Ọlọ́pàá fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ìyawo olóòtú ilẹ̀ Lesotho pé ó pa ìyáálé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Iyawo olootu ijọba orilẹede Lesotho, Maesaiah Thabane ni wọn ti fi ẹsun ipaniyan kan lorilẹede naa.
Iyawo olootu ilẹ Lesotho naa ni wọn fẹsun kan pe o pa iyawo ọkọ rẹ akọkọ ni ọdun 2017 wẹrẹ ti ọkọ rẹ gori oye.
Iyawo akọkọ olootu ilẹ naa, Lipolelo Thabane ni wọn yin ibọn pa ni iwaju ile rẹ ni Maseru, nigba ti o ku ọjọ meji ki wọn ṣe iburawọle fun ọkọ rẹ ni ọdun 2017.
Ki wọn to yinbọn pa iyaale naa ni oun ati ọkọ rẹ ti jaja tuka, ti wọn si wa lẹnu ati fi ara wọn silẹ, ki wọn to ge ẹmi rẹ kuru.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iyawo olóòtú ilẹ Lesotho, Maesaiah Thabane ni wọn fẹsun kan pe o pa iyawo ọkọ rẹ tẹlẹ, ki o to fẹ oun.
Maesaiah Thabane lo kọkọ jọwọ ara rẹ silẹ fun iwadii, ki ọkọ rẹ naa to gba agọ ọlọpaa lọ fun ifọrọwanilẹnuwo.
Nigba ti iṣẹlẹ naa kọkọ waye, awọn agbebọn ni wọn fẹsun kan pe wọn pa obinrin naa, amọ iwadii lati ileeṣẹ ọlọpaa fi ẹsun kan iyawo olootu ilẹ naa wi pe o lọwọ ninu iwa ibi naa.
Kọmisọnna ọlọpaa ilẹ naa, Holomo Molibeli ti fi iwe ifipanpẹ ọba mu ni sita fun Maesaiah Thabane to jẹ ẹni ọdun mejilelọgọrin ni ọjọ Kẹwa, Osu Kini, lẹyin ti obinrin naa sa pamọ ti wọn si bẹrẹ si ni wa.
Lẹyin ti wọn ri mu ni ibode ilẹ South Africa ni Ọjọ Iṣẹgun, Holomo Molibeli ni o ti wa ni gbaga ọlọpaa, ti wọn si n gbe lọ si ile ẹjọ ni Ọjọru, ọsẹ yii.
Bakan naa ni wọn ti fẹsun kan eniyan mẹjọ miran pẹlu rẹ fun ẹsun ipaniyan naa.

Osu to kọja ni Olootu, Thabane gba ki awọn ọlọpaa fi ọrọ wa oun lẹnu wo pẹlu bi awọn eniyan ṣe pe fun ki o kọwe fi ipo silẹ.
Thabane gba lati fi ipo silẹ, amọ ko sọ ọjọ ti oun yoo sẹ bẹẹ.














