Sotitobire: Ìgbẹ́jọ́ kò le è wáyé mọ́ l‘Ọ́jọ́rùú, wọ́n ṣun síwájú di Ọjọ́bọ̀

Ileejọ ti sun igbẹjọ to waye yẹ ko waye lọjọru siwaju di Ọjọbọ ọla lori ẹsun ijiọmọgbe ti wọn fi kan oludasilẹ ijọ Sotitobire nilu Akurẹ.
Bẹẹ ba gbagbe o ti to ọjọ melo kan ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ nipa ẹsun ti wọn fi kan Pasitọ Alfa Babatunde, tii se asaaju ijọ Sotitobi rẹ nilu Akure, lori bi Gold Kolawole, ọmọ ọdun kan se di awati ninu ijọ rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Nigba ti wọn n se alaye nipa ohun to fa bi wọn se sun ẹjọ ọhun siwaju, awọn osisẹ ileẹjọ sọ fun akọroyin BBC Yoruba to wa nile ẹjọ pe, ijọba ipinlẹ Ondo ti gbe ẹjọ ọhun kuro niwaju ileẹjọ Magistrate lọ sile ẹjọ giga ipinlẹ naa.

Awọn ọmọ ijọ Sotitobirẹ pọ biba nile ẹjọ lati wa se atilẹyin fun asaaju wọn, ti awọn akọroyin naa ko si gbẹyin pẹlu awọn eeyan miran to wa woran, ti ọpọ ko si mọ pe wọn ti sun ẹjọ naa siwaju.

Sugbọn wọn ko gbe Alfa Babatunde yọju sile ẹjọ rara nitori bi wọn se sun ẹjọ naa siwaju amọ agbẹjọro rẹ, wa nile ẹjọ .

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olusola Oke, tii se agbẹjọro Babatunde salaye pe, igun olujẹjọ ti sọ saaju lasiko igbẹjọ to kọja pe, awọn ti kọwe ẹbẹ pe ki wọn gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ giga ipinlẹ naa, idi si ree ti wọn ko fi gbe olujẹjọ wa sile ẹjọ lọjọru.
Ileasanmi wa fọwọ gbaya pe "lọjọbọ ni olujẹjọ naa, Alfa Babatunde yoo yọju sile ẹjọ lati tẹsiwaju nidi igbẹjọ rẹ, gbogbo awọn agbẹjọro si ni yoo yọju sile ẹjọ giga naa lọjọbọ naa."
Ara ilana ileeẹjọ ni bi wọn se gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ giga nitori oun nikan lo lẹtọ lati gbọ ẹjọ onikoko meji ti wọn fi kan olujẹjọ ọhun, ti igbẹjọ yoo si bẹrẹ ni sansan."













