Àṣeyọrí ńlá ló jẹ́ fún wa bí Simon Ekpa ṣe dèrò ẹ̀wọ̀n- Ìjọba Àpapọ̀ Nàìjíríà

Aworan Simon Ekpa ti ile ẹjọ Finland sọ si ọgba ẹwọn fun ọdun mẹfa

Oríṣun àwòrán, Screengrab/Simon Ekpa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ṣapejuwe igbẹjọ to waye fun ọkan lara awọn olori ikọ IPOB, Simon Ekpa lori ẹsun agbesunmọmi gẹgẹ bii aṣeyọri nla fun ilakak ijọba lati dẹkun iwa igbesunmọmi lorilẹede Naijiria.

Minisita fun eto iroyin, Mohammed Idris lo sọ eyi ninu atẹjade to fi sita lẹyin igbẹjọ Simon Ekpa, ti ileẹjọ Finland ni ko lọ lo ọdun mẹfa lọgba ẹwọn.

"Aṣeyọri nla ni eyi fun gbogbo igbinyanju orilẹede Naijiria nipa gbigbe ogun ti iwa igbesunami," Mohammed sọ ninu ọrọ to gbe soju opo ayelujara X.

"A tẹ wọ gba idajọ ile ẹjọ Finland nipa Simon Ekpa lori ẹsun igbesunami ti wọn fi kan ati pe ko lọ lo ọdun mẹfa ni ọgba ẹwọn.

"Aṣeyọri nla ni eyi fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati tako igbesunami."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Simon Ekpa ọ̀kan lára agbódegbà ẹgbẹ́ Ipob rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà he ní Finland

Simon Ekpa

Oríṣun àwòrán, Simon Ekpa/x

Iléẹjọ́ rán Ileẹjọ ẹkun Päijät-Häme ti ran Simon Ekpa lọ si ẹwọn ọdun mẹfa lori ẹsun igbesunmọmi atawọn ẹsun miran.

Gẹgẹbi iwe ileẹjọ naa ti akọwe ẹkun naa fi ranṣẹ si BBC News Pidgin lọjọ Aje ile ẹjọ naa ni Simon Ekpa, to jẹ ọkan awọn to wa lẹyin ẹgbẹ Ipob n lọwọ ninu iwa igbesunmọmi, o n ko araalu sodi lati hu awọn iwa to rọ mọ igbesunmọmi, o ja ilu lole owo ori to si tun n ṣẹ si ofin to de awọn amofin lorilẹede Finland.

Wọn ni ki Ekpa ṣi w ani ahamọ na

Lori ẹsun ti igbesunmọmi, ile ẹjọ naa ni Ekpa n gbimọ lati ja fun ominira ẹkun to pe ni Biafra fun ẹkun ila oorun gusu NAijiria lọna ti ko bao fin mu laarin oṣu kẹjọ ọdun 2021 si oṣu kọkanla ọdun 2024.

"O n lo ayelujara lati waa ipo oṣelu, bẹẹ lo n lo rukerudo to n waye laarin awọn ẹgbẹ ajijagbara lorilẹede NAijiria lati sọ ara rẹ di ogbontagi laarin wọn".

Wọn ni o tun da ẹgbẹ agbebọn silẹ labẹ igbekalẹ ijijangbara to n gbe kari.

"Ekpa n ko nnkan ija oloro, ado oloro atawọn ọta ibọn fun awọn ẹgbẹ ajijangbara naa nipasẹ awọn agbodegba rẹ."

Wọn ni o tun n lo oju opo ayelujara X lati ru awọn to n tẹle soke lati hu iwa ibi.

Ta ni Simon Ekpa ati pe ki lawọn ohun to ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni oṣu kejila ọdun 2024 ni awọn alaṣẹ orilẹede Finlad fi panpẹ ofin gbe Simon Ekpa fun ẹsun igbesunmọmi

Laarin ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹjọ ọdun 2021 ni wọn ni o bẹrẹ si ni hu iwa ọdaran naa ni ilu kan ti wọn pe ni Lahti

Ọmọ bibi ipinlẹ Ebonyi lẹkun ila oorun gusu NAijiria ni Simon Ekpa. Ere idaraya ọlọgọrun mita si ni ọpọ kọkọ fi gbọ okiki rẹ. O ṣoju Naijiria nibi idije ere idaraya ori papa fun awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ lọdun 2003 to si gba ami ẹyẹ fadaka nibi idije naa.

Talẹnti rẹ yii lo sig be e lọ si oke okun lorilẹede Finland, toun pẹlu fi di mọ orilẹede naa.

Ekpa bẹrẹ sin ii gbe ni ilu Lahti, pẹlu ọmọ orilẹede Finland kan, Marianne Säkäjärvi, to fẹ ni iyawo ati ọmọ meji ti Eleduwa fi ta wọn lọrẹ; ki wọn to pinya.

Simon Ekpa bẹrẹ si ni kopa ninu eto oṣelu ni ilu Lahti, ti wọn si yan an gẹgẹ bi ọmọ igbimọ iṣejọba ibilẹ ni Ẹkun Lahti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu National Coalition Party (NCP) to n ṣe ijọba lorilẹede naa bayii.

Ẹkpa jẹ ọkan lara awọn to n ṣe atilẹyin fun Nnamdi Kanu, aṣiwaju ẹgbẹ Ipob to n pe fun idaduro ẹya Igbo kuro lara Naijiria .