'Àwọn tó jí mi gbé yìnbọn mọ́ mi, wọ́n fi mí sílẹ̀ l'ágbàrá ẹ̀jẹ̀ láì mọ̀ pé mi ò tíì kú'

- Author, Alfred Lasteck
- Role, BBC News in Mbeya
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10
Ìkìlọ: Awọn ọrọ kan wa ninu iroyin yii ti o le ma ba ọ lọkan jẹ.
Ko sibi ti ìṣe ko si.
Gbajumọ ori ayelujara ni ọkunrin kan, Edgar Mwakabela, lorilẹede Tanzania. Ọkan lara awọn to maa n sọrọ tako ohun ti ko tọ ni, lai wo ẹni ti pẹtẹpẹtẹ ọrọ naa le ta ba.
Ṣugbọn awọn ajinigbe ji i gbe lọdun to kọja wọn si tun yinbọn lu u ni igboro Tanzania ti i ṣe Dar es Salaam, o royin pe oun ri aburo iku bo tilẹ jẹ pe, oun ko ba iṣẹlẹ naa lọ.
Edgar Mwakabela ti awọn eeyan tun mọ si Sativa, ṣalaye irinajo ijinigbe naa fun BBC pe, nigba ti wọn ji oun gbe lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa ọdun to kọja, awọn ajinigbe naa kọkọ bẹrẹ si i fi ọrọ wa oun lẹnu wọ gidi.
O ni lẹyin naa ni wọn gbe oun gba ori omi kọja lọ si ẹnu ibode orilẹede Congo, apa ibi to wọnu jingun-jingun ti wọn n pe ni Katavi lo ni wọn gbe oun lọ. Iyẹn si to kilomita 1,000km (600 miles).
Ninu alaye naa lo ti ni niṣe ni wọn so oun ni ṣẹkẹsẹkẹ lọwọ, wọn fi aṣo bo oun loju wọn si fẹrẹ lu oun pa, bẹẹ naa si ni wọn n fi pẹ̀tẹ́pẹ̀tẹ́ ada gba ori oun leralera, ati ẹsẹ pẹlu ẹyin oun.
"O lagbara pupọ."
Lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn ji i gbe, ifiyajẹni naa n tẹsiwaju nigba ti wọn gbe Sativa lọ si ibi ti a mọ si Katavi National Park. Ibudo yii kun fun oniruuru ẹranko buruku, bẹẹ ni wọn wọ ọ lọ siwaju odo kan bii ki wọn ju u sibẹ ko ku. Oun naa sọ ọ, pe o daju pe awọn to ji oun gbe naa ko fẹ ki oun yè, wọn fẹẹ gba ẹmi lẹnu oun patapata ni.
O ni nigba naa ni ẹnikan ke lohun rara pe: "Ẹ yinbọn fun un!"
Wọn fa ibọn, ọta ibọn kan si jade lẹsẹkẹsẹ, o wọ agbari rẹ lọ. Ibọn naa lo fọ ijagbọn rẹ, ẹjẹ bẹrẹ si i ya.
Nigba naa ni wọn si fi i silẹ sibẹ, ti wọn ba tiwọn lọ.- Wọn ro pe o ti ku ni .
Bi ibo apapọ ti wọn fẹẹ di loṣu Kẹwaa ṣe n sunmọle si i, bẹẹ ni ijinigbe ṣe n pọ si i, awọn eeyan to si n sọrọ tako ijọba ni wọn saba n ji gbe.

Ẹni orí yọ ó dilé ni àwọn mí-ìn fi lè sọ ohun tójú wọn rí, àwọn kan ti kú sóko ajínigbé
O fẹrẹ ma si ọsẹ kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i kede pe ẹnikan tun ti sọnu, awọn n wa a. Bẹẹ naa lo si ṣe n jade lori ayelujara. Awọn kan wa ti wọn ko tilẹ ri mọ, wọn si le pada ri awọn mii ti wọn yoo wale waa royin aburu gbogbo ti wọn koju lagbala awọn ajinigbe – oku awọn mii ni wọn yoo si pada ri.
Ni ti Sativa yii, ẹni ori yọ o dile ni lo fi ri iroyin ara rẹ sọ lai ku sigbekun ajinigbe.
Lẹyin to ji saye pada, Sativa ra pala de oju ọna, nibi ti awọn ti wọn n ṣọ agbegbe awọn ẹranko abija ti ri i ti wọn si ran an lọwọ.
Sativa sọ fun BBC pe awọn to ji oun gbe kuku sọ idi rẹ ti wọn fi gbe oun, o ni ohun ti wọn sọ ni pe oun n lọwọ si ijijagbara, ati pe ki ni idi rẹ t'oun fi n naka aleebu si ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ, ẹgbẹ Chama Cha Mapinduzi .
Ninu ọrọ rẹ, Sativa ni oun gbagbọ pe awọn ọlọpaa lo gbe oun pamọ, tabi ko jẹ awọn alagbara kan to ni i ṣe pẹlu awọn to wa nipo aṣẹ.
Ṣugbọn ṣaa, ijọba loun ko lọwọ ninu dida oju sọ awọn ajijagbara ilu Tanzania.
Igbiyanju BBC lati ba awọn ọlọpaa ṣe ifọrọwanilẹnuwo ko kẹsẹ jari, nitori awọn agbofinro naa ko da wa lohun, ṣugbọn ninu fidio kan ti wọn fi ranṣẹ si awọn ileeṣẹ iroyin loṣu Kẹfa, Agbẹnusọ fun igbakeji kọmiṣanna, David Misime, sọ pe awọn maa n tẹle ohun ti awọn ba gbọ nipa awọn to ba di awati, awọn si maa n tọpinpin ohun to ṣẹlẹ gan-an ati ohun ti awọn eeyan ba n sọ nipa rẹ.
BBC ti ba ẹbi awọn ti eeyan wọn sọnu sọrọ, atawọn ti eeyan wọn ti ku si oko ijinigbe, wọn si ṣalaye ibanujẹ ọkan wọn lori ẹni bii ọkan wọn ti wọn padanu.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣì ń wa ayàwòrán; Shedrack Chaula, tó dáná sun àwòrán ààrẹ

