Gay Sex: Ọlọ́pàá dá ọkùnrin méjì tó ń ní ìbálòpọ̀ ọkùnrin sọ́kùnrin padà sí ìlú abínibí wọn

Awon ti n se iwode ni Copacabana, Rio de Janeiro, Brazil

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orilẹede Naijiria naa ni irufẹ ofin yii, pẹlu ẹwọn ọdun mẹrinla fun ẹni ti o ba lu ofin naa

Wọn ti da ọkùnrin meji kan to n ni ibalopọ ọkunrin sọkunrin, to jẹ ara Chechen pada si ilu Chechnya, lati ibi ti wọn salọ lẹyin ti wọn fi ẹsun kan pe wọn fi iya jẹ awọn.

Àjọ ajafẹtọ kan si ti sọ pe inu ewu nla ni wọn wa bayii.

Ẹgbẹ awọn to n ni ibalopọ ọkunrin sọkunrin ni Russia sọ pe awọn ọlọpaa orilẹ-ede Russia lo mu Salekh Magamadov ati Ismail Isayev, ti wọn si da wọn pada si ibi ti wọn ti wa.

Ẹgbẹ naa sọ pe oun lo ran awọn ọkunrin naa lọwọ lati sa lọ si Russia lọdun to kọja, ki ọwọ awọn ọlọpaa Chechen ma baa tẹ wọn, nitori ẹsun pe wọn n samojuto oju opo ayelujara Telegram alatako.

Àkọlé fídíò, Wo ìgbé àyé ìyá àti ọmọbìnrin tó ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó jẹun
Aworan Okunrin ati Okunrin ti wọn di ara wọn mu ni India

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Òfin to sì lòdì sí ìbálòpọ̀ láàrin ọkùnrin sí ọkùnrin yi ti wa tipe lorílèèdè India

Awọn ọkunrin mejeeji sọ pe wọn fi iya jẹ awọn, ti wọn si tun fi ipa mu wọn lati ṣe fidio fun aforijin.

Àmọ́ sa, ẹgbẹ LGBT ni Russia sọ pe ninu ile wọn to wa ni Nizhny Novgorod, ni awọn ọlọpaa ti mu wọn l'ọjọbọ.

Ko si ẹni to ti i mọ ìdí ti wọn fi fi wọn si ahamọ.

Ẹgbẹ naa sọ pe lẹyin naa ni wọn fi ipá da wọn padà fun awọn alasẹ ni Chechnya.

Awọn musulumi lo pọ julọ ni Chechnya, idẹyẹsi àwọn to n ni ibalopọ ọkunrin sọkunrin si wọpọ nibẹ.

Àmọ́ o, olori ijọba ẹkùn naa, Ramzan Kadyrov ti sọ ni ọpọ igba pe irọ ni ẹsun ifini pamọ lọna ti ko ba ofin mu, ati títẹ ẹtọ ọmọniyan loju, ti wọn fi n kan an.

Koda, oun ati awọn olori ijọba rẹ ti ẹ sọ pe ko si ọmọ ẹgbẹ LGBT kankan ni Chechnya.

Ṣugbọn ọpọ eeyan, to fi mọ awọn ọkunrin meji yii, lo ti sọ ni gbangba pe ijọba n fi iya jẹ awọn nitori iru ibalopọ ti awọn n ni.

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike