NDLEA visa clearance: Ọwọ́ agbófinró tẹ obìnrin tó gbé 'cocaine' sínú ojú ara rẹ̀ l'Abuja

Cocain

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n gbogun ti lilo egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti fi ṣikun ofin mu obinrin ọmọ orilẹ-ede Chad kan pẹlu egboogi oloro ninu oju ara rẹ.

Wọn gba obinirin naa mu ni papakọ ofurufu to wa niluu Abuja nibi to ti n gbiyanju lati tẹkọ leti lọ si Addis Ababa.

Agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi sọ fun awọn akọroyin pe, wọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Babafemi sọ pe iroyin kan tun tẹ awọn lọwọ pe ọkunrin kan ti gbe egboogi kokeni wọ ipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, obinrin ti wọn mu yii sọ pe ọkunrin naa lo ni ki oun gbe aadọta kokeni mi, ṣugbọn nigba ti o ṣoro fun oun ni wọn da bi ọgbọn pe ki oun ti mejidinlogun ninu rẹ bọ oju ara.

NDLEA

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ mu obinrin naa to jẹ onidiri ni Italy lọdun 2016 lasiko to n lọ si Libya.

Àkọlé fídíò, Báa ṣe lọ́pọlọ tó, ẹnu Yorùbá ò kò, ọgbọ́n táa gbúdọ̀ dá rèé - Ìpàdé àgbààgbà Yorùbá n'Ibadan

Obinrin ọhun ti orukẹ rẹ n jẹ Tarmadji ni oun wa si Naijria lati wa pa owo ti oun yoo fi gba ṣọọbu onidiri lẹyin ti nnkan le koko ni Italy nitori ajakalẹ arun Corona.

O pari ọrọ rẹ pe €10,000 ni wọn yoo fun oun to ba jẹ pe oun ṣaṣeyọri ninu kiko oogun oloro naa jade ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Bí Oduduwa Republic bá bẹ̀rẹ̀, a ò ní ṣe aburú fún àwọn tó takò wá, ìlànà ààtẹ̀lé rèé - Banji Akintoye