Baràà: Pàtàkì wo ló so mọ́ ibùgbé Aláàfin Adeyemi àti àwọn Ọba tó wàjà ṣáájú rẹ̀?

Ibugbe ikeyin

Oríṣun àwòrán, Others

Bi ẹda ba sipo pada kuro nipo alaaye to bọ si ibi tawọn agba n ree, o di dandan ko ni ibusun eleyi ti wọn yoo tẹ ẹ si.

Ni ilẹ Yoruba ati lawọn ilẹ miran, ipo pataki lawọn ori ade wa to si jẹ pe ibi ti wọn a maa sin wọn si a maa yatọ si tawọn araalu to ku.

Bi iru oriade yi ba tun wa jẹ Alaafin, ọtọ ni aaye ti wọn yoo fi Oriade bi 'iku baba yeye', Alaafin Oyo to waja laipẹ yi si.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀

Orukọ ibi ti wọn a maa tẹ awọn Alaafin ilẹ Yoruba sí a maa jẹ Baraa.

Kini o yẹ ki o mọ nipa Baraa ni Oyo ti wọn n sin awọn Alaafin si?

Ninu awọn aaye isẹmbaye to lamilaaka ni ilẹ kaarọ o jiire, ọkan pataki ni Bara jẹ.

Ibẹ ni wọn maa n sin awọn Alaafin si.

Ọpọ awọn Alaafin bi Aláàfin Aólẹ̀, Onisile, Ajagbo, Ọbalókun ati Alaafin to waja laipẹ yi, Oba Lamidi Adeyemi III nibẹ ni gbogbo wọn sun si.

Baraa

Oríṣun àwòrán, @Pre Oyo Empire Archeological Digs

Pataki Bara ninu Aṣa ati iṣẹmbaye Yoruba

Lati le mọ pataki Baraa, Ileeṣẹ iroyin abele kan si onimọ nipa iṣẹmbaye Yoruba to si tun jẹ ọjọgbọn nipa imọ ilẹ Afrika ni fasiti North Carolina-Charlotte,Amẹrika, Ọjọgbọn Akinwumi Ogundiran.

O ṣalaye pe "Ko si ibomiran to jẹ aaye iṣẹmbaye ti wọn ṣe iwadii lori rẹ bi Bara.Ibi aaye ijọsin ni''

Àkọlé fídíò, Alaafin Oyo's burial: Oba Lamidi Adeymi darapọ̀ mọ́ àwọn àgbà ìṣáájú, ọ̀pọ̀ ń dárò Kábíèsí

O ni ''ti wọn ba fẹ ṣe iwuye fun Alaafin tuntun,Alaafin ti wọn fẹ fi jẹ oye yi gbọdọ lọ si Bara lati lọ foribalẹ fawọn Alaafin to ti jẹ to si ti waja saaju rẹ."

O ni nigba naa ni wọn yoo ṣẹṣẹ daamọ ni Oriade ni Oyo Ile.''

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Bi oba ba si waja lẹyin igba to lo ṣaa rẹ lori apere,''Bara ni wọn yoo gbe Oba pada si lati se awọ etutu ikẹyin ti wọn maa n ṣe fun Alaafin''

Toun ti bi aaye Bara yi ṣe pataki si fun aṣa ati iṣẹṣe Yoruba,nibi to wa lẹyin odi ọgba National Park ti mu ki aaye olowo iyebiye yi wa ninu ewu nitori ko si aabo to peye fun.

Baara

Oríṣun àwòrán, @Pre Oyo Empire Archeological Digs

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ,aaye yi wa wa ninu ewu to si jẹ pe aabo to yẹ ko wa fun ibusun awọn Alaafin yi ko fi bẹ si.

Gbogbo igi to yẹ ko jẹ idaabo fun awọn ori ade yi nibi ti wọn sun si lo ti n parẹ tan to si jọ pe yoo buru si nitori awọn ijọba ko bikita aaye yi nipa itọju to yẹ.