Oúnjẹ ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú, ariwo gèè! Ẹ wo ọgbọ́n tí àwọ̀n òbí yìí n dá lásìkò ìsìnmi ọlọ́jọ́ gbọọrọ

Àkọlé fídíò,
Oúnjẹ ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú, ariwo gèè! Ẹ wo ọgbọ́n tí àwọ̀n òbí yìí n dá lásìkò ìsìnmi ọlọ́jọ́ gbọọrọ

Asiko isinmi ọlọjọ gbọọrọ nile ẹkọ ni awọn ọmọde wa bayii lorilẹede Naijiria, ati ni awọn orilẹede kan l'agbaye.

Bo tilẹ jẹ pe asiko isinmi ni fun awọn akẹkọọ to wa ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, o tun ma n jẹ asiko ti awọn obi kan kii fi bẹẹ 'gbadun'.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọmọde ṣe ma n ṣe ereepa, jẹ ounjẹ laimọye igba, da ile ru, ija, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Asiko yii ni ọpọ obi ma n mọ iyi iṣẹ ti awọn olukọ n ṣe lasiko ti awọn ọmọ ọhun ba wa ni ile ẹkọ.

Bi isinmi ọlọjọ gbọọrọ ọhun ṣe wa n lọ lọwọ, BBC ba awọn obi kan sọrọ lati mọ ọgbọn ti wọn n da a si lasiko yii.

Awọn ọmọde to wọ aṣọ ile-ẹkọ wọn, to si n sare pẹlu idunnu ninu ọgba ile-ẹkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn obi naa to fẹnuko pe lasiko isinmi yii, awọn ọmọ wọn n jẹun ju ti tẹlẹ lọ, ti wọn si n fẹ ki obi wọn ko ṣe ọpọ nnkan fun wọn.

Yatọ si eyi, wọn tun gba awọn obi bii ti wọn ni iyanju lati jẹ ki awọn ọmọ wọn wa iṣẹ ọwọ lati kọ tabi awọn iṣẹ ọpọlọ miran, lai pa isinmi wọn lara.