Kúrúnà ara, ṣokoléètì, ààbò lọ́wọ́ òòrùn! Ẹ wo àwọn nnkan tí ẹ le lo òrí fún àti ànfààní rẹ̀

Ori to wa ninu abọ fifẹ, ti ọwọ obinrin kan n pin si kekeeke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bi wọn ṣe n lo ori fun nnkan jijẹ, ni wọn n lo o fun iwosan ara ati iṣaraloge
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ori jẹ ọkan lara awọn eso to wọpo nilẹ Afirika paapaa julọ lẹkun iwọ-oorun rẹ.

Oriṣiriṣi nnkan si ni awọn eeyan maa n lo ori fun lati ọjọ to ti pẹ.

Igi to maa n so ori ti ọpọ mọ si igi ẹmi wọpọ lorilẹede Naijiria papaa julọ ni ipinlẹ Niger, Kwara, Kebbi, Nasarawa ati Kogi.

Awọn obinrin lo pọju ninu awọn to n ṣowo ori ni Naijiria - lẹyin ti wọn ba ka eso rẹ tan lori igi ni wọn maa n pa a.

Lẹyin naa ni wọn a lọ ọ ki wọn to se e lori ina ti yoo si yọ bi ororo ki o to sarajọ to ba ti tutu tan.

Ajọ EU buwọlu lilo ori lọdun 2006 fun ipese ṣokoleeti dipo lilo eso koko, wọn ni o dara ju ṣokoleeti ti wọn n fi koko ṣe lọ.

Wọnyii ni awọn oriṣiriṣi nnkan ti wọn n lo ori fun un:

Wọn maa n lo ori bii ipara lasiko otutu

Wọn maa n lo ori fun ipara ti ko ni jẹ ki otutu mu eeyan, gbogbo nnkan ti o ni lati ṣe ni pe ki o fi ori pa ara rẹ ki o to jade sita.

Bi ori ṣe maa n ki lọwọ ti eeyan ba fi para maa n daabo bo ara lọwọ otutu ti eeyan ba ti jade sita.

Bakan naa, eroja olomi aṣaraloore to wa ninu ori kii jẹ ki ara eeyan o gbẹ.

Wọn maa n lo ori lati mu ara dan

Wọn maa n da ori fun eeyan to ba ni ifo tabi kokoro mii lara.

Ori maa n jẹ ki ara ti ko dan jọlọ, ko si bi ara eeyan ṣe le ri rọku rọku to, ti ẹni naa ba le lo ori daadaa; ara iru ẹni bẹẹ yoo pada jọlọ.

Ti o ba fẹ ki ara rẹ maa dan ko si maa jọlọ, maa fi ori para lẹyin ti o ba ti wẹ tan lojoojumọ.

Laipẹ lai jina gbogbo ibi ti ko dan tẹlẹ ninu ara rẹ ni yoo jọlọ.

Wọn maa n fi ori wọ aya ati iṣan ara

Ori wulo gan an fun wiwọ aya, wọn si tun maa n fi pa ọyan bakan naa paapaa julọ laaarọ ati lalẹ.

Ori tun wulo fun wiwọ iṣan to ba n dun eeyan ninu ara.

Ti o ba fi ori ra ibi iṣan to n dun ọ lera lera, ori maa jẹ ko tu ọ pẹlu epo to maa n sun jade lara rẹ.

Wọn maa n lo ori si atẹlẹsẹ to ba dapaadi

Ẹnikan n da ori to ti yọ lati inu ife sinu ike kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wọn maa n lo ori itọju ifo tabi kokoro mii lara

Njẹ atẹlẹsẹ rẹ kale tabi o n la?

Atẹlẹsẹ rẹ yoo pada jọlọ ti o ba le maa fi ori pa a lojoojumọ.

Ti o ba fẹ tete ri iyatọ, maa fi ori pa atẹlẹsẹ rẹ ki o to lọ sun lalẹ.

Iyẹn nikan kọ, wọ ibọsẹ lẹyin ti o ba ti fi ori ra atẹlẹsẹ tan ki o si sun bẹẹ.

Wọn maa n lo ori fun itọju ete gbigbẹ

Wọn maa n lo ori fun itọju ete gbigbẹ tabi ete to ba n ṣi.

Ete awọn ẹlomiran maa n gbẹ tabi ko maa ṣi lasiko ọyẹ, fifi ori ra ete daadaa maa n ṣẹ oogun eleyii.

Eyi to tun dabi rẹ ni pe ti o ba le maa fi ori ra ete rẹ daadaa lalẹ ki o to sun, ete rẹ ko ni bẹ tabi gbẹ mọ.

Wọn maa n lo ori fun itọju awọn ọmọ ikoko

Ori jẹ ipara ti wọn maa n lo fawọn ọmọ ikoko lojoojumọ eyi to maa n daabo bo ara wọn lọwọ kokoro to si maa n mu ara wọn jọlọ.

Ori dara lara awọn ọmọ ikoko gan an, o maa n jẹ ki awọ ara wọn jọlọ.

Ori kii jẹ ki ara awọn ọmọ ikoko gbẹ pẹlu eroja olomi aṣaraloore to wa ninu rẹ.

O si tun maa n jẹ ki awọ ara awọn ọmọ rẹwa gan an.

Ti o ba ti wẹ fun ọmọ rẹ tan, iwọ fi ori pa gbogbo ara rẹ lati ori de ẹsẹ, ni ṣe ni gbogbo ara ọmọ rẹ yoo maa jọlọ ti yoo si maa dan.