Oríṣun àwòrán, The Citizen
Ayaworan Shedrack Chaula, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) naa ko ti i je riri, wọn ṣi n wa a.
Ko sẹni to ri i tabi gbọ nnkan kan nipa rẹ fun bii ọdun kan bayii. Loṣu Kẹfa ọdun 2024, Shedrack ju fidio kan soju opo Tiktok. Ninu fidio naa lo ti n dana sun aworan Aarẹ orilẹede Tanzania, Samia Suluhu, to si tun n bu u. Fidio naa lọ kari aye gan-an.
Wọn fọwọ ofin mu un lori eyi, wọn fẹsun didunkoko mọni lori ayelujara kan an pẹlu, won si fi i silẹ lẹyin to sanwo itanran. Ṣugbọn oṣu kan lẹyin rẹ, awọn ajinigbe tẹnikan ko mọ ji i gbe lọ.
"A ko mọ igba ti wọn yoo ri i, tabi boya a ti ẹ maa ri i mọ rara. Nigba ti wọn mu un, a mọ ibi to wa. Ṣugbọn ni bayii, awọn alaṣẹ gan-an sọ pe awọn ko mọ bo ṣe rin irin rẹ ni."
Baba Shedrack, Yusuf Chaula, lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
O ni loṣu Kẹjọ odun 2024, awọn ọkunrin mẹta kan to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ ti ẹnikẹni ko le ri inu rẹ, de, wọn si gbe Shedrack lọ.
Wọn ko sọ bi wọn ṣe jẹ, bẹẹ ni wọn ko sọ idi ti wọn fi n gbe e lọ tabi ibi ti wọn tilẹ n gbe e lọ rara.
Baba rẹ ni gbogbo ipa lawọn ti sa lati ri i, ṣugbọn pabo lo n ja si, ati pe o tilẹ ti su oun. Gbogbo teṣan ọlọpaa titi to de ọgba ẹwọn lo ni awọn wa Shedrack de, ṣugbọn ẹkọ ko ṣaa ṣe ojuu mimu naa ni.
''Mo ń bẹ ìjọba kí wọ́n fi ọkọ mi sílẹ̀, láti oṣù Karùn-ún ni wọ́n ti gbé e lọ''

Iṣẹlẹ ijinigbe mi-in to tun gbomije loju awọn to kan ni ti ọkunrin oloṣelu kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako niTanzania. Orukọ ọkunrin naa ni Mpaluka Nyangali, inagije rẹ si ni Mdude, bo se jẹ oloṣelu lo tun jẹ ajijagbara.
Niṣoju iyawo ati ọmọ rẹ kekere ni wọn ti gbe e lọ loṣu Karun-un, nile rẹ to wa ni Mbeya, ni Guusu Tanzania, ojubọrọ kọ ni wọn fi gbe e lọ, o mu jagidijagan dani.
Koda, aworan iṣẹlẹ naa fi ibi ti ẹjẹ ti wa nilẹẹlẹ han, to n ṣapejuwe bi ikọlu ọhun ṣe lagbara to.
Latigba naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako, Chadema, ti bẹrẹ si i wa a kaakiri agbegbe Mbeya, bi wọn sẹ n gba adura ni wọn n ṣe iṣọ oru, ti wọn si tun n beere lọwọ awọn ọlọpaa pe ibo ni Mdude wa, wọn lawọn fura pe ọwọ awọn ọlọpaa ko mọ si gbigbe ti wọn gbe ajijagbara naa lọ.
Titi doni, Iyawo Mdude, Siji Mbugi, ko ti i foju kan an .
"Mo n bẹ wọn ki wọn fi ọkọ mi silẹ, mo gbagbọ pe awọn ọlọpaa lo ti i mọle. Mdude o ṣe ẹṣẹ kankan, ko jale ẹnikẹni ri, mo bẹ wọn ki wọn fi i silẹ. To ba ni ohunkohun ti wọn fẹẹ ba a fa, ki wọn gbe e lọ si kootu." Bẹẹ ni Siji Mbugi, iyawo Mbude wi.
Lọjọ kẹsan-an, oṣu Keje, ile ẹjọ giga da ẹjọ ti obinrin yii pe nipa ai ri ọkọ rẹ nu.
Alaye to ṣe ni kootu lasiko igbẹjọ naa ni pe awọn kan to dihamọra ogun, ti wọn pe ara wọn ni ọlọpaa, ya wọ ile awon lọwọ alẹ, wọn si lu ọkọ oun bii bara ki wọn too gbe e lọ.
Lasiko igbẹjọ naa, awọn ọlọpaa Mbeya ṣalaye pe awọn n ṣewadii nipa boya ọkan lara awọn lọwọ ninu bi Mbude ṣe di awati.
Bi Adajọ ṣe waa da ẹjọ naa nu ni awọn ajafẹtọọ ọmọniyan koro oju si, wọn ni ifasẹyin gbaa lo jẹ fun Tanzania nipa idajọ ododo ti wọn wa lori ọrọ awọn ẹgbẹ alatako.

