Daniel Arap Moi: Ọdun 2002 ló yẹ̀bá lórí àlééfà bíi ààrẹ Kenya, tí wọ́n sì ní kò gbọdọ̀ díde mọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Daniel arap Moi jẹ gaba lori eto oṣelu orilẹede Kenya fun bi ọdun mẹẹdọgbọn.
Koda o gbajumọ gẹgẹ bi oloṣelu ju ọga rẹ Jomo Kenyatta gan an lọ, bẹẹ lo si ni awọn alatilẹyin kaakiri orilẹede Kenya.
Ṣugbọn o kuna lati fopin si ijọba amunisin nilẹ naa, koda oun gan an fimu awọn alatako rẹ danrin.
Moi tiẹ gba orukọ inankijẹ ''Ọjọgbọn eto oṣelu'' ṣugbọn ẹsun iwa ajẹbanu ati ọrọ aje to dẹnu kọlẹ ba ijọba rẹ jẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Máṣe tijú láti gé ọmú rẹ to bá ṣàkíyèsí kóró nínú ọyàn, ilèra ló ṣe kókó - Ẹni tó ye àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn
- Kò sí ìfòyà tí ẹ bá ti ní nọ́mbà ìdánimọ̀, kékeré ni káàdì ìdánimọ̀ - NIMC
- Wọ̀dùwọ̀dù àsìkò ijáde mú ẹ̀mí akẹ́kòó mẹ́tàlá lọ
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Afíríkà kan tí lùgbadì ààrùn Coronavirus ní Fásitì China
- Ọwọ Gómìnà Makinde làṣẹ wà bóyá a ó fí òfin dé Okada ní Oyo -OYRTMA
- 'Ẹ bá wa sọ fún Sanwoolu kó dárí jì wá o, ìpinú tí wọ́n ṣe l'Eko kò m'ọ́gbọ́n wá rárá'
''Eto oṣelu niiṣe pẹlu bibori ati fifidi rẹmi'' - Daniel Arap Moi.
Wọn bi Daniel Arap Moi lọjọ keji oṣu kẹsan an ọdun 1942 si idile agbẹ kan lagbegbe Balingo, lapa iwọ oorun orilẹede Kenya.
Orukọ abisọ rẹ Torotich Arap, ṣugbọn o bẹrẹ sii jẹ Daniel nigba ti o ṣe iribọmi.
Aṣoju
Moi jẹ ọkan lara awọn oloṣelu ti ko wa lati inu ẹya meji to tobi ju- ẹya Kikuyu ati Luo. Ẹya Tugen ni.
O di olukọ ni ile iwe ile ijọba ilẹ Afirika(Government African School) lọdun 1945, ki o to di ọga olukọ lọdun 1946 ni ẹni ọdun mejilelogun.
O pada si Kapsabet ni ọdun 1954 gẹgẹ bi ọga ile iwe, ibẹ lo si wa di ọdun 1957.

Moi ko kopa ninu idojukọ Mau Mau ṣugbọn kaanu awọn ajijagbara ominira lati ilẹ Gẹeṣi
O jẹ ọkan lara awọn eeyan dudu mẹjọ ti wọn dibo yan si ile aṣofin lọdun 1957.
Ni ibẹrẹ ọdun1960, o wa lara awọn aṣoju ilẹ adulawọ ti wọn kọ iwe ofin ilẹ Kenya nibi apero nilu London lọdun 1960
''Ti wọn ba fiya jẹ wọn, ki lode ti wọn ṣe lọ sile ẹjọ?'' Daniel Arap Moi lo sọrọ yii fun BBC lẹyin ẹsun pe ijọba n fiya jẹ awọn ẹgbẹ alatako.
Moi di minisita fun eto ẹkọ lọdun 1961, o si tun jẹ minisita fun ijọba ibilẹ.
Eto aabo orilẹede
Nigba tirẹ, Moi kopa ninu oriṣiiriṣii apẹro ti wọn fi ṣe igaradi fun ominira orilẹede Kenya. Bẹẹ wọn si rii pe ijọba apapọ ti yoo fun awọn eeyan lagbara ati aabo fun ẹya kekeke.
Kenyatta jẹ Olootu ijọba nigba ti Kenya gbominira lọdun 1963, ti Moi si jẹ minisita fun eto ọgbin.

