Turkey Plane:Bàálù pín sí mẹ́ta nígbà tó fẹ balẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn f'arapa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Baalu akero kan ni orileede Turkey ti pin yẹlẹyẹlẹ si ọna mẹta ti eeyan mejilelaadọrin si farapa ninu ijamba to waye.
Baalu naa ti awọn alaṣẹ ni o gbe eeyan mọkanlelaadọsan ati awọn oṣiṣẹ baalu mẹfa ja lulẹ ni papakọ Sabiha Gokcen to wa ni Istanbul.
Minisista feto irina Mehmet Cahit Turhan sọ pe ko si eeyan kankan to ku ninu ijamba ọhun.
Bẹẹ naa ni Gomina Istanbul,Ali Yerlikaya sọ pe wọn ti ṣaaju sare gbe eeyan mọkanlelogun lọ si ile iwọsan toun ti bi awọn oṣiṣẹ pajawiri ṣe n ba iṣẹ lọ.
Awọn iwe iroyin ilẹ Turkey jabọ pe lasiko ti ojo n rọ ni baalu ti ile iṣẹ ọkọ ofuurufu Pegasus naa gbiyanju lati balẹ lyin to gbera kuro ni agbegbe iwọ oorun Izmir.
Wọn ti gbe awọn ero kuro ninu baalu naa ṣugbọn awọn oṣiṣẹ pajawiri ṣi n gbiyanju lati yọ awọn to ha sinu rẹ.
Lori ẹrọ ayelujara, awọn eeyan n ṣalabapin fọnran fidio kan to ṣafihan ina to n jo ninu baalu naa amọ awọn panapana pada pa ina ọhun.








