Peju Ogunmola, àgbà òṣèré, tó tilé òṣèré jáde, tó tún di aya àgbà òṣèré

Aworan Sunday Omobolanle ati Peju Ogunmola

Oríṣun àwòrán, Instagram/official_pejuogunmola

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ti a ba n sọrọ nipa agba ninu ere sinima lorilẹede Naijiria paapa nidi ere sinima Yoruba, ọkan gboogi ni Adepeju Ogunmola.

Peju Ogunmola wa lati idile awon oṣere. O jẹ ọmọ fun agba oṣere to tun jẹ onkọtan, Kola Ogunmola.

Kola Ogunmola jẹ olukọ ile ẹkọ, to si fẹran ere siṣe. O tẹsiwaju lati jẹ ọkan ninu awọn oṣere to lamika lasiko rẹ ko to di pe o jaye laye lọdun 1973.

Bakan naa, Peju Ogunmole jẹ iyawo fun agba oṣere ninu ere sinima lorilẹede Naijiria, Sunday Omoboriowo.

O jẹ aburo fun Yomi Ogunmola, agba oṣere to jade laye ni ọdun 2003.

Arabinrin Peju Ogunmola wa lati ilu Okemesi, nipinlẹ Ekiti lorilẹede Naijiria.

Yatọ si pe o jẹ agba oṣere, Peju Ogunmola jẹ agba onkọtan, oludari ere ati olugbe sinima sita gẹgẹ bii ti baba rẹ, Kola Ogunmola.

Ninu ọrọ rẹ ti a ri ka lori ayelujara o ni. "Mo wa sinu aye yii, ti mo si ba ṣiṣe ere sinima lọwọ awọn obi mi.

"Ni bayii, ko si nnkan ti mo mọ ṣe bi ṣiṣe ere sinima ati pe ohun lo n fun ni ounjẹ."

Igbeyawo Peju Ogunmola

Aworan Sunday Omobolanle ati Peju Ogunmola

Oríṣun àwòrán, Instagram/official_pejuogunmola

Ni ọdun 1989, Peju Ogunmola ṣe igbeyawo pẹlu Sunday Omobolanle, ẹni ti ọpọ mọ si Papiluwe, to si jẹ iyawo keji fun agba oṣere alawada naa.

Ninu ọrọ ti Ọkọ rẹ, Sunday Omobolanle ba ileeṣẹ iroyin City People sọ lọdun 2017, o ni oun pade iyawo oun ni ile baba rẹ, Kola Ogunmola lasiko ti o n tẹlẹ baba naa kaakiri fun ere itage lasiko naa.

"Baba Peju jẹ baba fun gbpgbo wa. Nigba ti a bẹrẹ si ni ma rin irinajo kaakiri orilẹede, a pada si ile Baba Ogunmola ni ilu Eko.

"Peju kere lasiko naa, to si rẹwa ni obinrin. Mo ma fi n ṣe iwada pe ẹmi ni ma fẹ gẹgẹ bii iyawo.

"Peju yoo fesi pe oun ko ki n ṣe iyawo mi, ti oun ko si le fẹ mi ṣugbọn a pada jọ wa, ti a si ti wa fun ọpọ ọdun bayii, ti a si n tẹsiwaju."

Awọn sinima ti Peju Ogunmola kopa ninu rẹ

Aworan Peju Ogunmola, agba oṣere tiata Yoruba

Oríṣun àwòrán, Instagram/official_pejuogunmola

Apaadi (2009), Omo Ghetto: The Saga (2010) gẹgẹ bii iya Ayomide

King of Thieves (2022) gẹgẹ bii Lalopne

Beast of Two Worlds (2024) gẹgẹ bii Iyalode

House of Ga'a (2024) gẹgẹ bii Iyaloja

Maradona (2003), Mafi wonmi (2008), Toromade (2009), ati Apaadi (2009).