Sotitobire Update: Agbẹjọ́rò Pásítọ̀ Alfa Babatunde láwọn ṣetán láti yí ìdájọ padà nilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn

Aworan agbẹjọro Wolii Babatunde

Awọn agbẹjọro to n soju Pasitọ Alfa Bataunde ti ijọ Sotitobirẹ ti n ṣalaye fawọn akọroyin bi wọn yoo ti ṣe yi idajọ rẹ pada.

Ile ẹjọ Kotẹmilọrun to wa nilu Akure ni igbẹjọ Sotitobirẹ tuntun yi ti n gbera sọ lati yi idajọ ile ẹjọ giga to dajọ ẹwọn gbere fun Pasitọ Bababtunde.

Losu Kẹwa ọdun to kọja ni ile ẹjọ gbe idajọ kalẹ lori ẹsun pe Pasitọ Babatunde mọ si bi ọmọ ọdun kan Gold Kolawole ti ṣe di awati nile ijọsin rẹ loṣu Kọkanla ọdun 2019.

Àkọlé fídíò, Ìdájọ́ òdòdò ló fẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ Sotitobire - Agbẹjọ́rò fún ìjọba

Pasitọ Babatunde ati awọn eeyan marun un mii lo gba idajọ lẹyin igbẹjọ oloṣu mẹwa to waye laarin oṣu Kini ati Oṣu Kẹwa 2020.

Agbẹjọro agba Gboyega Awomọlọ ni o lewaju awọn to ṣoju Pasitọ Babatunde ti arabinrin Bola Joel Ogundadegbe ati John Dada Joshua soju ijọba.

Àkọlé fídíò, Wo ìgbé àyé ìyá àti ọmọbìnrin tó ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó jẹun

Ninu ọrọ rẹ Awomolo gba iyọnda ile ẹjọ lati fi iwe mẹta sọwọ eyi ti o fẹ fi tako agbara ile ẹjọ to gbẹjọ Sotitobirẹ ati aikajuoṣunwọn iwadii ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS.

Aworan agbẹjọro Ijọba

Iwe mẹta yi la gbọ pe awọn agbẹjọro ijọba to ṣẹjọ Sotitobirẹ niwaju ile ẹjọ giga lẹyin ti awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ mu Pasito Babtunde ko tako.

Adajọ to n gbẹjọ ọhun Rita Nosakhare Pemu ni awọn funj awọn agbẹjọro Sotitobire ni ọjọ mọkanla lati ṣatunto gbogbo iwe ti wọn ba fẹ kọ wa siwaju ile ẹjọ.

Lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ, agbẹjọro Pasito Babatunde ọgbẹni Awomolo sọ fawọn akọroyin pe gbogbo ipa lawọn yoo ṣa lati ri pe Pasitọ naa gba itusilẹ.

Bẹẹ naa ni agbẹjọro ijọba arabinrin Ogundadegbe ni wamuwamu lawọn ti gbaradi lati ṣẹjọ naa niwaju adajọ.

Wolii Babatunde ati awọn ti wọn jijọ fẹsun kan ko yọju sile ẹjọ amọ iwadii wa fi han pe o ti kọwe lati yọju sawọn igbẹjọ mi ti yoo waye lẹyin toni.

Alfa Babatunde

Woli Sotitobire tún yọjú! Ó ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn yáá lónìí láti tún ẹjọ́ dá

Lẹyin oṣu mẹta ti wọn dajọ pe o jẹbi ẹsun gbigbimọpọ ti ọmọde kan, Gold Kolawole fi poora ni ijọ rẹ ninu oṣu kọkanla ọdun 2019, nkan mii ti wu jade bayii o.

Atẹjade kan ti o jẹ pe BBC Yoruba nikan ni anfani lati foju ganni rẹ ti fihan pe igbẹjọ mii lorii Woli Sotitobire yoo tun bẹrẹ lonii, ọjọ kẹjọ oṣu keji ọdun 2021.

