Gay Sex: Bí òníbálòpọ̀ akọsákọ ṣe ké gbàjarè lórí àwọn Ìbejì rẹ̀ t'íjọba bẹ́gi dínà ìrìnàjò wọn

Onibalopọ akọsakọ atawọn ibeji rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile ẹjọ giga kan ni Namibia yoo gbe idajọ kalẹ lori boya arakunrin onibalopọ akọ si akọ kan lẹtọ lati gbe awọn ọmọbinrin ibeji rẹ ti obinrin kan baa gbe oyun wọn ni South Africa.

Phillip Lühl sọ pe awọn ọmọ rẹ yi ko ni orileede ti wọn le pe ni ilẹ wọn lẹyin ti ileeṣẹ abẹle Namibia kọ lati fun wọn ni iwe irinajo pajawiri lọsẹ to kọja.

Labẹ ofin biba eeyan gboyun ni South Africa, awọn ọmọ ti wọn ba gba ọna yi ti di ọmọ orileede ibi tawọn obi wọn ba ti wa.

Lori ọrọ to wa nilẹ yi, ofin naa gbe ipo obi yi fun ọgbẹni Luhl ati ọkọ rẹ ọmọ orileede Mexico Guillermo Delgado.

Àkọlé fídíò, 'Òde ìnáwó làwọn èèyàn ma ń rò bí wọ́n bá rí Ankara, ìgbà tí wọ́n rí i lára àga tí mo ṣe, ẹnu wọn ò padé mọ́'

Ninu iwe ibura ọgbẹni Lühl ni ileeṣẹ eto abẹle ni ki ohun ṣafihan bi o ṣe jẹ pe oun lo ni awọn ọmọ meji yii.

O ni oun gbagbọ pe wọn gbe igbesẹ naa nitori pe oun ṣe igbeyawo ibalopọ akọ si akọ ati pe idẹyẹsi ni iwa yi jẹ si oun.

Ẹwẹ,o ni iwe ofin orileede Namibia ko pọn ni dandan pe eeyan gbọdọ finu ara rẹ bimọ ki wọn to mọ pe oun lobi ọmọ naa.

Ni Namibia, ofin ilẹ naa tako ibalopo akọ si akọ bo tilẹ jẹ wipe awọn to n ṣe bẹ kii foju wina ofin lọpọ igba.

Bakan naa ni ko si ilana kankan to de gbigboyun ẹlomiran sikun nilẹ naa.

Awọn ajafẹtọmọniyan n palẹmọ lati ṣe iwọde niwaju ile ẹjọ giga Namibia lỌjọbọ lati fẹhonu han idẹyẹsi ọkan lara awọn ti iṣesi wọn yatọ.

Àkọlé fídíò, Bí Oduduwa Republic bá bẹ̀rẹ̀, a ò ní ṣe aburú fún àwọn tó takò wá, ìlànà ààtẹ̀lé rèé - Banji Akintoye