Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọkọ tó dáná sun ìyàwó rẹ̀ láàyè nítorí àwọ̀ ara obìnrin náà

Ikilọ: Awọn ohun to le ma ba ọkan rẹ́ wa ninu iroyin yii.
Ile ẹjọ giga kan lorilẹede India, ti dajọ iku fun ọkunrin kan to dana sun iyawo rẹ nitori àwọ ara obinrin naa.
Eeyan dudu ni iyawo naa ti orukọ rẹ n jẹ Lakshmi.
Ninu ọrọ to sọ ṣaaju iku rẹ, Lakshmi ṣalaye pe ọkọ oun torukọ rẹ n jẹ Kishandas, maa n daamu oun nitori awọ dudu ti oun ni.
Idaamu naa lo pada di ohun ti Kishandas dana sun iyawo rẹ laaye.
Nigba ti ọrọ dele ẹjọ, Adajọ Rahul Choudhary to dajọ ni ẹkun Ariwa ilu Udaipur, India, sọ pe ipaniyan ti ọkọ yii ṣe fun iyawo rẹ buru jai, o si lodi si iwa ọmọniyan ẹlẹran ara.
Ṣugbọn agbẹjọro ọkọ iyawo sọ fun BBC pe Kishadas ko jẹbi, o ni awọn yoo pe ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun lori idajọ yii.
Ọdun kẹjọ ree ti Lakshmi ti dagbere faye, ti idajọ rẹ si ṣẹṣẹ waye lopin ọsẹ to kọja.
Latigba naa lo ti di ohun ti awọn iwe iroyin n gbe yẹẹ-yẹẹ-yẹẹ ni India, ti wọn n kọ nipa orilẹede kan ti awọ ara eeyan ti mumu laya wọn.
Iṣẹlẹ iku Lakshmi waye loru ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa ọdun 2017.
Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣááju?
Ninu ọrọ ti kootu fi silẹ pe Lakshmi sọ koo too jade laye, eyi ti awọn ọlọpaa fi ṣọwọ si kootu, to si de ọdọ awọn dokita to tọju rẹ pẹlu lo ti ṣalaye pe lati 2016 toun ti fẹ ọkọ naa lo ti maa n fi awọ ara bu oun.
Lakshmi sọ pe ọkọ oun maa n pe oun ni 'Kali', to tumọ si alawọ dudu. Bẹẹ lo tun maa n fi eebu ara bu oun.
Loru ọjọ to ku, ọkọ rẹ, Kishandas, gbe ike kan ti nnkan olomi alawọ erupẹ wa ninu rẹ wale- O ni oogun ti yoo mu iyawo oun pupa ni.
Gẹgẹ bi akọsilẹ naa ṣe tẹsiwaju, o fi kinni ọhun pa iyawo rẹ lara, nigba ti iyawo si sọrọ pe kinni naa da bii asiidi, omi oro, niṣe lo sọ ina si I lara pẹlu igi turari.
O tun da kinni naa to ṣẹku si i lara bo ṣe n jona lọ, o si sa lọ kuro nile.
Awọn ẹbi iyawo lo gbe e lọ sileewosan, nibi to pada dakẹ si.
" Ki i ṣe asọdun bi a ba sọ pe Lakshmi nikan kọ ni iwa buruku yii kan, gbogbo ọmọniyan pata ni" Adajọ Choudhary lo sọ bẹẹ.
O ni Kishandas dalẹ, o si huwa to buru jai nigba to tun da omi iku naa si iyawo rẹ lara bo ṣe n jona, to si waa sa lọ.
Agbẹnusọ ijọba, Dinesh Paliwal, ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bii eyi ti ko ni i parẹ ninu itan.
"Ọdọbinrin ti ọjọ ori rẹ wa laaarin ogun ọdun ni wọn pa nipa ika bẹẹ. Aburo ẹnikan ni, ọmọ ẹnikan ni, oun naa ni awọn eeyan to fẹran rẹ. Bi a ko ba ja fun ẹtọ awọn ọmọ wa obinrin bayii, ta ni yoo ba wa ja fun wọn?"
Paliwal lo beere bẹẹ.
O ni oun ti fi ẹda idajọ naa ranṣẹ si ile ẹjọ giga lati fi idi idajọ iku mulẹ fun ọkọ to pa iyawo rẹ.
O ni ṣugbọn o ni anfaani lati pe ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun wa fun un laaarin asiko idajọ naa si ọgbọn ọjọ.
Ikú yẹn ṣẹ̀ṣì ni, oníbáàrà mi ò jẹ̀bi- Agbẹjọ́rò ọkọ ìyàwó
Agbẹjọro ọkọ ìyàwó, Surenda Kumar Menariya, ṣalaye fún BBC pe iku Lakshmi ṣeṣi ni.
O ni ko si ẹri kankan to tako oníbàárà oun ti wọn n fẹsun kan lori ohun ti ko ṣe.
Lọọya ọkọ iyawo sọ pe awọn yoo pe ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun ta ko idajọ yii.
Ohun kan to daju ni pe idájọ́ kootu yii tun tan imole si bi àwọn èèyàn India ṣe nífẹ̀ẹ́ si awọ̀ pupa ju dudu lọ.
Orúkọ abuku ni won maa n pe àwọn ọmọbìnrin ati agba obìnrin to ba ni awọ dúdú, wọn si maa n déyẹ si wọn gidi.
Kódà, àwọn to n ta ipara ibora ti n ri taje ṣe daadaa bayii latari awon obinrin tó n ra a lati di aláwọ̀ pupa, èrè bílíọ́nù dọ́là la gbọ pe won n jẹ lori ipara ibora.
Tọrọ ba di ti ìgbéyàwó, àwọn ọmọge pupa ni àwọn okunrin n fẹ́.
Koda, BBC ti figba kan kọ iroyin awon iyawo ile to pa ara won nítorí ìdààmú ti ọkọ n fun wọn nítorí wọn ko pupa.
Ṣaa, bi ọlaju ṣe n de si i bayii ni àwọn olupolongo ti n kede tako igbagbọ àwọn to gba pe ki obinrin pupa lo daa ju, won n jẹ ko ye wọn pe awọ ara ko túmọ̀ sí nnkan kan.
Ṣùgbọ́n wọn ni ko rọrùn láti yi igbagbọ adẹyẹsini naa pada, bi ko ba si yipada, yoo maa baye jẹ si i ni.