Ọjọ ti pẹ ti awọn alatilẹyin ati ololufẹ oludasilẹ ijọ Sotitobire Praising Chapel ni ilu Akure, Woli Babatunde Alfa ti n foju sọna fun ohun ti yoo pada ṣẹlẹ lori idajọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Wo ìgbé àyé ìyá àti ọmọbìnrin tó ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó jẹun
Àkọlé fídíò, Sotitobire: Ọkọ mi kò mọ̀ Jegede PDP rí, kódà kò fa ẹnikẹ́ni kalẹ̀ dípò Akeredolu- Bisola

Boya o ti n wa sopin ni o, boya o tun n tẹsiwaju ni o, ọrọ tun ti yipada bayi pẹlu bi Pasitọ naa ṣe pinu lati gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lati sọ pe ko tọ bi ile ẹjọ giga ṣe fi oun sẹwọn gbere.

Gẹgẹ bi aridaju ti a ni lọwọ, agbẹjọro agba Naijiria meji, Oloye Gboyega ati iyawo rẹ, Victoria ni yoo dari agbẹjọro mẹfa mii lati koju aridaju ti Pasitọ naa sọ pe oun ni pẹlu awọn olukọ ọmọde marun mii ni ijọ rẹ ti wọn jọ n foju wina ofin lẹwọn.

Awọn atẹjade naa fihan wipe wọn ti kọkọ pe ẹjọ kotẹmilọrun ninu oṣu kọkanla ọdun 2020 pẹlu ẹri marun ti wọn ni, bakan naa wọn tun fi ipẹjọ mii ṣọwọ pẹlu ẹri mejila ni ọjọ kejila oṣu kejila dun 2020.

Woli Alfa sọ pe adajọ to kọkọ da ẹjọ ti wọn fi ju oun sẹwọn ṣe ohun aitọ nile ẹjọ nitori wipe ile ẹjọ ko ni aṣẹ lati gbọ ẹjọ naa bẹẹ si lo ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ naa ko ni agabara kankan lati maa tọpinpin ati ṣewadii ọrọ to yẹ ki ọlọpaa mojuto.

Nibayii, wọn ti da ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ oṣu keji ọdun 2021 lati gbọ ẹjọ rẹ ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti ilu Akure.

Iwadii tun fihan pe awọn tọrọ kan koda to fi mọ ile iṣe to n ri si eto idajọ lo ti mọ nipa igbesẹ tuntun yii ti wn si ti gbaradi lati bẹrẹ igbẹjọ lakọtun lori ẹjọ yii to jẹ ọkan pataki ninu iwe itan eto idajọ ipinlẹ Ondo.

Ijọ Sotitobire Praising Chapel ti Woli Babatunde Alfa Babatunde jẹ oludasilẹ ati alakoso fun jẹ ijọ ti ero ti maa n wọ ju niluu Akure ko to wa di pe o kagbako iṣẹlẹ aburu yii nigba ti Gold Kolawole, ọmọ ọdun kan nigba naa lọhun dede poora lasiko ti isin n lọ lọwọ ninu oṣu kọkanla ọdun 2019.

Lẹyin eyi ni awọn agbofinro ọtẹlẹmuyẹ DSS lọ gbe Wolii naa ti wọn si wọ ọ lọ ile ẹjọ majisireeti ni Akure to tun wa di ero ile ẹjọ giga nibi ti wọn ti da ẹjọ fun un lori ẹsun gboogi meji to da lorii ijọmọgbe ati igbimọpọ ati lilọwọ ninu ijọmọgbe.

Nkan bii oṣu mẹwaa gbako laarin oṣu Sẹẹrẹ si oṣu Ọwara ọdun 2020 ni fa ki n fa ẹjọ naa waye ti idajọ sọ pe Woli Sotitobire atawọn olukọ ọmọde marun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, wn si ran wn lọ si ẹwọn gberee labẹ idajọ Adajọ Olusegun Odusola ni ibamu pẹlu aṣẹ ẹri ti ẹjọ ti adajọ agba tẹlẹri ni Ondo, Adekola Olawoye dari.