''Kò sí físà pàtàkì fáwọn tó bá fẹ́ lọ Kisarazu, ìlú tí ìjọba Japan yọ̀nda f'ọ́mọ Naijiria láti máa gbé''

Asiko ti arabinrin Florence Akinyemi Adeseke, to jẹ aṣoju Naijiria si Japan, ati Yoshikuni Watanabe, to jẹ alakoso ilu Kisarazu, ti gba iwe aṣẹ lọwọ ijọba Japan pe ilu Kisarazu naa lawọn ọmọ Naijiria yoo maa gbe nibẹ.

Oríṣun àwòrán, @FMINONigeria/

Àkọlé àwòrán, Lọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ yii ni iroyin kan jade pe ijọba orilẹede Japan ti kede iyasọtọ ilu Kisarazu fun awọn ọmọ Naijiria to fẹ maa gbe lorilẹede naa lati ṣiṣẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ijọba orilẹede Japan ti ṣalaye pe oun ko ni fawọn ọmọ Naijiria atawọn ọmọ ilẹ Afirika mii ni fisa pataki lati lọ si ilu Kisarazu lati maa gbe.

Lọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ yii ni iroyin kan jade pe ijọba orilẹede Japan ti kede iyasọtọ ilu Kisarazu fun awọn ọmọ Naijiria akọṣẹmọṣẹ to fẹ maa gbe lorilẹede naa lati ṣiṣẹ.

Amọ, ileeṣẹ ijọba Japan to n ri si ọrọ ilẹ okeere ti ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aje wi pe yiya ilu Kisarazu sọtọ fawọn ọmọ Naijiria lati maa ṣiṣẹ ati lati maa gbe ko tumọ si pe ijọba Japan yoo maa fawọn ọmọ Naijiria ni fisa pataki lọ si orilẹede naa.

Ileeṣẹ ijọba Japan to n ri si ọrọ ilẹ okeere ṣalaye wi pe ijọba ṣe ifilọlẹ eto naa nibi ipade apero 9th Tokyo International Conference for African Development to waye laipẹ yii lati jẹ ki ibaṣepọ to wa laarin awọn orilẹede Afirika ati awọn ibilẹ ni Japan le fidi mulẹ sii.

Ileeṣẹ ijọba Japan to n ri si ọrọ ilẹ okeere ṣalaye pe ''labẹ eto yii, ilu mẹrin ni Japan ni ijọba ti ya sọtọ lati di ile fun awọn eeyan lati orilẹede Afirika mẹrin.

Ijọba n gbero lati ri pe ibaṣepọ to dan mọran wa laarin ilu mẹrin yii atawọn orilẹede Afirika mẹrin ọhun nipa oniruuru eto JICA ti a ṣe ifilọlẹ rẹ.

Ṣugbọn ko si nnkan to jọ wi pe ijọba yoo maa fawọn ọmọ orilẹede mẹrẹẹrin yii ni fisa pataki lati wa si Japan.

Iroyin ofege ni iroyin to ba sọ pe ijọba Japan yoo maa fawọn to ba fẹ lọ sawọn ilu mẹrin naa ni fisa pataki.

Ṣaaju ninu iroyin to jade tẹlẹ ni ijọba Naijiria ti sọ pe ijọba Japan yoo pese eto fisa tuntun fun awọn ọmọ Naijiria to jẹ akọṣẹmọṣẹ lati lọ maa ṣiṣẹ ati lati maa gbe ni Kisarazu.

Iroyin to jade tẹlẹ tun ṣafihan adele aṣoju ijọba Naijiria ni Japan, Florence Akinyemi Adeseke pẹlu Yoshikuni Watanabe, nibi to ti gba iwẹ ẹri fun orukọ ilu ti ijọba Japan ya sọtọ fawọn ọmọ Naijiria.

