Obasanjo: Ẹ ò lè jíròrò l'órílẹ̀èdè yín bẹ́ ò bá paná ìjà ogún tẹ́ẹ ṣì ń jà

Oríṣun àwòrán, Others
Aṣoju patakii àjọ isọkan agbaye fun pipẹtu sááwọ̀ to tun jẹ Ààrẹ orileede Naijiria tẹ́lẹ̀ rí, Oloye Olusegun Obasanjo tí kilọ fún pé ìjíròrò ko leè pèsè alafia rara ni orileede Ethiopia niwọn ìgbà ti wọn ba si tẹsiwaju nínú ogun tí wọn n bá ara wọn ja to si n le sii.
Ọgbẹni Obasanjo to ṣẹ̀ṣẹ̀ padà de lati orileede náà laipẹ nibi to ti bá àwọn alasẹ ijọba orileede naa sọ̀rọ̀ àti ẹgbẹ́ to ń ṣojú awọn to n ja fún ominira awọn eeyan ilẹ̀ Tigray (TPLF) tí wọn ti jọ ń doju ogun kọ ara wọn to ti le ni ọdun kan bayii.
Oloye Obasanjo ni oun ni ireti nípa bibara ẹni jiroro o amọ pe igun mejeeji nilo lati sọ awọn nkan ijagun silẹ na ki wọn dawọ ija duro na ki wọn si wa ibi pẹlẹbẹ ti wọn ti leè mu ijiroro wọn na.
Titi di asiko yii, tirela ṣi gba àárín àwọn mejeeji koda ó duro pa síbẹ̀ ni tori ija wọn ko i ribi aa yanjú ẹ si.
Àwọn ará Tigrayan ni láyé ko lee si ijiroro ayafi bi awọn aláṣẹ ijọba bá nawọ ìranwọ si Tigray níbi ti ọpọlọpọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún eeyan ti ń koju ìyàn àti ìṣẹ́.
Ni ti ijọba Ethiopia, wọn ni awọn Tigray gbudọ moye nipa ipò ati àṣẹ tí àwọn ní ki wọn si ko ara wọn kuro awọn ni ẹkùn naa eyi tii ṣe Amhara àti Afar.
Koda ọrọ ija wọn ti wa buru jáì to bẹẹ ti awọn ẹgbẹ́ bíi mẹsan kan ti wa nilẹ to ti da imọ pọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ TPLF tàwọn ará Tigrayan.
Pẹlu bo ṣe jẹ pe awọn ajija Tigray tí ń sunmọ olú ìlú orileede Ethiopia, ó ṣeéṣe ki wọn fẹ tẹra mọọ sii ki wọn tilẹ̀ to gba lati dawo ogún dúró pátápátá tàbí tilẹ̀ lọ ki ara bo ijiroro alafia kankan.
















