Ibadan Fire: Àwọn olùgbé Ibadan,Ṣakí àti Ìséyìn lè bọ sí òkùnkùn biribiri

Ina ṣẹyọ ni ibudo ina ọba l'Ayede

Oríṣun àwòrán, Other

Ajọ alagbelebu pupa Red Cross ti sọ pe eeyan mẹta to farapa ninu ijamba ina to ṣẹyọ ni ibudo amunawa nilu Ibadan ti n gba itọju.

Akọwe ajọ naa Ojo Olaleye lo fi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin nilu Ibadan.

Amọ ṣa o ṣeeṣe ki awọn eeyan agbegbe Ibadan,Saki ati Iṣeyin wa ni okunkun birimu nitori ijamba ina yi to ṣe akoba fẹrọ amunawa ni Ayede.

Oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna kan ti ko fẹ ki adarukọ ohun lo ta awọn akọroyin lolobo ọrọ yi.

O ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna to wa nibiṣẹ lasiko ijamba yi gbiyanju lati pa ina naa ṣugbọn pabo ni igbiyanju wọn ja si.

O ni yatọ si awọn ilu ta darukọ tẹlẹ, Sagamu ati Iwo naa le ma ni ina nitori ẹrọ to n muna wa si adugbo wọn ni ina naa jo.

Lẹyin igbiyanju fun nkan bii wakati mẹta, ni wọn to ribi pana to ṣẹyọ ni ibudo ina mọnamọna nilu Ibadan.

Toun ti bẹẹ, awọn alaṣẹ ko ti ribi fidi ọrọ mulẹ nipa ohun to ṣokunfa ina naa tabi iru akoba ti ṣe.

Alukoro ileeṣẹ to n pin ina ni agbegbe Ibadan, IBEDC, Frank William sọ pe, ibudo amunawa to jona naa kii ṣe tawọn, bi ko ṣe ti ileeṣẹ to n ta ina fawọn to n pin fara ilu,Transmission Copany of Nigeria(TCN).

Ibudo ti ina ti ṣẹyọ ni Ibadan

Ni nkan bi ago meje aarọ ni ina naa ṣẹyọ, ti igbakeji ọga ileeṣẹ panapana nilu Ibadan, Adewumi Moshood naa si fidi ọrọ mulẹ pe iṣẹlẹ naa waye.

Wọn ko ti sọ boya awọn ara ilu Ibadan ko ni ni ina, nitori ijamba to waye yii.

Ni kete ti a ba ti ri aridaju rẹ, a o ma mu wa si eti igbọ yin.

Ina ṣẹyọ ni ibudo ina ọba l'Ayede

Oríṣun àwòrán, Other

Ohun to ti ṣẹlẹ ṣaaju

Ina tun ti ṣeyọ ni ibo ina mọnamọna to wa lagbegbe Ayede ni adugbo Ring Road niluu Ibadan.

Awọn ti ọrọ ṣoju wọn ni, ibugbamu lo kọkọ ṣẹlẹ ni ibudo naa ki ina to tẹ lee.

Ina naa ti da ipaya ọkan silẹ fawọn olugbe agbegbe naa niluu Ibadan bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ibeere ti wọn si n bi ara wọn ni pe báwo ni wọn ṣe fẹ́ pa iná tó ṣẹ́yọ níbùdó amúnáwá tó wà ní agbegbe Ayede n'Ibadan?

Idi ni pe ọ̀pọ̀ ohun eelo amunawa to wa nibudo naa lo lee maa gbe ẹni to ba sunmọ ibẹ, to si seese ki onitọhun dero ọrun.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn osisẹ panapana ti de si ibudo ti ina tii n jo lọwọ naa, sibẹ ko dabi ẹni pe agbara wọn tii ka ina ọhun, lasiko ta n ko iroyin yii jọ.