EFCC ní kàwọn ọmọ Naijiria tó pàdánù owó sínú òkòwò CBEX yọjú sí ọ́ọ́fíìsì rẹ̀ l'Eko àti n'Ibadan

Aworan awọn eeyan ni ọọfiisi CBEX

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Ọpọ eeyan ya bo ọọfiisi CBEX lati lọ beere owo ti wọn fi dokowo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ti ranṣẹ pe awọn ọmọ Naijiria ti wọn padanu ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu owo sinu okowo CBEX lati yọju si ọọfiisi ajọ naa to wa niluu Ibadan ati Eko.

Ajọ EFCC ransẹ pe awọn eeyan ọhun lati ṣe iranwọ fun iṣẹ iwadii ti ajọ naa n ṣe lọwọ lori bi owo ti wọn fi dokowo ṣe wọgbo.

Agbẹnusọ ajọ EFCC, Dele Oyewale, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita lopin ọsẹ yii.

Ninu atẹjade naa ni Oyewale ti sọ pe ''ajọ EFCC n ṣe ẹjọ afurasi mẹta, Adefowora Olanipekun, Otorudo Avwerosuo ati Ehirim Chukwuebuka, lọwọ lori ẹsun wi pe wọn kopa ninu okowo CBEX ti ọpọ ọmọ Naijiria padanu owo gọbọi sinu rẹ.

Gẹgẹ bi EFCC ti ṣalaye, awọn eeyan to ṣagbatẹru CBEX, tan ọpọ ọmọ Naijiria lati dokowo pẹlu idaniloju pe wọn yoo ri ere gọbọi.

EFCC ni lẹyin ti wọn dokowo tan pẹlu ọpọlọmọ miliọnu ni owo wọn wọgbo ti wọn ko si ri nnkankan mọ, ati ere ati oju owo.

Idi niyi ti EFCC fi n kepe awọn eeyan tawọn to ṣabatẹru CBEX rọ lati kowo le CBEX lori niluu Eko ati Ibadan, ki wọn le ran EFCC lọwọ pẹlu iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ.

Kí ló ń jẹ́ CBEX, okoòwò ayélujára tó kò àwọn ọmọ Naijiria sínú gbèsè apanilẹ́kún?

Aworan awọn eeyan to dokowo pẹlu CBEX

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Awọn onibaara CBEX kawọ lori ni ọọfiisi ileeṣẹ naa

Ṣaaju ninu oṣu Kẹrin ọdun 2025 ni ọpọ eeyan pariwo nipa okoowo sogun di ogoji kan ti wọn se lori ayelujara, ti wọn n pe ni CBEX.

Ọrọ bẹyin yọ nigba ti oju opo ayelujara ileeṣẹ naa ko ṣiṣẹ mọ, ti wọn si ko owo gbogbo awọn onibaara wọn lọ.

Bi owo naa se n sọ ogun di ogoji ni ko ye ọpọlọpọ eeyan sugbọn ọrọ nipa CBEX bayii ti gba omije loju ọpọ eeyan.

Ki ni wọn n pe ni CBEX gangan?

Gẹgẹ ohun ti o a ri ka, Ileeṣẹ CBEX ni wọn da silẹ tí ni ọdun 2022, eyiun ọdun mẹta sẹyin.

Cripto Currency ni wọn ni awọn n ṣe, ti wọn sọ owo awọn eeyan di ilọpo meji.

Ṣugbọn ni ọsẹ to kọja, CBEX ko jẹ ki awọn eeyan gba owo wọn sita ,ti ariwo si sọ.

Kete ti ileeṣẹ CBEX ko owo awọn eeyan ni awọn ọdọ kan yawọ ọfisi wọn niluu Ibadan, ti wọn si bẹrẹ si ni ko gbogbo ẹru wọn lọ.

Fọnran kan to lu sita lori ayelujara safihan bi awọn ọdọ kan ṣe binu yawọ ọfisi naa to wa niluu Ibadan, ti wọn si n da gbogbo nnkan ru, koda wọn ji ọpọlọpọ awọn nnkan ini wọn lọ.

Bakan naa ni ana ode yii ni Ileeṣẹ CBEX ko gba wọle, ti wọn si tun sọ fun onibara pe ẹni to ba ni apapọ owo to din ni ẹgbẹrun kan Dọla, san owo ọgọrun un Dọla, ti awọn to ni apapọ owo to le ni ẹgbẹrun kan Dọla, lọ san owo to jẹ igba Dọla.

Eyi lo bi ọpọlọpọ ninu sugbọn CBEX ni wọn ko ni anfani si owo wọn, ti wọn ko ba san owo tuntun ti wọn ni ki wọn san.