Arap Moi: Ọdún mẹ́rìnlélógún ló fi darí Kenya, tó sì di apàṣẹ wàá

Arap Moi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Bi itan aye Daniel Arap Moi se lọ ree ninu fidio yii, ẹni to fi ọdun mẹrinlelogun tukọ orilẹede Kenya.

Àkọlé fídíò, Arap Moi: Ọpọ lo ri ijọba rẹ bii onijẹkujẹ

Ìjọba Kenya kéde ọjọ́ ọ̀fọ̀ tí kò l'ópin lẹ́yìn ikú Moi

Orilẹ-ede Kenya ti kede asiko ti ko l'opin fun gbogbo ọmọ orilẹ-ede naa lati ṣọfọ, lẹyin ti aarẹ wọn to pẹ ju lori oye, Daniel arap Moi jade l'aye.

Ileewosan Nairobi lo ku si ni owurọ ọjọ Iṣẹgun, l'oju awọn mọlẹbi rẹ, gẹgẹ bi ikede kan ṣe sọ.

Kenya yoo ṣe ọfọ rẹ lati ọjọ kẹrin, oṣu Keji titi di ọjọ ti wọn yoo sin oku rẹ, botilẹjẹ pe wọn ko ti i kede ọjọ.

Awọn aarẹ ati olori ijọba orilẹ-ede agbaye ti n ba awọn eniyan Kenya kẹdun nitori iku aarẹ wọn tẹlẹ, Daniel arap Moi to jade l'aye ni owurọ kutu ọjọ Iṣẹgun.

Eto isinku lati ọwọ ijọba ni wọn yoo fun aarẹ nigba kan ri ọhun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eto isinku lati ọwọ ijọba ni wọn yoo fun aarẹ nigba kan ri ọhun

'Orilẹ-ede America darapọ̀ mọ́ Kenya láti ṣọ̀fọ̀ Moi'

Aṣoju, Kyle McCarter sọ pe ilẹ America wa pẹlu awọn eniyan Kenya lasiko ti wọn n ṣọfọ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

'Aarẹ Museveni ṣọfọ Moi'

Aarẹ Uganda, Yoweri Museveni ti kẹdun Daniel arap Moi. O sọ pe Moi jẹ ọ̀kan lara awọn olori ti oun wo ni awokọṣe nigba ti oun wa ni fasiti.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Aṣoju orilẹ-ede UK si Kenya ranṣẹ ibanikẹdun

Jane Marriot sọ pe oun ranṣẹ ibanikẹdun atọkan wa si ẹbí ati awọn ọrẹ, ati awọn eniyan Kenya.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Daniel arap Moi, ààrẹ Kenya tẹ́lẹ̀ jáde l'áyé lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́

Aarẹ tẹlẹ ni orilẹede Kenya, Daniel Arap Moi ti jade laye lẹni ọdun marundin lọgọrun.

Daniel Arap Moi jẹ aarẹ laarin ọdun 1978 si 2002

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Daniel Arap Moi jẹ aarẹ Kenya laarin ọdun 1978 si 2002

Aarẹ Moi lo jẹ aarẹ keji fun orilẹede Kenya lẹyin ti Jomo Kenyata fipo naa silẹ lọdun 1978.

Ọjọ keji, oṣu Kẹsan, ọdun 1924 ni wọn bi Moi.

Ọpọ awọn ti ko gba ti iṣejọba rẹ ri i gẹgẹ bi apaṣẹ wa a, to di ipo agbara mu fun ọdun mẹrinlelogun. Ṣugbọn, awọn to gba tiẹ gbe oṣuba fun un pe o jẹ ki nkan o lọ deede ni orilẹ-ede Kenya.

Ọdun 2002 ni Moi fi ipo silẹ, lẹyin ti ofin de e pe ko tun gbọdọ dije fun ipo aarẹ mọ.

Lasiko to wa ni ipo aarẹ, bi awọn eniyan ṣe bẹru rẹ naa ni wọn gba tiẹ. Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan an pe o tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.

Moi lo jẹ ki ẹgbẹ oṣelu o pọ si i ni Kenya l'ọdun 1991, ṣugbọn awọn eto idibo ti wọn ṣe lẹyin naa kun fun mago-mago.