Mọ̀ nípa Kisarazu, ìlú tí Ìjọba Japan yọ̀nda fún àwọn ọmọ Naijiria láti máa gbé

Ọkunrin kan to jẹ alawọ dudu ati obinrin jan to jẹ ọmọ orilẹede Japan jọ n rin lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ lọ sibẹ le ko mọlẹbi wọn lọ ki wọn si maa janfani eto ilera nibẹ bii ọmọ oniluu.

Ijọba orilẹede Japan ti kede iyasọtọ ilu Kisarazu fun awọn ọmọ Naijiria to fẹ maa gbe lorilẹede naa lati ṣiṣẹ.

Ileeṣẹ ijọba Naijiria to kede ọrọ naa oju po X rẹ sọ pe igbesẹ ọhun wa fun irẹpọ larin orilẹede mejeji.

Gẹgẹ bii ohun ti ijọba Naijiria sọ, ibi ipade apero 9th Tokyo International Conference for African Development to waye laipẹ yii ni wọn ti fẹnuko lori ọrọ naa.

Wọn ni ijọba Japan yoo pese eto fisa tuntun fun awọn ọmọ Naijiria to kọṣẹmọṣẹ lati lọ maa ṣiṣẹ ati lati maa gbe ni Kisarazu.

Ninu nnkan bii ọgọrun ati mẹtalelogun miliọnu eeyan to n gbe ni Japan, ẹgbẹrun lọna ọgọrun ati mẹrindinlogoji ninu wọn lo n gbe ni Kisarazu latari pe pupọ eeyan to wa nibẹ lo jẹ arugbo.

Wọn ni ẹnikẹni to ba fẹ jẹ anfaani naa gbọdọ kọkọ kọ nipa aṣa ati ede awọn eeyan Japan nitori kii ṣe ọpọ wọn lo gbọ ede Gẹẹsi.

Labẹ eto ọhun, ijọba Japan yoo pese ile ti ọwọ rẹ ko pọ ju fun awọn ọmọ Naijiria, wọn si le ṣowo tabi ṣiṣẹ nibẹ lai si wahala kankan.

Awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ lọ sibẹ le ko mọlẹbi wọn lọ ki wọn si maa janfani eto ilera nibẹ bii ọmọ oniluu.

Fun aṣeyọri eto naa, ijọa Japan yo ṣe atilẹyin fun awọn to ba ni ọmọ, paapaa awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ ọmọ Japan.

Awọn wo ni yoo janfaani eto fisa yii?

Gẹgẹ bii alakalẹ eto ọhun, awọn to ba ni iṣẹ ọwọ ti wọn si ṣetan lati mọ si ninu iṣẹ wọn ni yoo jẹ anfani to pọ julọ.

Nipa eto naa, ijọba Japan n fẹ ki ajọṣepọ to dan mọran wa laarin rẹ ati orilẹede mẹrin ni Afrika.

Arabinrin Florence Akinyemi Adeseke, to jẹ aṣoju Naijiria si Japan, ati Yoshikuni Watanabe, to jẹ alakoso ilu Kisarazu, ti gba iwe aṣẹ lọwọ ijọba Japan pe ilu Kisarazu naa lawọn ọmọ Naijiria yoo maa gbe nibẹ.

Wọn ni igbagbọ wa pe eto ọhun yoo mu idagbasoke ọtun ba ilu Kisarazu atawọn ilu mii layika rẹ.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa ilu Kisarazu

Eeyan 136,000 pere lo n gbe niluu Kisarazu to jẹ aadọrin kilomita siluu Tokyo to jẹ olu ilu Japan.

Ilu naa gbajumọ fun iṣẹ ẹja pipa ati iṣẹ agbẹ, o si jẹ agbggbe ti ko ni wahala pupọ.

Ilu ọhun ni ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria n gbe ti wọn si ti n gbaradi lasiko idije Olympics ọdun 2020.

Awọn eeyan ilu naa fẹran ariya bii awọn ọmọ Naijiia, awọn kan ninu si gbọ ede Gẹẹsi latari pe wọn maa n kọ ede naa lawọn ile ẹkọ wọn.