Community Policing: Onímọ̀ ètò ààbò ní kìí ṣe ojúṣe ọ̀gá ólọ́pàá láti dá ọlọ́pàá agbègbè sílẹ̀

Awọn ọlọpa agbegbe

Oríṣun àwòrán, @NTANewsNow

Ọlọpaa agbegbe, ti ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria n gbero lati dasilẹ ko le kẹsẹjari, laijẹ wi pe ijọba ṣetan lati maa fawọn ti wọn fẹ gba ṣiṣẹ lowo.

Onimọ nipa ọrọ eto aabo, Ọgbẹni Richard Amuwa to ba BBC Yoruba sọrọ, lo woye bẹẹ.

Ọgbẹni Amuwa sọ pe awọn ara ilu to ba fẹ ṣiṣẹ ọlọpaa agbegbe, nilo lati gba owo oṣu, bi bẹẹ kọ, wọn ko ni ṣiṣẹ naa tọkantọkan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Onimọ nipa ọrọ eto aabo tun sọ pe, kii ṣe ojuṣe ọga ọlọpaa lati ṣe eto gbigba ọlọpaa agbegbe.

O ni awọn awọn alaṣẹ ipinlẹ kọọkan lo yẹ ki wọn wa awọn eeyan lawujọ lati ṣiṣẹ ọlọpaa agbegbe, nitori awọn lo mọ awọn eeyan wọn.

Ọga agba ọlọpaa Mohammed Adamu lo paṣẹ fawọn ọga ọlọpaa ipinlẹ kọọkan lati forikori pẹlu awọn ọba alaye atawọn olori awujọ k'eto naa kẹsẹjari.

Awọn ọlọpa agbegbe

Ṣugbọn Ọgbẹnu Amuwa ni ọga agba ọlọpaa ko ni ohun kan ṣe pẹlu ọlọpaa agbegbe nitori ko si lọwọ ijọba apapọ.

O fi Gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha ṣe apejuwe ijọba ipinlẹ to ti ṣe agbekalẹ ọlọpaa agbegbe ri.

Ọgbẹni Amuwa ni Rochas forikori pẹlu awọn ọba alaye atawọn olori awujọ lati gba awọn eeyan ṣiṣẹ, bakan ni ijọba rẹ si n fun wọn lowo.

Àkọlé fídíò, Cancer Survivor: Àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn ṣe wò, ta bá tètè ṣe àkíyèsí rẹ̀, ká sì lọ sílé ìwòsàn

O ni ijọba apapọ ati ọga agba ọlọpaa ni Naijiria ko mọ itumọ ọlọpaa agbegbe.

Onimọ nipa ọrọ eto aabo, Ọgbẹni Amuwa ni ko lee si eto aabo to mọyan lori ti ijọba ba kọ lati sanwo fawọn ti wọn fẹ gba gẹgẹ ọlọpaa agbegbe.