Ondo accident: Ìjàmbá ọkọ̀ gba ẹ̀mí èèyàn mẹ́fà, àwọn márùn ún farapa ní òpópónà Okitipupa

Oríṣun àwòrán, AFP
O kere tan eeyan mẹfa ti jona ninu ijamba ọkọ kan to waye ni Olla loju ọna Okitipupa si Ọrẹ nipinlẹ Ondo.
Ọkọ nla akero Coaster kan ati ọkọ J5 kan to ko ogogoro la gbọ pe o kọlu ara wọn ninu ijamba yi.
Awọn kan tọrọ naa ṣoju wọn ni o ṣeeṣe ki eeyan to ku to mẹwa.
Bakan naa la gbọ pe igba ti ọkan ninu awọn ọkọ yi fẹ sare gba iwaju ẹlẹẹkeji ni wọn kọlu ara wọn ti wọn si gbana.
Pupọ awọn arinrinajo to wa ninu ọkọ akero Coaster naa la gbọ pe wọn n pada si Akure lati Okitipupa nibi ti wọn ti kopa ninu inawo ọkan lara awọn ọga ijọba ibilẹ Odigbo.
Ijọba ibilẹ Akure North la gbọ pe o ni ọkọ ọhun.
Kaakiri oju opo ayelujara lawọn eeyan ti n pin fọnran fidio ijamba ọkọ yi nibi ti awọn ọkọ naa ti n jona tawọn eeyan kan to farapa si n ke irora,
Sikiru Alonge to jẹ ọga agba ajọ ẹsọ oju popo fidi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ iroyin The Cable sọ pe awọn kole sọ iye eeyan to ku lọwọ bayi.
Amọ ṣa o ni awọn ti doola eeyan marun un to farapa tawọn si tigbe wọn lọ si ile iwosan State Specialist Hospital ni Okitipupa ati Prima Hospital to wa ni Ore.
O ni awọn ajọ FRSC pẹlu ọlọpaa lo jijọ pa ina ọkọ naa.












