹ lati se adura fun oun ni ayajọ ọjọ ibi rẹ naa.
Olori Badrat, bẹẹ ba gbagbe, ni ẹnu n kun pe o ti kuro ni aafin Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta gẹgẹ bii olori rẹ.
Eyi ko si sẹyin awuyewuye ọrọ kan to gba ori ayelujara kan lasiko kan pe, arẹwa ayaba naa n ni ifẹ ikọkọ pẹlu Ọba Fuji, King Wasiu Ayinde Marshall, Kwam 1.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Pẹlu awọn ohun ti olori Badra kọ sori ayelujara naa, o ti n foju han pe o seese ko ma si lara awọn olori to n gbe pẹlu Ọba Adeyemi mọ, ninu aafin rẹ nilu Oyo.
Bakan naa, Olori Badra ti si ile itaja asọ nla kan si adugbo Ikeja nilu Eko ninu ọdun 2020 yii, eyi to tun n mu kawọn eeyan maa ni ilu Eko ni Ayaba Badra n gbe bayii, kii se Oyo mọ.