Wọn maa n lo ori fun abo ara lọwọ oorun

Nnkan mii ti wọn maa n lo ori fun ni pe ti eeyan ba fi pa ara, o maa n daabo bo ara lọwọ oorun amuju.

Eroja latex to wa ninu ori lo maa n daabo bo ara eeyan ti oorun ba mu ju.

Fitami E. to wa ninu ori to maa n pese eroja hydrolipidic kii jẹ ki oorun ni ipa ti ko dara lara ẹni to ba fi ori para.

Awọn anfaani to wa ninu ori ree

Ori kọlọbọ pẹlu eso ẹmi ti wọn n fi ṣe e ninu ewe

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eroja latex to wa ninu ori lo maa n daabo bo ara eeyan ti oorun ba pọju.

Ori dara fun awọ ara gbogbo eeyan

Iwadii ti fidi rẹ mulẹ wi pe ko fẹẹ ma si ẹni ti ko le lo ori lati fi pa ara lai ni ṣakoba fun ara rara.

Ori jẹ nnkan ti a n ri lara igi, tori naa kii saba ni eroja to le ṣiṣẹ lodi si ara ẹnikẹni.

Gbogbo eeyan lo le lo si ara wọn lai sewu kankan nibẹ.

Ori maa n mu awọ ara eeyan jade daadaa, kii si bo ara eeyan.

Ori lomi aṣaraloore ninu

Lara nnkan ti ọpọ eeyan fi maa n lo ori eroja olomi aṣaraloore to wa ninu rẹ.

Awọn onimọ nipa eto ilera sọ pe lara awọn eroja aṣaraloore naa ni fatty acid, linoleic, oleic, stearic, ati palmitic acids.

Awọn eroja yii ni wọn maa n wọ inu ara lọ ti eeyan ba ti fi ori pa ara.

Awọn eroja yii bakan naa si lo maa n jẹ ki awọ ara eeyan jọlọ.

Ori kii jẹ ki awọ ara maa rin

Awọn onimọ ijinlẹ lori eto ilera sọ pe ori ni eroja linoleic acid ati oleic acid to pọ gan an.

Eyi tumọ si pe awọn acid mejeeji yii maa n ṣiṣẹ papọ to fi jẹ pe ori ko ni maa rin lara ẹni to ba lo o.

Lara iṣẹ ti ori n ṣe ni pe o maa n mu ara jọlọ, o si maa n mu ara dan.

Ori maa n jẹ ki ara to wu lọọlẹ

Iwadii lori ori ti fi han pe o wulo fun ki eeyan maa lo o fun ibi to ba wu lara eeyan.

Awọn onimọ nipa eto ilera sọ pe ti eeyan ba fi ori ra ibikan to ba wu, o maa n jẹ ki cytokines atawọn sẹẹli to wa nibi to wu naa lọ silẹ.

O si tun maa n mu adinku ba ki ibi to wu lara maa dun eeyan.

Ori kii jẹ ki nnkan tete bajẹ

Ori ni eroja fitami A ati fitamin E ninu eyi ti kii jẹ nnkan tete bajẹ.

Awọn eroja to wa ninu ori yii ṣe pataki tori wọn maa n daabo bawọn sẹẹli awọ ara.

Eyi ko si ni jẹ ki ẹnikẹni to ba n lo ori tete dabi arugbo tabi ki oju eeyan ma dun un wo.

Ori maa n gbogun ti kokoro ninu ara

Iwadii kan tawọn onimọ ijinlẹ nipa eto ilera ṣe lọdun 2022 fidi rẹ mulẹ pe ori ni awọn eroja to maa n gbogun ti kokoro ninu ara.

Bo tilẹ jẹ pe iwadii si tun n lọ lori eyi, lilo ori maa n dena kokoro bakitiria ninu ara.

Ori maa n jẹ ki eroja aṣaraloore collagen pọ ninu ara

Lara anfaani to wa ninu ori ni ipese eroja aṣaraloore collagen ninu ara eeyan.

Eyi tun maa n dabbo bo eroja fibre ninu ara.

Eroja yii bakan naa ni kii jẹ ki eeyan ni ila lara.

Ori maa n ṣe isọdọtun awọn sẹẹli

Awọn eroja olomi ati eyi to maa n daabo bo awọ ara ninu ori maa n ṣiṣẹ pọ sọ awọn sẹẹli to wa ninu awọ ara dọtun.

Pẹlu lilo ori, awọn sẹẹli tuntun maa n ṣuyọ ninu awọ ara lati rọpo awọn to n ku lọ.

Eroja aṣaraloore olomi to wa ninu ori ko ni jẹ ki eeyan to ba n lo ni sẹẹli to ku lọ dabi alara.

Ori maa n mu adinku ba apa ati ila to maa n wa lara eeyan

Lara awọn iwulo ori ni pe o maa n mu ki apa to wa lara eeyan parẹ diẹ diẹ.

Eyi maa n waye tori ori maa n ṣe isọdọtun awọn sẹẹli inu awọ ara.

Ori le ma jẹ oogun fun ila to maa n wa lara eeyan amọ, o maa n ṣeranwọ lati jẹ ki apa to wa lara parẹ.

Ori kii jẹ ki irun ori eeyan ja

Iwadii ti fi han wi pe ori maa n jẹ ki irun ori eeyan duro nilẹ daadaa.

Iwadii ọhun ti wọn ṣe lọdun 2017 tun ṣalaye pe awọn eroja to wa ninu ori kii jẹ ki irun ja.

Bakan naa tun ni ori maa n gbogun ti ẹṣi to maa n wa ni isalẹ irun.