Kwam 1 dá àwọn tó ń wọ́ ọ tuurutu nílẹ̀ pé ó jẹ́ gbèsè dollar iṣẹ́ orin kan l'Amẹ́rika

Oríṣun àwòrán, Kwam 1
Gbajugbaja akọrin Fuji, Wasiu Ayinde, A.K.A K1, ti fi ọrọ sita pe oun ko lu ẹnikẹni ni jibiti owo.
Lori ayelujara Instagram rẹ ni K1 fi ikede naa si ni irọlẹ Ọjọbọ.
Eyi waye lẹyin ti iroyin jade pe o gba ẹgbẹgbẹrun owo Dọla lọwọ awọn eeyan kan nilẹ America lati wa kọrin, ṣugbọn o kuna lati yọju.
Awọn wo lo fi ẹsun kan Wasiu Ayinde?
Igun meji eeyan lo fi ẹsun kan gbajugbaja akọrin Fuji naa.
Ẹni akọkọ ni tọkọ-taya ori afẹfẹ to ma n ṣe ere Mr and Mrs Kogberegbe, Lanre Olakanle ati Dunni Badru.
Ilẹ America ni oṣere mejeeji n gbe.
Wọn fi ẹsun kan Wasi Ayinde pe awọn san owo to to ẹgbẹrun meji aabọ Dọla fun, nipasẹ alamojuto irinajo orin kikọ rẹ nilẹ America, Mike Fash (Orbit Ent. Group).
Tọkọtaya Kogberegbe sọ pe awọn fẹ ko wa kọrin fun awọn ololufẹ wọn nibi eto kan ti wọn ṣe.
Wọn ni ṣugbọn K1 ko farahan lọjọ eto naa, bẹẹni ko da owo ti awọn san pada.

Oríṣun àwòrán, Kwam1
Wọn fi ẹsun kan pe awọn ni lati da gbogbo owo tikẹẹti iworan ti awọn san fun awọn to fẹẹ wa pada, eyi to si ti di gbese si awọn lọrun.
Yatọ si eyi, wọn ni niṣe ni alamojuto rẹ ọhun n fun awọn ni oriṣiriṣi awawi.
Ni ti ẹnikeji, Babatunde Akinlami, to jẹ alawada ati olootu ayẹyẹ, sọ pe K1 kọ lati farahan nibi eto ATL show ti oun sẹto rẹ ni Atlanta lẹyin ti oun san ẹgbẹlẹgbẹ owo Dọla.
O ni niṣe ni alamojuto K1 sọ fun oun lẹyin ti eto naa ti kọja pe "Alhaji fẹ ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ akọrin rẹ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ki wọn o to le rinrinajo silẹ okeere.
Ohun naa sọ pe gbogbo igbiyanju oun lati ri owo gba pada lo n ja si ofo.
Ìjọba Buhari, tí ẹ bá fẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ yìí ẹ jẹ́ kí Igboho lọ tọ́jú ara rẹ̀ ní Germany ná - Agbẹjọ́rò
Kini K1 n sọ?
Ninu ọrọ to kọ sori ayelujara, Wasiu Ayinde sọ pe ipenija ti awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin oun n ni nipa iwe irinna wọn, Visa, lo fa idiwọ.
O ni oun ko gba owo lọwọ ẹnikẹni, ati pe alamojuto oun nilẹ America, Mike, lo n sẹ gbogbo eto.
Akọrin naa sọ pe ibi pataki ni oun to awọn ololufẹ orin oun si, ti oun ko si fi oju di wọn.
O ni oun ko lu ẹnikẹni ni jibiti, ti irinajo oun si ilẹ America fun orin kikọ yoo waye ni kete ti ọrọ iwe irinna awọn ọmọ ẹgbẹ ba yanju tan.
















