Èèyàn tó lé ní 600 kú nínú àjálù ilẹ̀ ríri ní Afghanistan, èèyàn 1500 míràn farapa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko din ni ẹgbẹta eeyan to ti jade laye lẹyin ti iṣẹlẹ ajalu ilẹ riri waye ni orilẹede Afghanistan.
Bakan naa ni iye awọn to farapa ti le ni ẹgbẹrun kan ati ọọdunrun, gẹgẹbi awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọrọ abẹnu lorilẹede naa ṣe sọ.
Agbegbe Jalalabad, to jẹ iwọn ogoje kilomita si Kabul, olu ilu orilẹede naa ni ilẹ riri naa ti ṣọṣẹ julọ
Awọn alaṣẹ fi to BBC News leti pe ọpọlọpọ ile ni iṣẹlẹ naa wo lulẹ.
Ninu ọrọ rẹ, agbẹnusọ fun ijọba Taliban lorilẹede naa ṣalaye loju opo X pe ajalu ilẹ riri naa ti 'gba ọpọlọpọpọ ẹmi, to si tun ba ọpọlọpọ dukia jẹ pẹlu lawọn agbegbe kan lẹkun ila oorun orilẹede wa".
Iroyin sọ pe awọn agbegbe to wa lawọn ibi ti oke nlanla pọ si lẹkun naa ni ilẹ riri ọhun ti ṣọṣẹ julọ to si n mu ki o nira fun awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi lati le tetet de ibẹ ṣe iṣẹ wọn
Bakan naa la tun gbọ wi pe, pupọ awọn to ku ninu ajalu ilẹ riri naa wa lagbegbe Kunar.
Ijọba Taliban to n ṣe akoso orilẹede naa sọ pe iye awọn to ti ku bayii ti le ni ẹgbẹta ati mẹwaa nibẹ.
Wọn fi kun un pe awọn mejila miran ti ku lagbegbe Nangarhar.
Amọṣa, iroyin nipa ọṣẹ ilẹ riri naa ṣi n wọle diẹdiẹ.