Lọdun keji, Kenyatta di aarẹ, bẹẹ ni wọn bura fun Moi gẹgẹ bi minisita fun ọrọ abẹle.
Lọdun 1867 ninu oṣu kinni, Moi di igakeji aarẹ orilẹede kenya ati igbakeji ẹgbẹ ajajagbara aṣofin Kanu.
''Nilẹ alawọdudu gbogbo eeyan la fẹran to fi mọ awọn otosi.''- Daniel Arap Moi
Awọn ẹka tuntun
Nigba ti Kenyatta ku lọdun 1978, Moi di aarẹ fidihẹ.
Ninu oṣu kẹwaa, wọn dibo yan an gẹgẹ bi olori ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo to wa lorilẹede Kenya, bẹẹ lo si di aarẹ keji ilẹ Kenya.
Loṣu kọkanla, o ṣe atunto ijọba rẹ ati awọn to yab si po gbogbo.

Oríṣun àwòrán, PA
Awọn ẹka ijọba tuntun bi ẹka alumọni ati ayika bẹrẹ, ti ẹka eto ọgbin ṣi di pinpin.
Awọn ologun fẹ gbajọba lọdun 1982, ṣugbọn ko ṣeeṣe fun wọn.
''Awọn ara ilẹ Kenya ti fihan pe Afirika le sẹto ijọba ara wọn laisi idiwọ.''- Daniel atap Moi.
Ninu oṣu kan naa, aarẹ tu awọn ologun ti wọn gbimọ lati gbajọba rẹ ka.
Ainidaniloju
Iṣẹlẹ iditẹ gbajọba lo fun Moi lanfani lati jẹ ki agbara rẹ pọ si nipa lile awọn to fẹ gbajọba danu. Bakan naa, lo ṣe ayipada iwe ofin ilẹ Kenya lati faye gba ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo
Gbogbo awọn alatako rẹ papa lo bori
Iye awọn to ṣẹwọn mitori oṣelu pọ si, bẹẹ ni Moi gbe igbesẹ lati din ominira awọn oniroyin ku.
Laarin ọdun 1990 ati 1999, ọpọlọpọ lati apa Rift Valley lo le danu, bakan ọpọ eeyan niroyin sọ pe wọn padanu ẹmi wọn ninu ija ẹlẹyamọnya.
''Mi o ṣetan lati dari orilẹede ọmuti.''- Daniel arap Moi
Iwadi
Moi gbe osẹlu ẹlẹgbẹjẹgbẹ pada, o si tun wọle lọdun 1992 ati 1997.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹsun nla kan ti wọn kan an ṣẹlẹ lọdun 1992.
Ẹsun ijale igba meji owo ti ijọba rẹ san bi owo ajẹmọnu fun ile isẹ Goldenberg lati polowo goolu ati okuta iyebiye orilẹede Kenya.
Lẹyin ọdun mẹrinla ni wọn fi ẹsun jibiti kan alakoso ile iṣẹ ọhun, akọwe agba ile ifowopamọ ati igbakeji oludari banki itẹwo.
Iwadi sọ pe aarẹ Moi mọ nipa iwa jibiti naa, ṣugbọn o ni ko si ohun to jọ bẹ, wọn o si gbe lọ sile ẹjọ.
Ninu idibo gbogbogbo lọdun 2002 ti wọn fofin de Moi, ọpọ lo fi ṣẹlẹya ti wọn si lẹ amọ mọ ọkọ rẹ.
Ẹgbẹ osẹlu rẹ Kanu fidi rẹmi. Koda ninu ayẹyẹ to fi gbejọba fun Mwai Kibaki, awọn eeyan yẹyẹ rẹ.
Lọdun 2007, Aarẹ Kibaki yab an aṣoju si orilẹede Sudan nitori iriri rẹ ati imọ rẹ nipa ọrọ ilẹ Afirika
Moi gbe igb aye rẹ to ku ninu ifẹyin ti, ti ko si dasi eto oṣelu kankan mọ.












