Minimum Wage: NLCKwara fún ìjọba ní ọjọ́ mẹ́rìnlá láti yanjú owó oṣù tuntun

Awọn ẹgbẹ osisẹ to n fẹhonu han

Oríṣun àwòrán, NLC Hqr

Awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Kwara ti rawọ ẹbẹ si awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa, lati bẹrẹ aawẹ ati adura ọlọjọ mẹta, ki awọn nkan ti wọn n fẹ lọwọ ijọba lori owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju o le wa si imuṣẹ.

Ikede naa waye ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Aje.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ipinnu lati gba aawẹ ati adura waye lẹyin ipade kan ti wọn ṣe pẹlu awọn akẹẹgbẹ wọn latinu ẹgbẹ awọn ontaja, Trade Union Congress, ni ọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun 2020, ni ile ẹgbẹ wọn nilu Ilorin.

Atẹjade ti ẹgbẹ osisẹ ni Kwara fisita

Oríṣun àwòrán, Kwara NLC

Bakan naa ni wọn fi ẹnu ko lati fun ijọba ipinlẹ Kwara ni oore-ọfẹ ọjọ mẹrinla, bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni to kọja, ki o le yanju gbogbo ikunsinu to wa lori ọrọ owo oṣu naa.

Atẹjade ti ẹgbẹ osisẹ ni Kwara fisita

Oríṣun àwòrán, Kwara NLC

Ẹgbẹ naa l'opin ọrọ wọn ninu atẹjade naa sọ pe awọn ko fi ara mọ ọrọ kan ti kọmisana eto inawo ni Kwara, sọ lori ẹrọ redio kan pe igbimọ ti awọn gbe kalẹ ti faramọ igbesẹ ijọba lori owo oṣu tuntun naa.

Ati wi pe ẹnikẹni ko gbọdọ da ẹgbẹ oṣiṣẹ l'ẹbi to ba bẹrẹ iyanṣẹlodi lati beere awọn nkan to n fẹ.

Àkọlé fídíò, Ìjọba AbdulRazaq ti wólé aláànúú wa ní Ilorin

Ni ti aawẹ ati adura naa, yoo waye laarin ọjọ karun, oṣu Keji si ọjọ keje, oṣu keji, ọdun 2020.