Ilẹ̀ yíya ti pa èèyàn 370 ní Sudan

Awọn eeyan laarin ẹbiti ilẹ to ya.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan agbegbe naa n gbiyanju lati wa ọna fi wọn yoo fi mojuto ara wọn lẹyin iṣẹlẹ ilẹ yiya naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iṣẹlẹ ilẹ yiya kan to waye lagbegbe orioke Marra lẹkun iwọ oorun orilẹede Sudan ti gbẹmi eeyan to din diẹ ni irinwo.

Gẹgẹbi ohun ti ajọ iṣọ̀kan agbaye, UN sọ fun BBC o ṣi ṣoro lọwọ yii lati sọ ni pato iye awọn eeyan to ti ku ninu ajalu ọhun.

Igbakeji alamojuto fun eto iranwọ fun orilẹede Sudan, Antoine Gérard sọ pe wọn ṣin sa ipa lati doola awọn eeyan, ṣugbọn o n ṣoro fun wọn lati ṣe bẹẹ nitori pe agbegbe naa nira lati de.

Ikọ ọmọogun agbebọn, Sudan Liberation Movement/Army, to n ṣakoso agbegbe naa ti kọkọ sọ ninu atẹjade kan ti wọn fi sita pe awọn ẹmi to tik u sinu iṣẹlẹ ti le ni ẹgbẹrun kan.

Ojo arọọrọda to rọ lagbegbe naa lo fa ilẹ to yan aa lọjọ Aiku, eyi to gbẹmi eeyan kan to si tun "gbe ọpọlọpọ agbegbe ileto Tarseen mi, gẹgẹbi wọn ṣe sọ ninu atẹjade naa.

Ikọ ọmọogun naa rawọ ẹbẹ sawọn ajọ ẹlẹyinju aanu ni UN atawọn ẹkun ati kaakiri agbaye fun iranlọwọ.

Awọn eeyan n rin laarin igbo kan to wa lẹgbẹ oke kan.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn ajọ ẹlẹyinjuaanu ti n sọ pe iṣoro nla ni dide agbegbe ti ilẹ yiya naa ti waye, nitori bi oju ọjọṣe ri ati bi ilẹ agbegbe

Wahala ogun to n bẹ silẹ lo le ọpọ awọn eeyan lọsi agbegbe orioke Marra naa

Ọgbẹni Gérard sọ pe, yoo nira lati ko awọn nnkan iranwọ de awọn agbegbe naa.

"A ko ni baluu, ọkọ nikan la fi n ko awọn ẹru lawọn oju popo to nira lati rin naa. Eyi yoo gba ọpọlọpọ asiko, bẹẹni asiko ojo la way ii - ọpọlọpọ igba, a maa ni lati duro fun ọpọlọpọ wakati, tabi gan ojọ kan si meji ki a to le kọja lawọn afonifoji… fifi ọkọ ko ẹru yoo lagbara.

Ọpọ awọn olugbe ipinlẹ North Darfur lo ti di ogunlende si agbegbe orioke Marra nibi ti wọn ti n sa asala lọna ati bọ lọwọ ogun to n bẹ silẹ laarin ileeṣẹ ọmọogun Sudan atawọn ọmọogun Paramilitary Rapid Support Forces (RSF) .