Alaafin Oyo Oba Lamidi Adeyemi: Kìí ṣe oògùn ìbílẹ̀ ni mo fi ń rántí déètì ọjọ́ àti oṣù lórí

Alaafin

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Lamidi III

Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi tí sapejuwe iyi to wa ninu bo ṣe ni imọ pé o da bíi idokoowo ni to sì ni ere pupọ ninu.

Oba Adeyemi tún jẹ́ ko di mimọ pe oogun tí àwọn èèyàn ro wípé òun n lo to fi jẹ pe ọgbọn orí àti ọpọlọ pọ to bẹẹ ni iye ọjọ orí to wa, bàbà ṣi máa ń rántí nkan perepere, o ni irọ gbaa ni, oun ko lo oògùn kankan.

Ori ade yìí mẹ́nu bá ọrọ náà níbi eto ayẹyẹ igbaniwọ ile ẹ̀kọ́ gíga ìkẹrindínlógún Fasiti Lead City ti wọn pe e si gẹgẹ bi alejo pataki to si n sọ̀rọ̀ nípa awọn to n ro wípé Alaafin máa ń lo oogun ìbílẹ̀ lati lee rántí awọn ọjọ, oṣù àti ọdun pàtàkì gẹgẹ bawọn eeyan ṣe woye rẹ pe kii gbagbe irú nkan báyìí.

Nigba to n bu ẹnu ẹtẹ lu ọrọ naa, Ọba Adeyemi ni òun maa n rántí ọjọ tori idokoowo toun ṣe si igbesẹ níní imọ.

"Mo mọọmọ ko owó àti akoko lorii mímú imọ mi gbòòrò sii ni tori pe mo fẹ́ di sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀ itagbangba nítorí ipò mi".

Ọba Adeyemi rọ awọn ọmọ Naijiria lati dokoowo ohun tí wọn ní sinu idagbasoke imọ ati ọgbọn ori wọn.

Alaafin ni "nigba ti mo wa ni Fasiti Usman Dan Fodio gẹgẹ bii Ọga Giwa Fáṣítì, mo dá nìkan san owó iléèwé awọn ọmọ ilẹ̀ ẹ̀kọ́ igba láti lọ ṣe imọ ẹ̀kọ́ to ba wu wọn.

Too ba ko gbogbo ti apo rẹ síta, too ko lori idagbasoke ọpọlọ rẹ, okoowo to dára gidi nìyẹn".

Alaafin ni ni gbogbo ibi tí òun bá ti ń sọ̀rọ̀ tòun ń rántí déètì ọjọ́, asiko àtàwọn iṣẹlẹ àtẹ̀yìnwá, awọn èèyàn máa ń rò pé mo lo oògùn ni torí ọpọlọ òun pé yekeyeke.

"Àmọ́ kii ṣe bẹẹ, titori pe mo nifẹ láti di Ọga nínú sọ̀rọ̀-sọ̀rọ̀ ìta gbangba ni.

Ohunkohun too ba fẹ láyé too bá sì fi ọkan rẹ sii too beere lọwọ Ọlọ́run pe ko ṣe é fún ọ, yoo ṣe é fun ọ ".

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ ọkùnrin mẹ́tà ló timi mọ́lé tí wọ́n n bá mi sùn lójoojúmọ́ ni Libya