Yoruba Nation: Kò yẹ kí èèyàn tó kàwé bíi Akintoye lè tako gómìnà lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ìpínlẹ̀ rẹ̀ - Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi
Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunri Rotimi Akeredolu ti fi ohun ranṣẹ si agba ilẹ Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoyin lori awuyewuye to n waye lori ọrọ Yoruba Nation.
Ninu atẹjade kan ti olubadamọran pataki fun Akeredolu lori akanṣe iṣẹ, Doyin Odebowale fi lede, o ni iyapa ti Akintoye atawọn ẹmẹwa n lọgun yoo lẹyin.
Akeredolu sọ pe o ṣeni laanu pe eeyan to kawe, to si tun jẹ ọlọpọlọ pipe bii Akintoye le sọ pe gomina ipinlẹ ko laṣẹ lati sọrọ lorukọ awọn eeyan rẹ.
- Kò sí olóṣèlú tí wọ́n fi tọ́ lẹ́nu wò pé kó di ààrẹ Naijiria ní 2023 tí kò ni tọ ọ́ lá - Fayemi
- Ọwọ́ agbófinró tẹ obìnrin tó gbé 'cocaine' sínú ojú ara rẹ̀ l'Abuja
- Kí ló lè fàá kí Yomi Fabiyi àti PA rẹ̀ máa fẹnu ko ara wọn l'ẹ́nu?
- Oríire déé! Ilé aṣòfin ti buwọ́lu Adewale Adeyemo ẹni ọdun 39 bíi igbákejì adarí ẹ̀ka ètò ìsúná ní ilẹ̀ Amẹrika
- Ọ̀jọ̀gbọ́n fásítì tó yì èsì ìbò fún Akpabio yóò ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta, ẹkọ táa lè kọ́ rèé fún ará yòókù
- Arákùnrin òníbálòpọ̀ akọsákọ yarí mọ́ ìjọba lọ́wọ́ lórí àwọn Ìbejì rẹ̀ tí wọ́n bẹ́gi dínà ìrìnàjò wọn
O ni "a ri atẹjade ti awọn kan ti wọn pe ara wọn ni Ilana Omo Oodua gbe jade, eyii to lodi si ọrọ Gomina Akeredolu lori ọrọ ijagbara ilẹ Yoruba."
"Ko yẹ ki a da si ọrọ naa, ṣugbọn a ni lati fesi lẹyin ọrọ ti wọn sọ pe Ọjọgbọn Banji Akintoye sọ, niṣe lo dabi ẹni pe o ṣoro fun Akintoye yii lati ri nnkan lọna miran yatọ si nipa ẹlẹyamẹya."

Oríṣun àwòrán, Aketi
Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe, ijọba ipinlẹ Ondo ko sọ pe ki ẹnikẹni ma gbe igbesẹ lati dari ẹya Yoruba, ṣugbọn o jẹ ohun iyalẹnu pe wọn lero pe ijagbara wọn ọhun ko ni mu itajẹsilẹ lọwọ.
O ni "Ilẹ Amẹrika ni Akintoye wa lasiko ijọba ologun nigba ti awọn to ni ifẹ Naijiria lọkan ja kii nnka le dara lọjọ naa lọhun, o jẹ ohun to buru jọjọ lati sọ Naijiria sinu idarudapọ bayii nitori ijangbara kan.
Akeredolu ni o jẹ ohun to buru jai lati maa gbe igbesẹ lati sọ orilẹ-ede Naijiria ti iṣọkan wa di eyii ti awọn eeyan inu rẹ ko ni gbọ ti ara wọn mọ.
O fikun pe, "ẹ jẹ ki a sọ fun yin lẹẹkan si, ipinlẹ Ondo ko ni kopa ninu ija ominira kankan"
"Ti Akintoye ba mọ pe o wu oun lati maa ṣe aṣoju awọn eeyan, ni ṣe lo yẹ ko jọwọ ara rẹ fun wọn."
O pari atẹjade naa pe awọn eeyan ipinlẹ Ondo kii ṣe omugọ, wọn mọ ohun to tọ lati ṣe, wọn si mọ ọrọ ẹni to yẹ ki wọn tẹle.
- Ẹ kó àwọn ọmọ yín lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn Musulumi tí ẹ bá fẹ́ kí wọ́n máa lo Hijab - Oyedepo
- Àìgbọ́ra ẹni yé ẹ̀yà Yoruba ló ń ṣe ìdíwọ́ fún òmìnira wa - Àkójọpọ̀ ẹgbẹ́ Yoruba l'àgbáyé
- Ṣé ǹkan ọmọkùnrín rẹ ò ní padà kéré báyìí? Wo tuntun tí onímọ̀ Sáyẹ̀nsì gbéjáde
- Àlùwàlá ológbòò Tinubu pẹ̀lú ₦50m tó f'áwọn ará Katsina, ọgbọ́n àti kẹ́ran jẹ nínú ìbò 2023 ni
- Christopher Sapara-Williams, ọmọ Ijesha tó di agbẹjọ́rò àkọ́kọ́ tó jẹ́ ọmọ Naijiria
- Tinubu gbé ₦50m fún àwọn oníṣòwò tí ọjà wọn jóná ní Katsina


















