Ọmọdé méjì kú lásìkò tí ọ̀dọ́kùnrin kan yìnbọn nílé ẹ̀kọ́ Ìjọ Kátólìíkì

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ko din ni ọmọde meji to ku, ti eeyan mẹtadinlogun mii si farapa lẹyin ti ọdọmọkunrin kan wọ inu ile-ẹkọ Katoliiki kan, Annunciation School, to si ṣina ibọn fun wọn.
Nibi iṣẹlẹ ọhun to waye ni Ọjọru niluu Minneapolis lorilẹede Amẹrika, ni ọmọ ọdun mẹwaa ati ọdun mẹjọ ọhun ti ku, gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ṣalaye.
Ileesẹ ọlọpaa sọ pe lasiko ti isin owurọ n lọ lọwọ ninu ṣọọṣi ile ẹkọ naa ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe, ibọn mẹta ọtọọtọ ni ọdọkunrin naa ko dani to si bẹrẹ si ni yinbọn sinu ṣọọṣi lati oju ferese.
Awọn ọlọpaa ṣalaye pe ibọn to yin mọ ara rẹ lo jẹ ki oun naa jẹ gbẹmi mi.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ fawọn akọroyin pe lati agbegbe ti kii ṣe aarin igboro Minneapolis ni ọkunrin naa ti wa ṣiṣẹ laabi rẹ.
Ọga ọlọpaa Brian O'Hara ni ọdọkunrin naa mọ n mọ huwa ipa sawọn ọmọde atawọn olujọsin ni.
Ọmọde mẹrinla lo wa ninu awọn to farapa nibi iṣẹlẹ naa, meji ninu wọn si wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii.
Ẹwẹ, adari ijọba ilu Muinneapolis, Jacob Frey, fi itara sọrọ pe ọrọ adura kọ lọrọ to wa nilẹ yii nitori awọn ọmọde to pa yii gan an n gbadura lọwọ ni ki ẹnikan to wa yinbọn pa wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Trump ni ki wọn fa asia Amẹrika walẹ ni iranti awọn ọmọ to ku
Aarẹ Donald Trump ti paṣẹ pe ki wọn fa asia Amẹrika walẹ kaakiri orilẹede naa lati bu ọla fun awọn ọmọ to d'oloogbe ati awọn to farapa nibi iṣẹlẹ Minneapolis.
Bakan naa ni aarẹ Amẹrika paṣẹ pe ki wọn fa asia orilẹede naa walẹ nibi gbogbo ti olu ileeṣẹ Amẹrika ba wa, awọn ibudo ologun ati ninu awọn ọkọ oju omi Amẹrika.
Amẹrika gbọdọ pa aṣẹ yii mọ titi di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹjọ yii, gẹgẹ bi Trump ṣe sọ.
Ọmọde meje lo n gba itọju nile iwọsan
Ọmọde meje ni a gbọ pe wọn kọkọ gbe lọ si ile iwosan awọn ọmọde to wa ni Minneapolis.
Ọkan ninu wọn ti pada sile, awọn mẹfa lo ku bayii ti wọn si n gba itọju nile iwosan naa.
Bakan naa ni Ọgbẹni Thomas Wyatt to jẹ alaga ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nile iwosan Hennrpin Healthcare sọ pe eeyan meje ni wọn gbe wa sile iwosan naa.
Wyatt ni mẹrin ninu awọn eeyan ọhun ni wọn nilo iṣẹ abẹ ni kiakia.
Iṣẹlẹ ibọn yinyin nigbangba ti waye ni igba 286 l'Amẹrika lọdun 2025 yii
Akọsilẹ fi han pe iṣẹlẹ ibọn yinyin ni gbangba ti waye ni igba 286 l'Amẹrika lọdun 2025 yii.
Iṣẹlẹ ibọn yinyin nigbangba ni ibi kibi ti iṣẹlẹ ibọn yinyin ba ti waye ti ọta ibọn ba ti ba eeyan bii mẹrin tabi ju bẹẹ lọ, lai si ẹni to yinbọn nibẹ.
Akọsilẹ tun fi han pe iṣẹlẹ ibọn yinyin ni gbangba to lọ soke lasiko ajakalẹ arun Covid-19 ti n lọ silẹ bayii .















