Báyìí ni akẹ́kòó mẹ́tàlá ṣé kàn àgbákò ikú lásìkò ijáde nílé ẹkọ ní Kenya

Oríṣun àwòrán, NATION MEDIA
Awọn akẹkọọ kan ti ku ti awọn ọgbọn miran si farapa lasiko wọduwọdu to waye nile ẹkọ alakọbẹrẹ kan ni iwọ oorun Kenya.
Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe awọn akẹkọọ naa n sare jade kuro ni kilasi wọn ni igba ti asiko ilọle to laago marun un irọlẹ.
Akọroyin BBC jabọ pe, awọn akẹkọ kan jabọ lati oke kẹta ile ẹkọ alakọbẹrẹ Kakamega Primary School.
Awọn akọroyin lagbegbe naa ṣe afihan bi awọn obi ati mọlẹbi ti ṣe peju si inu ọgba ile iwosan Kakamega lati gbọ iroyin nipa awọn ọmọ wọn.
Iku awọn ọmọ yi tunbọ pe akiyesi ara ilu si bi ko ti ṣe si aabo to peye fun awọn akẹkọọ ni ile ẹkọ Kenya.
Lọdun to kọja ni awọn akẹkọọ mẹjọ padanu ẹmi wọn ti mọkandinlaadọrin si farapa nigba ti ile ti wọn fi n ṣe ile ẹkọ kan wo lulẹ ni Nairobi.








