Ẹ wo Ọba Olajide Okunato, tó ń fi owó ara rẹ̀ ṣe ojú ọ̀nà, ìná, kọ́ àgọ́ ọlọ́pàá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ fún ìlú
Yoruba bọ, wọn ni, oniluu ko nii fẹ ko tu. Bẹẹ gan an ni ọrọ ri fun Ọba Olajide Okunato, Irẹsi ilu Osi, nipinlẹ Ondo.
Nibi ti ọpọlọpọ ilu ati olori wọn ti ma n duro de awọn olori ijọba oloṣelu lati ba wọn tun ilu wọn ṣe, ti iduro wọn kii si saba so eso rere, ọna ọtọ ni Ọba Okunato gbe ọrọ ilu Osi gba.
Niṣe ni ori ade naa ma n fi owo ara a rẹ tun ilu ṣe, lai duro de ijọba.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC News Yoruba, Ọba Olajide Okunato sọ pe nigba ti oun kọkọ jẹ ọba ilu naa, bi abule lasan ni nitori pe ko si ina ẹlẹtiriiki, oju ọna to dara, koda, ko si agọ ọlọpaa.
"Bii pe ki ilu Osi ti dabi London lo ṣe ma n ri loju mi, lati igba ti mo ti jẹ ọba."

Oríṣun àwòrán, Oba Olajide Okunato
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Ọba Okunato sọ pe ko si iye owo ti oun ba ni, ti oun ko le na fun idagbasoke ilu Osi.
"Bi igba ti eniyan wa sinu aginju ni ilu ri, ṣugbọn iran aginju kọ ni Ọlọrun fi han mi ki n to o jẹ ọba, iran ilu nla ni.
"O le ni ọgọrun adugbo ti mo ṣe sinu ilu, ti mo si na owo ti ko din ni ẹgbẹrin un lọna igba naira lojoojumọ lori oju ọna ṣiṣe."
Lẹyin to ṣe oju ọna lo tun ra ẹrọ amunawa, opo ina, kọ ile ẹjọ majisireeti, agọ ọlọpaa, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Gbogbo eyi ni Okunato ṣe ṣaaju ko to o jẹ ọba, to si tun n tẹsiwaju lẹyin to jọba.
Bawo ni ọba naa ṣe n ri owo tun ilu ṣe?
Kabiesi Okunato sọ pe awọn owo ti oun n pa lati ileeṣẹ to da silẹ lo n lo, pẹlu afikun eyi ti wọn ba ri ninu ilu.
O ni kii ṣe pe oun n ṣe gbogbo nnkan naa lati fi gba ere tabi idupẹ lọwọ ẹnikẹni.
Diẹ lara awọn araalu Osi to ba BBC sọrọ, jẹrii si i pe lootọ ni ilu naa jẹ abule oko ti ẹnikan ko mọ ṣaaju iyansipo Ọba Olajide Okunato.



