Gbẹ̀rẹ̀bì, àbàwọ̀n àmì tó ń kojú àwọ̀ ara, àti bí o ṣe lè kojú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun ti a n pe ni gbẹrẹbi jẹ ọkan lara awọn ami to ṣe ajeji si ara eeyan. O maa n farahan nigba mi-in ti yoo mu awọ Elese Aluko (Purple) wa, yoo si tun yi awọ pada to ba ya.
Ara obinrin ni gbẹrẹbi ti wọpọ ju, bo tilẹ jẹ pe o maa n mu ọkunrin pẹlu.
Ohun idojuti ni ọpọ eeyan mọ gbẹrẹbi si, nitori o maa n ṣoro fun awọn to ba ni i ti wọn si mọ pe abawọn ni lati ṣi ara silẹ, tabi wọ aṣọ to ba wu wọn.
Ki lo wa de ti gbẹrẹbi n han lara awọn kan ti ko si ki n mu awọn eeyan mi-in? Ki lo tiẹ n fa gbẹrẹbi ọhun? Nibo ni gbẹrẹbi ti wa? Ṣe o ṣee ṣe fun wa lati jẹ ko parẹ lara lẹyin to ba ti wa lara eeyan tan?
Àlàyé rèé
"Àwọ̀ ara tí iṣoro kan ba kọlu ló ń fa gbẹ̀rẹ̀bí"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nipa ohun to n fa gbẹrẹbi, onimọ nipa awọ ara lati orilẹede Benin; Dokita Franck Olivier Yedomon, ṣalaye pe nigba ti apa ibi kan ninu awọ ara ti a mọ si dermis, ba ni iṣoro ni gbẹrẹbi maa n jade lara.
" O ṣe pataki lati mọ pe ipin mẹta ni awọ ara eeyan pin sin: Loke patapata ni a ti ni eyi ti a n pe ni Epidermis, to maa n paarọ ara rẹ ni gbogbo ọjọ mọkanlelogun.
"Ikeji ni awọ ara aarin ti a mọ si Dermis, ikẹta to wa nisalẹ si ni Hypodermis, oun ni ọra."
" Igbagbọ to lodi ni lati ro pe obinrin nikan ni gbẹrẹbi maa n mu, awọn ọkunrin kan naa maa n ni ibi ti gbẹrẹbi ti han lara wọn"
Bẹẹ ni Dokita Yedomon ṣalaye.
O ni awọn ọkunrin to ba ni gbẹrẹbi maa n sanra.
Awọn ibi to ni o ti maa n han lara obinrin ju ni awọ ara, itan ati ibadi, igẹ si lo ni o ti maa n han lara ọkunrin ju.
Orísun gbẹ̀rẹ̀bí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbagbọ ọpọ eeyan ni pe ẹni to ba sanra lo maa n saba ni gbẹrẹbi, ṣugbọn Dokita Franck Olivier Yédomon ni ko ri bẹẹ.
"Bi apa kan awọ ara ba ti pin sọtọ ninu iṣan lọhun-un, boya lasiko ti eeyan n sanra si i ni, tabi nigba ti eeyan ba wa ninu oyun, o ṣee ṣe ki gbẹrẹbi jade si i lara.
"Ṣugbọn o tun ṣee ṣe ki eeyan ni gbẹrẹbi lasiko to ba rù naa, ti gbẹrẹbi naa yoo jade kia."
"Nigba ti awọ ara ba ti sán, gbẹrẹbi yoo jade nibẹ. Awọn sẹẹli kan wa ti a n pe ni fibroblasts, awọn ni wọn n pese eroja collagen ati elastin ninu ara.
Bi ara ba koju ohun ti ko fẹ, gbẹrẹbi le jade si ara."
Awọn nnkan mi-in to le fa gbẹrẹbi bi Dokita ṣe sọ ni ti obinrin ba loyun, tabi to ba sanra asanju.
Ibi itan lo ni ara sisan obinrin maa n wọpọ si, ti ọkunrin si ni ibi igẹ wọn.
Bakan naa ni Dokita Yedomon kilọ, pe aṣeju ere idaraya lai sinmi naa le fa gbẹrẹbi sara.
"Bi eeyan ba n na pọnpọn ju, to ba kọja ibi to yẹ ninu awọ ara, ti ko si si pe wọn ba eeyan to ara deede (regular massages), o le fa gbẹrẹbi sara."
Kirimu lilo ni Dokita sọ pe o tun maa n fa gbẹrẹbi si ara awọn ẹlomi-in.
O ni bi ipara wọn ba ni eroja 'corticosteroids' ninu, eyi to pọ lọja Africa kiri, o ṣee ṣe ki gbẹrẹbi ṣeyọ lara .
"Lọpọ igba, awọn obinrin maa n lo o pẹlu erongba lati bora.
"Nigba ti awọ ara wọn ba si ti yi kuro ni eyi ti wọn ni latilẹ, wọn yoo maa ri gbẹrẹbi to n jade lara wọn. Iru gbẹrẹbi yii maa n yatọ diẹ si iru eyi to maa n jade lara obinrin lasiko iloyun, tabi nigba ti wọn ba sanra, nitori awọn eleyii maa n jinlẹ gan-an."
Dokita Yedomon lo ṣalaye bẹẹ.
Bí o ṣe lè kojú gbẹ̀rẹ̀bí
Bo tilẹ jẹ pe awọn epo kan ti wọn maa n lo lati to ara (Oil massages) ni ọpọ eeyan maa n lo ju lati koju gbẹrẹbi, Dr Yedomon sọ pe eeyan le lo oogun rẹ pẹlu ti yoo si koju gberẹbi naa ni ida aadọrin si aadọrun-un (70- 90%).
Awọn itọju kan naa tun wa to ni i ṣe pẹlu atẹ plasma, wọn si tun maa n gun awọn ẹlomi-in ni abẹrẹ collagen lati ṣẹgun gbẹrẹbi.
''Bi o ba ni gbẹrẹbi to lagbara, o le gba ọ ju oṣu mẹfa lọ lati tọju rẹ ti yoo si lọ. Awọn gbẹrẹbi kan tun wa ta a mọ si 'acute stretch marks, awọn yẹn le ma gba ọ ju oṣu meta lọ lati kapa wọn.''
Ohun tí olóyún lè ṣe láti ṣẹ́gun gbẹ̀rẹ̀bí
Ọpọ obinrin ni ki i ri awọ tutu ti wọn ni tẹlẹ mọ lẹyin ti wọn ba bimọ tan, gbẹrẹbi yoo ti gba ara wọn kan lasiko iloyun, ko si ni i kuro bi wọn ba bimọ tan pẹlu.
Fun awọn eeyan to ba ri bayii fun, Dokita Franck Olivier Yedomon, gba wọn nimọran lati ma ṣe jokoo tẹtẹrẹ.
O ni ki wọn maa fi ipara pa ara wọn daadaa, ki wọn maa lo epo itora, paapaa latigba ti wọn ba ti ṣẹṣẹ loyun naa, ki wọn si maa to ara (massage) daadaa.
O fi kun un pe wọn nilo lati maa jẹ ounjẹ to daa pẹlu.
Bi wọn ba bimọ tan, ki wọn maa jẹun to tọ, lati le kapa itiju ti gbẹrẹbi maa n fa si awọ ara nitori oyun.














