Oríadé, Apetu ti ìlú Ipetumodu, dèèrò ẹ̀wọ̀n l'America fún lílu jìbìtì owó Covid-19

Oríṣun àwòrán, @BritoCurrency
Ile ẹjọ kan nilẹ Amẹrika ti sọ Apetu ti ilu Ipetumodu nipinlẹ Osun, Ọba Joseph Oloyede, si ẹwọn ọdun mẹrin lori ẹsun lilu jibiti owo iranwọ Covid-19 ti iye rẹ le ni miliọnu mẹrin dọla.
Ọmọ Naijiria ati ilẹ Amẹrika ni Oloyede, to jẹ ẹni ọdun mejilelọgọta, to si n gbe niluu Medina, to wa ni Ohio orilẹede Amerika, ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade kan lati ile ẹjọ ariwa Ohio, wọn ti ni ki ọdaran naa da owo ti iye rẹ jẹ $4,408,543.38 pada fun ijọba Amẹrika.
Ijọba Amerika yoo tun gbẹsẹ le "ile ọdaran ọhun to wa ni Medina, loju ọna Foote, eyiito fi owo jibiti naa ra, to fi mọ owo mii ti iye rẹ jẹ $96,006.89."
Agbẹjọro ijọba Amẹrika ni, Oloyede lu ijoba ni jibiti, o si gba owo to ya sọtọ fun awọn oniṣowo kekeeke lati fi kun owo wọn latari ipalara ti arun Covid-19 ṣe fun wọn.
Iwe ile ẹjọ naa sọ pe "lati nnkan bii oṣu Kẹrin ọdun 2020 si oṣu Keji ọdun 2022 ni Oloyede ati ẹnikeji rẹ, Edward Oluwasanmi gbimọpọ lati gba ẹyawo ti ijọba gbe kalẹ labẹ ajọ awọn oniṣowo kekeeke, eyii ti wọn ṣe labẹ ofin Coronavirus Aid, Relief, and Economic Security (CARES) Act."
Ninu oṣu Kẹrin ọdun yii ni awọn mejeeji sọ pe awọn jẹbi ẹsun jibiti naa, ti wọn si gba owo ti iye rẹ jẹ $4.2m lọwọ ijọba ọna eburu.
Iroyin ni, Oloyede, to n ṣiṣẹ gẹgẹ bii ẹni to n ṣeto owo ori ni ileeṣẹ marun un ọtọtọ ati ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, nigba ti ẹnikeji rẹ, Oluwasanmi ni okoowo mẹta.
"Awọn mejeji lo ileeṣẹ wọn lati gba owo lọwọ ijọba amọ iroyin ti kii ṣe ootọ ni wọn fi silẹ lasiko iforukọsilẹ wọn.
"Wọn gba owo to to $1.2m lori awọn ileeṣẹ Oluwasanmi nigba ti wọn gba owo ti iye rẹ to $1.7m lori awọn ileeṣẹ to jẹ ti Oloyede" gẹgẹ bi awọn iwe ile ẹjọ naa ṣe wi.
Gẹgẹ bii awọn ọrọ ti awọn oluwadii sọ, Oloyede ko fi owo to gba lọwọ ijọba ṣowo kankan, niṣe lo ko owo ọhun si apo ara rẹ.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa ọba to lu jibiti naa ree
Oba Joseph Olugbenga Oloyede ni Apetumodu kẹtadinlọgbọn ilu Ipetumodu nipinlẹ Osun.
Ọdun 2019 lo gori aleefa lẹyin ti Ọba James Adedokun Adegoke waja ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2017.
O kẹkọọ alakọbẹrẹ nile ẹkọ Christ Church II ati C & S Modern Commercial Secondary School niluu Ipetumodu.
Itan sọ pe o kẹkọgboye ninu imọ iṣiro nile ẹkọ gbogboniṣe ilu Ibadan ko to lọ si fasiti ijọba ipinlẹ Enugu lati kẹkọọ siwaju si.
Lẹyin naa lo lọ silẹ Amẹrika lati kẹkọọ ni fasiti Sarasota, ni Florida nibi to ti gba oye MBA.
O tun gba oye ọmọwe, Doctor of Business Administration (DBA) ni Argosy University, Sarasota.
Lara awọn ibi to ti ṣiṣẹ ni ile ifowopamọ First Bank of Nigeria ati John Holt Financial Merchant Bank ko to pada silẹ Amẹrika.
Ọmọ oye Aribile ni lati idile Latimogun ko to gori itẹ ilu Ipetumodu.















