Alaafin of Oyo dead: Oba Lamidi Adeyemi ti jáde láyé! Bó ṣe ń lọ rèé

Alaafin Oba Adeyemi III

Oríṣun àwòrán, acebook/Alaafin Oba Adeyemi III

BBC Yoruba ti kan si Aafin Oyo fun ẹkunrẹrẹ lori iku Ọba Lamidi Adeyemi, Alaafin ti ilu Oyo.

Iroyin naa tẹ wa lọwọ ni yajoyajo lowurọ yii to sọ pe Alaafin ti ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi ti lọ darapọ mọ awọn baba nla rẹ lajule ọrun.

"Gbogbo eto aṣa ati iṣẹẹṣe ti bẹrẹ bayii ni Aafin"!

Ki lo n ṣẹlẹ l'Aafin Alaafin lọwọ lowurọ yii?

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo

Ọmọba ni Aafin Oyo sọ fun BBC Yoruba pe kete ti wọn rii pe baba ti re alakeji ni ilana aṣa ati iṣẹṣe ti bẹrẹ l'Aafin ni pẹrẹwu.

"Wọn ti bẹrẹ aṣa ati iṣẹṣe bayii. A ni ki ni yoo tun ṣẹlẹ bi ojumọ ba ti mọ ni Aafin, ọmọba ni "ṣe ẹ mọ pe ọmọde lemi, awọn agbaagba si wa atawọn alaṣẹ ni Aafin torinaa emi o le sọ".

Ni oru ọganjọ ti a kọkọ bẹrẹ si ni gbọ fiinfiin ni BBC Yoruba ti tara ṣaṣa kan si afin ti ọkan lara awọn ọmọ aafin rẹ si fi da wa loju pe Baba ti lọ. Wiwadii yii kan ṣe kongẹ asiko ti ọmọ wọn maa n ji fun saari, ni to si jẹ anfani fun BBC Yoruba tori ibaṣepọ oun ati ẹni to ba sọrọ lara wa amọ ti a ko le darukọ ẹnikẹni.

A tun gbiyanju lati pe pada fun ẹkunrẹ́rẹ́ amọ, wọn ti wa ninu ọfọ, gbogbo aanfin ti ko si idaro Ọba nla to lọ yii.

Gẹgẹ bi awọn iwe iroyin kan ṣe sọọ, wọn ni Alaafin dakẹ ni ile iwosan Fasiti ti Afe Babalola ni Ado Ekiti.

Ẹwẹ ọmọ Alaafin to ba BBC Yoruba sọrọ ti a ko le darukọ rẹ sọ pe ni owurọ oni ni Alaafin dagbere faye.

Ẹni ọdun mẹtalelọgrin ni Alaafin nigba to jad laye, oun si ni Alaafin to ti jọba fun odidi ọdu mejilelaadọta.

Ọmọ Alaafin ba BBC Yoruba sọrọ laarọ yii

Oba lamidi Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Oba (Dr.) Lamidi Adeyemi III, JP, CFR

Nigba ti BBC Yoruba ba ọkan lara awọn ọm Alaafin to ti wa laafin lowurọ yii sọrọ o fi da wa loju pe lootọ ni Baba ti lọ.

"Bo ṣe ri gangan ni iroyin tẹẹ gbọ yẹn, nkan tẹẹ gbọ yẹn naa ootọ ni. Baba ti lọ ni owurọ yii".

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Nigba ti a beere pe igba wo lo ṣẹlẹ gangan toripe awọn oniwe iroyin kan ti n gbe e kiri pe alẹ ana ọjọ Ẹti ni Kabiyesi ku, ọmọba ni "aarọ yii gangan lo ṣẹlẹ".

A o maa mu ẹkunrẹrẹ́ wa fun yin bo ba ṣe n lọ.