Unilorin beats lecturer to stupor: Ara lẹ́kíṣọ́rà Zakariyyah ti ń yá lẹ́yìn tí ọmọ 400L lù ú - Aláṣẹ Fásitì

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Iroyin to tẹ wa lọwọ latiri fidio kan to tan ka lori ayelujara nipe ọmọ ile ẹkọ kan ni ẹka imọ ẹkọ Sayẹnsi Microbiology ni Fasiti Ilorin lu olukọ rẹ obinrin bii bara.
Iroyin ni ọmọ ile ẹkọ naa ti inagijẹ rẹ n jẹ Captain Walz jẹ gbajumọ ninu ile ẹkọ giga naa ti wọn si ni ko ṣe eto lilọ kọ iṣẹ labẹ ileeṣẹ eyi ti awọn ọmọ ile ẹkọ maa n ṣe ki wọn to pari (SIWES) ti wọn si ni o lọ ba olukọ naa fun iranwọ.
Olukọ naa ti orukọ rẹ jẹ Arabinrin Zakariyyah ni alabojuto akanṣe iṣẹ aṣekagba
Eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ koro ṣugbọn ti ko fẹ darukọ ara rẹ jẹ ko di mimọ pe Captain Walz ni oun maa "n ri arabinrin naa (ati awọn mii, olugbaninimọran fun ipele ẹkọ to wa) loju ala rẹ ti wọn lepa rẹ.
Lo ba gbe igbesẹ loju aye lati lọ si ọfiisi rẹ pẹlu ero lati lọ lu u pa titi doju iku".
Ẹ̀wẹ̀, BBC Yorùbá ribi kan si baba to bi Captin Walz to jẹ ka mọ orukọ rẹ gangan,
- Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ UNILORIN lòpọ̀ títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀?
- Fásitì Ilorin ti akẹ́kọ̀ọ́ mọ́lé tórí ó fi "yẹrín etí" sí imú, ohun tí wọ́n sọ f'áráàlù rèé
- Ọwọ́ ikọ̀ Amotekun tẹ afurasí ajínigbé tó n múra bíi wèrè ní gáréèjì Akure
- Ẹgbẹ́ Afenifere kò gbàgbọ́ nínú yíyapa kúrò ní Naijiria - Ayo Adebanjo
Wọn ni ṣaaju asiko yii, o ti maa n lọ si ile ọga to jẹ olugbaninimọran fun ipele ẹkọ to wa lati kan ilẹkun rẹ.
Iroyin ni o s fun olugbaninimran ọhun pe oun o ba ti pa a to ba jẹ pe oun ṣeeṣi ri ilẹkun ṣi ni gbogbo awọn ọjọ to n wa.
O sọ gbogbo eyi nigba tọwọ tẹẹ lọdọ awọn agbofinro ileewe to si ni oun n foju si awọn akẹgbẹ oun kọọkan naa lara.
Eeyan kan to mọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ lo ṣalaye pe Captain Walz lọ si ọfiisi ọga obinrin naa lati bẹẹ toripe ko ṣe eto SIWES.
"O wọ ọfiisi ọga naa o si n gba tabili gba gba gba, arabinrin naa sọrọ sii lo ba sunmọ ọ to si bẹrẹ si ni gba obinrin naa leti".
Ẹni to ṣoju rẹ ni obinrin naa gbiyanju lati sa ṣugbọn ṣe lo tun n le e titi to fi sa wọ inu ọfiisi kan am Captain Walz tun fọ ferese wọle to si n lu u bii bara.
- Wo ọ̀nà tuntun tí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà gbé kalẹ̀ tí o fi lè di onílé
- Wọ́n ní mo máa ń lọ bá ìyá tó bí mi sùn ní gbogbo ọjọ́ Tuesday, àṣírí ti tú, àwọn náà ti ń fojú balé ẹjọ́ o! - Genesis
- Kwam 1 dá àwọn tó ń wọ́ ọ tuurutu nílẹ̀ pé ó jẹ́ gbèsè dollar iṣẹ́ orin kan l'Amẹ́rika
- 'Mi ò fìgbà kankan fura pé ọkọ mi lè fi ọmọ wa ṣe òògùn owó'
O ni obinrin naa n kigbe fun iranwọ ṣugbọn awọn eeyan ko pọ ninu ileewe toripe wọn ṣẹṣẹ wọle saa ẹkọ ni.
Wọn ni o le obinrin naa titi to fi jẹ ko bọ sipo ko mọ ohun to n ṣe mọ.
Nigba ti BBC Yoruba kan si awọn alakoso ile ẹkọ giga naa, ohun ti wọn sọ nipe lootọ, gbogbo eyi ṣẹlẹ amọ ara arabinrin naa ti n ya bayii ati pe ibẹwọ Ọga agba ile ẹkọ naa, Ọjọgbọn Suleiman Age Abdulkareem pẹlu awọn Ọga mii si mọlẹbi wọn fihan pe lootọ, ara rẹ ti n ya.
Ọgbẹni Kunle Akogun to jẹ oludari ẹka eto gbogbo, to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe Ọga agba ile ẹkọ ti fi aridaju han pe idajọ ododo ni yoo ṣẹlẹ to si ni wọn yoo tọju ẹni to faragba, fasiti yoo si san owo rẹ.

