Àwọn ọlọ́pàá ní àwọn ń ṣèwádìí, ṣùgbọ́n wọn kò tí ì mú ẹnìkan lórí àwọn tó di àwátì
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ni awọn ṣi n ṣewadii lori awọn iṣẹlẹ ijinigbe yii, wọn ko ti i mu ẹnikẹni lorii rẹ.
Eyi ni awọn ajafẹtọọ fi n sọ pe awọn alaṣẹ orilẹede Tanzania n tẹ ẹtọ awọn eeyan loju mọlẹ.
Boniface Mwangi lati Kenya, ati Agather Atuhaire lati Uganda, sọ pe wọn fi awọn si ahamọ, wọn si ṣe awọn baṣubaṣu lẹyin tawọn de inu gbaga lọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un.
Awọn mejeeji naa ni ẹnikẹni ko si mọ ibi ti wọn wa fun ọpọ ọjọ.
Ko pẹ ti wọn de Tanzania lati wo igbẹjọ olori ọmọ ẹgbẹ alatako, Tundu Lissu, ni wọn mu wọn fun awọn ẹsun to tako alaafia orilẹede.
Ṣugbọn niṣe ni wọn pada gbagbe wọn si itosi ẹnu ibode orilẹede wọn.
Jumanne Muliro, ọga agba ẹka ọlọpaa Dar es Salaam, sọ fun BBC pe ahesọ lasan ni ẹsun ti awọn eeyan naa fi kan ijọba. O ni ki wọn mu ẹri wa. Wọn si ti pe ẹjọ kan si apa Ila-Oorun Africa lori ọrọ yii.
"Ko ṣeni kan to n fun wa lesi lori ohun to n ṣẹlẹ." Maduhu William, ajafẹtọọ ọmọniyan ni Legal and Human Rights Centre (LHRC) lo sọ bẹẹ. O fi kun un pe awọn eleto aabo sọ pe awọn yoo ṣewadii, ṣugbọn ibi to pari si naa niyẹn.
"Lẹyin gbogbo ẹ naa, a ko gbọ nnkan lori awọn ẹjọ yii mọ"
O fi ọrọ Ali Kibao, oṣiṣẹ Chadema kan ti wọn pa lọdun to kọja ṣe akawe. Lẹyin ti wọn ji i gbe ni wọn lu u bii ko ku, wọn si pada da omi oro asiidi (Acid) si i lara to fi ku.
"Koda, Aarẹ Samia gan-an ni ki wọn ṣe iwadii lori awọn iṣẹlẹ yii ki wọn si mu abọ wa, ṣugbọn titi doni, a ko gbọ nnkan kan."
Boniface Mwabukusi, Aarẹ ẹgbẹ amofinTanganyika, sọ pe ọpọ eeyan ni ẹru n ba lati jade waa sọ ohun to ṣẹlẹ si wọn, ko ma baa di ohun ti wọn n dẹyẹ si wọn.
O ni ko si ilana kankan to fi idajọ ododo han.
"Bi o ba wa ni ahamọ ọlọpaa, ti awọn ọlọpaa si ni ki i o kọ ohun ti o mọ silẹ nigba ijinigbe rẹ, ṣe o le lọọ ba wọn? Eeyan o ni le lọ." Bẹẹ ni Mwabukusi wi.
"Ọpọ eeyan maa n fi gbogbo rẹ silẹ fun Ọlọrun ni. Ẹru n ba wọn, wọn ni bawọn ba gbe igbesẹ kankan lori ohun toju n ri, ọrọ le bẹyin yọ ko tun buru si i".














