Doyin Odebowale: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ l‘Ondo ní lílọ ní amúgbálẹ́gbàá yóò lọ fún ẹ̀tọ́ Adeola Egbebi

Doyin Odebowale

Oríṣun àwòrán, OSRC TV/Funmilayo Fanda

Ọkọ arabirin oṣiṣẹẹ wolewole ti amugbalẹgbẹ Gomina Akeredolu gba leti ni ipinlẹ Ondo ti ni ara oun ko ba ma gba a lati kan kawọ ko bi oun ba wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Ọkọ Adeola Egbebi ni "mi o tilẹ mọ pe ara mi ni iso ti n run nigba ti mo sun mọ ibẹ afi ti wọn sọ fun mi mo si yari gidi gan".

Ọgbẹni Egbebi ni niwọn igba ti oun tun lọ bere lọwọ awọn ara inu ọja ti wọn ni bẹẹ lo ri koda ki ẹnikẹni to ba fẹ fọrọ wa awọn lẹnu wo ko maa bọ, o ka a lara gidi.

"Bi mo ba nibi ti iṣẹlẹ igbati naa ti ṣẹlẹ ni, amugbalẹgbẹ ọhun ko ba ma fara ire lọ tori ohun to ṣe lo gbe iyawo mi de ile iwosan bayii".

O ni oun ti lọ fi ọrọ naa sun nile iṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n ri si ọrọ awọn obinrin ati ileeṣẹ ọlọpaa lati da si ọrọ naa.

Ẹwẹ, o sọ fun BBC pe inu oun bajẹ gidi nigba ti oun gbọ pe amugbalẹgbẹ gomina ipinlẹ Ondo gba iyawo oun leti to si ni oun ti lọ fi ọrọ naa sun nile iṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n ri si ọrọ awọn obinrin ati ileeṣẹ ọlọpaa lati da si ọrọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, irẹjẹ naa kọja eyii ti oun ati idile oun le farada, oun si fẹ ki awọn ọmọ Naijiria da si ọrọ naa ki iyawo oun le ri idajọ ododo gba.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe iwọde lati ja fun ẹtọ arabinri oloyun.

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn osisẹ nipinlẹ Ondo ti ke si gomina Rotimi Akeredolu lati gba isẹ lọwọ amugbalẹgbẹ rẹ fọrọ akanse isẹ ati aato, Ọmọwe Doyin Odebowale.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe obinrin alaboyun kan to jẹ osisẹ nileesẹ kolẹ-kodọti lo daku nigba ti Odebowale gba leti lẹnu isẹ.

Ẹgbẹ osisẹ naa ni iwa idojuti gbaa ni Odebowale hu si alaboyun naa, Adeola Egbebi lasiko ti obinrin naa wa lẹnu isẹ ladugbo Oja Oba nilu Akure l'Ọjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ apapọ awọn osisẹ ọba (AUPCTRE) nipinlẹ naa, Comrade Moyin Banso fisita lọjọ Ẹti, lo sisọ loju ọrọ yii.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ kálọ sí ìlú mi'... Ètò ńlá tó bẹ̀ sílẹ̀ kìjà lórí BBC Yorùbá

"A fi gbogbo ẹnu bẹnu atẹ lu iwa ti ọmọwe Odebowale hu si obinrin naa, idi si ree ta se n beere pe kijọba juwe ọna ile fun.

Igbesẹ yii nikan si lo le jẹ ki alaafia jọba, ki wọn si maa tọpinpin ipo ti ilera obinrin naa wa."

Amin iyasọtọ kan

Ki lo sẹlẹ saaju:

Mo dákú rangbọndan lẹ̀yìn tí amúgbálẹ́gbẹ gómìnà Akeredolu fún mi ní ìgbájú olóyì - Aláboyún

Doyin Odebowale

Oríṣun àwòrán, OSRC TV/Funmilayo Fanda

Alaboyun kan ti fẹsun kan olubamọran pataki lori akanṣe iṣẹ si gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo, Ọmọwe Doyin Odebowale pe o fọ oun leti.

Obinrin naa, Egbedi Adeola ati ọkọ rẹ ṣalaye fun BBC Yoruba pe gbagede inu ọja ọba ilu Akure ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Adeola ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti wọn n ṣe eto gbalumọ inu ọja ti wọn maa n ṣe ni gbogbo Ọjọbọ.

O ni "Iṣẹ wolewole ni mo n ṣe ti a si maa n jẹ ki awọn araalu bọwọ fun ofin gbalumọ inu ọja, ṣugbọn o rẹmi lọjọ naa nitori mo jẹ alaboyun."

"Nigba ti amugbalẹgbẹ gomina ọhun atawọn ẹmẹwa rẹ n bọ, wọn ni ki gbogbo awa ti a joko dide, mo si dide lati gbe ijoko ti mo joko le lori lọ si abẹ afara ọja ọba."

"Lẹyin naa lo ni ki n gbe ijoko naa silẹ, nigba ti mo ki n wo ẹyin wo bayii, igbaju lo ko fun mi, lẹsẹ kan naa ni oju mi ṣu."

Adeola sọ siwaju si pe ile iwosan ni oun wa lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye nitori oun ko gbadu ara oun mọ, oun si ti n mura lati ṣe ayẹwo ara oun siwaju sii.

Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, o ni ko si ẹnikẹni to tii wa fi ọrọ naa to awọn leti.

Bo tilẹ jẹ pe o ni awọn yoo gbe iwadii dide lori iṣẹle naa, ṣugbọn igbesẹ awọn yoo da le ọrọ ti wọn ba fi to ileeṣẹ awọn leti, kii ṣe lori ahesọ.

Gbogbo akitiyan BBC lati gbọ lati ẹnu ọkunrin ti ọrọ naa kan, iyẹn Ọmọwe Doyin Odebowale lo ja si pabo.

Ṣugbọn o sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ ipinlẹ ọhun, OSRC pe, irọ pata ni ẹsun ti wọn fi kan oun ati pe oun ko fọwọ alaboyun ọhun leti.

Àkọlé fídíò, 'Iṣẹ wá burẹkẹ síi tórí Covid-19, owó ńlá ló wà nínú dídáná sun òkú, ìsìnkú Zoom, Live streaming'