Father and Pastor murder son for ritual: Pásítọ̀ ran bàbá lọ́wọ́ láti fi ọmọ rẹ̀ ṣe oògùn owó, ọká bá fó!

Iya ọmọkunrin ọmọ ọdun meje ti baba rẹ sin laaye nipinlẹ Enugu, sọ pe ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun oun.
Arabinrin Onyishi sọ fun BBC Igbo ninu ifọrọwanilẹnuwo pe oun ko fi igba kankan fura pe ọkọ oun le fi ọmọ wọn ṣe oogun owo.
O sọ pe kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta (Maruwa) ni ọkọ oun fi n ṣiṣẹ, ti awọn si ni ọmọ mẹfa.
Ọmọ to kú ni ọmọ keji to bi.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita ni wọn ti sọ pe iwadii awọn fihan pe Chidi Onyishi, ẹni ọdun mẹrindinlogoji lo pa ọmọ ara rẹ.
Arabinrin Onyishi sọ pe lọjọ ti ọmọ naa di awati, oun ati baba rẹ lo jọ wa nile.
"Nigba ti mo pada sile, mo bẹrẹ si ni wa ọmọ mi."
"Mo pe ọkọ mi lori foonu ju ìgbà ogún lọ, ko gbe ipe rẹ. Lẹyin wakati diẹ, o gbe e. Mo beere pe nibo ni ọmọ mi wa, o ni oun fi silẹ pẹlu awọn ọmọ to ku ni."
Lati igba naa ni a ko ti ri Chimdalu, ọmọ mi ọkunrin keji to jẹ ọmọ ọdun meje."
O ni gbogbo igba ni oun fi n lọ si ṣọọṣi lati gbadura nitori ọrọ naa. Gbogbo igba ti mo ba si ti n gbadura ni oru, ọkọ mi ma n sọ pe mo n ni oun lara."
"O ni baba arugbo kan to jẹ afọju, ọkọ mi ma n fi kẹkẹ gbe wa lọ si ṣọọṣi rẹ ti iṣesi wọn jẹ kayeefi bakan. Mo sọ fun ọkọ mi pe mi o fẹran baba naa ati ṣọọṣi rẹ. Ṣugbọn ko gbà.
"Awọn olori adugbo ti a n gbe tun ṣeto awẹ ati adura ọlọjọ mọkanlelogun lori ọrọ ọmọ mi. Ọjọ kẹrinla rẹ ni a gbọ pe ọkọ mi lo pa mi lọmọ."
Arabinrin Onyishi ni oun ko gbagbọ, titi di igba ti awọn ọlọpaa wa si ile awọn lati mu ọkọ oun.
Bawo ni ọwọ ọlọpaa ṣe tẹ Chidi Onyishi ati pasitọ to ba a lo ọmọ rẹ
Latari iroyin kayefi nla kan ti ileeṣẹ ọlọpaa gbọ nipa ọmọ kan to dede di awati, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu ti fi panpẹ ofin mu arakunrin Chidi Onyishi.
Chidi ẹni dun mẹrindinlogoji to n gbe ni agbegbe Taylor Avenue, Coal Camp ni ipinlẹ Enugu ni wọn mu fun ẹsun pe o mọ nipa bi ọmọ bibi inu ara rẹ ṣe poora ti wọn si ni oun lo fi ṣe oogun owo.
Ọmọ ọdun meje ni Chimdali Chidi ọmọ rẹ ti wọn ni o fi ṣ'oogun owo naa ti wọn si ti fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa.
Awọn afurasi yii lo mu awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọ si idi odo kan nibi ti wọn sin oku ọmọde naa si, ti o si ti n jẹra.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Enugu ni ọwọ awọn ti tẹ afurasi naa Chidi bayii lori ẹsun pe o ji ọmọ rẹ ọdun meje gbe, to si fi ṣe oogun owo.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii fihan pe ọmọ ti wọn fi ẹjọ sun ni ileeṣẹ ọlọpaa pe o sọnu, ni oṣu to kọja naa ni iwadii fihan pe baba rẹ gan an to wa fi ẹjọ sun ni ileeṣẹ ọlọpaa lo ṣe iku pa a.
Eyi ko ṣẹyin baba ọmọ naa to jẹwọ pe lootọ ni oun hu iwa buruku yii pẹlu ajumọṣe pasitọ kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Okeke Eneokwor, ti ọjọ ori rẹ jẹ ọdun marundinlọgọrun lori ẹsun pe wọn jọ jumọ lọwọ ninu iku ọmọ naa.
Iroyin ni awọn afurasi mejeeji mu awọn ọlọpaa lọ si idi omi odo kan ti wọn sin oku ọmọ naa si, ti o si ti n jẹra.
Odo naa to wa ni agbegbe Abakpa-Nike ni ipinlẹ Enugu nibi ti wọn gbẹ ilẹ si ti wọn bo ọmọ naa mọlẹ ti ko jin ni ogunjọ, oṣu Kẹwa, ọdun 2021.
Nibayii, Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Enugu, Abubakar Lawal ti paṣẹ fun awọn ọlọpaa kogberegbe lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si fi ẹnikẹni to ba jẹbi iwa ipaniyan naa jofin.
Ìjọba Buhari, tí ẹ bá fẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ yìí ẹ jẹ́ kí Igboho lọ tọ́jú ara rẹ̀ ní Germany ná - Agbẹjọ́rò
Bakan naa ni wọn ke si awọn araalu, lati ṣọra gidigidi, ki wọn si maa fi ẹjọ ọdaran sun ni ileeṣẹ ọlọpaa to ba sun mọ wọn.
Ko tan sibẹ o, ileeṣẹ ọlọpaa naa fi awọn nọmba ti awọn araalu le pe si lede lati fi ẹjọ iwa ọdaran to ba waye ni agbegbe wọn sun fun awọn ẹṣọ alaabo.
Awọn nọmba naa ni 08032003702, 08075390883 or 08086671202, tabi ki wọn fi atẹjade ranṣẹ si oju opo yii- E-mail to: [email protected].
















