Ìjàmbá ọkọ̀ gba ẹ̀mí èèyàn mẹ́rìnlá, àwọn mẹ́ta fun farapa ní òpópónà Eko sí Ibadan

Ko din ni eeyan mẹrinla to jona kú ninu ijamba ọkọ kan to waye ni opopona Eko si Ibadan ni alẹ Ọjọbọ.
Bẹẹ ni awọn mẹta mii tun fi ara pa.
Iroyin sọ pe ni nkan bi ago mẹjọ kọja ogun iṣẹju ni alẹ Ọjọbọ ni ijamba ọkọ naa waye lori afara 'Long Bridge' ni abala opopona naa to wa si Eko.
Ọkọ bọọsi akero kan la gbọ pe o kọlu ọkọ ayọkẹlẹ jiipu kan to ti bajẹ si aarin ọna.
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle jabọ pe niṣe ni bọọsi naa gbiyanju lati sare kọja awọn ọkọ miran loju popo lọna aitọ, amọ nibi to ti n ṣe bẹẹ lo ti lọ kọlu ọkọ jiipu ọhun to ti bajẹ si aarin ọna.
Ni kete to kọlu u, ni awakọ bọọsi naa ko le dari ọkọ daadaa mọ, eyi to mu ki ọkọ rẹ takiti, to si gbina.
Agbẹnusọ ajọ to n mojuto irinna ọkọ ni ipinlẹ Ogun, TRACE, Ọgbẹni Bababtunde Akinbiyi sọ fun awọn akọroyin pe mẹrinla ninu awọn eero inu bọọsi naa lo jona kọja didamọ, ti ina si pa mẹta lara wọn lara.
Lara awọn to ku si ni ọmọde mẹta wa.
Bakan naa ni wọn ti gbe awọn to farapa lọ si ileewosan iṣẹlẹ pajawiri ti ipinlẹ Eko to wa ni Tollgate ati ileewosan General to wa ni Gbagada.










