"Àwọn Fijilanté tó já mi sí ìhòòhò, halẹ̀ mọ́ mi pé àwọn yóò yìnbọn pa mi, ju òkú mi sínú igbó"

Aworan mẹta ti a ko papọ nipa bi awọn fijilante se n ti obinrin kan nto wọ asọ funfun, awọn figilante naa si gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Obinrin agunbanirọ ti awọn fijilante kan ṣe ikọlu si, ya aṣọ mọ lara nipinlẹ Anambra ti jade sọrọ lori ohun to la kọja lasiko naa.

Ṣaaju ni fọ́nrán àwòrán kan tí lu sita lori ayelujara, eyi to ṣafihan bi awọn fijilante Agunechemba nipinlẹ Anambra, ṣe ja agunbanirọ obinrin kan si ihooho, ti wọn si wọ sita lẹyin ti wọn ko ọpọ igbaju fun un.

Iṣẹlẹ yii waye ni agbegbe Oba, nijọba ibilẹ Guusu Idemili nipinlẹ Anambra, to si ti fa ọpọ ariyanjiyan lori ayelujara.

Gẹgẹ bii agunbanirọ naa ṣe sọ, iṣẹlẹ yii waye ni Ọjọ kẹtalelogun oṣu keje ọdun 2025 ni dede ago marun un ni ile awọn agunbanirọ ni Anambra.

"Wọn le wa kuro ninu ile wa, wọn wo ẹrọ foonu wa ati kọmputa agbeletan wa"

Agunbanirọ náà ṣalaye pe awọn ọkunrin yii wa si ile naa, wọn bẹrẹ si ni ma fi ipa ja ilẹkun ṣugbọn oun si ilẹkun lati wo eeyan to n gba ilẹkun, ti wọn si gbe ibọn jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọn bẹrẹ si ni pariwo ṣugbọn wọn ko wọ aṣọ iṣẹ wọn.

Ọdọmọbinrin naa sọ eyi ninu fọnran kan to ṣe lati fi ṣalaye ohun to waye.

O ni oun wa ninu ile awọn agunbanirọ pẹlu awọn Agunbanirọ akẹgbẹ òun nínú ile alaja mẹta naa.

Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, " Mo ri awọn ọkunrin kan to fi nnkan boju pẹlu ibọn.

Wọn ko wọ aṣọ iṣẹ, ko si nnkan ti a le fi da wọn mọ.

Lakọkọ, ole ni mo pe wọn, ti ẹru si n ba wa ṣugbọn wọn ni ki gbogbo wa bọ sita".

O ni oun beere lọwọ awọn eeyan yii pe ki lo de ti wọn fi ni ki awọn bọ síta?

"Gbogbo awa ti a wa ninu ile naa jẹ agunbanirọ.

Wọn ko sọ fun wa iru eeyan to jẹ.

Awọn akẹgbẹ mi yọ káàdì idanimọ wọn sita, ti awọn yoku naa si yọ ti wọn ṣugbọn wọn ko da wa lohun.

"Wọn le wa kuro ninu ile wa, wọn wo ẹrọ foonu wa ati kọmputa agbeletan wa.

Wọn bẹrẹ si maa le eegun mọ wa, ti wọn si fẹsun kan wa pe iṣẹ yahoo yahoo ni a n ṣe."

"Wọn lù mí pé kí ló dé tí mò ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn, wọn ní oninabi obinrin ni mí"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agunbanirọ naa ni awọn gbiyanju lati ṣalaye pe awọn ko ṣe yahoo, ti awọn si wa sin ilu awọn ni.

O ni awọn mẹsan an ti awọn jẹ agunbanirọ ni awọn fijilante ko lọ lọjọ naa.

O ni awọn fijilante yii tu gbogbo ile ṣugbọn wọn ko ri nnkankan.

"Wọn ti wa lọ si isalẹ.

Wọn beere pe ki ni idi ti mo fi koju wọn gẹgẹ bii obinrin.

Nigba ti a de isalẹ ni a ri awọn oṣiṣẹ fijilante Anambra.

"A ni ti a ba ma tẹle wọn lọ si ọfisi wọn, a ni lati pe Ọga wa lati sọ fun pe ibi bayii ni a wa nigba ti a ko mọ ibi ti a n lọ,"

Obìnrin náà ni awọn ọkunrin fijilante yii kọ jalẹ, ti wọn ko si fun awọn ni anfani lati pe ẹnikẹni.

O ni wọn bẹrẹ si maa lu oun nitori oun n beere ibeere.

"Wọn bẹrẹ si ni ma lu mi pe ki ni idi ti mo fi n beere ibeere lọwọ awọn.

Wọn ni awọn yoo fọ foonu wa mọlẹ ti a ba pe ẹnikẹni.

Wọn lu mi, ya aṣọ mi.

Ọkan ninu awọn akẹgbẹ mi to n ba mi bẹbẹ, wọn gba ni irin."

O tẹsiwaju pe wọn pe oun ni oninabi obinrin, ti wọn si dunkoko pe awọn yoo yin oun ni ibọn, ju oku oun sinu igbo.

"Wọn gba eti mi, pe mi ni oni naabi obìnrin.

Wọn ni awọn yoo yinbọn fun mi, ju oku mi sinu igbo."

Ki ni ijọba ipinlẹ Anambra sọ?

Isẹlẹ naa ti de ọdọ ijọba ipinlẹ Anambra, wọn si ti gba iṣẹ lọwọ awọn Fijilante to lu Agunbanirọ naa.

Yatọ si pe ijọba gba iṣẹ lọwọ awọn fijilante naa, wọn tun fa wọn le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ fun iwadii pẹlu.

Ṣugbọn ijọba Anambra ti ni iṣẹlẹ naa ko ni i lọ bẹẹ, wọn ni awọn yoo tuṣu de isalẹ ikoko lori ohun gbogbo to ṣẹlẹ.

Oludamọran pataki fun Gomina ipinlẹ Anambra, Chukwuma Soludo, iyẹn Ken Emeakayi, lori aabo agbegbe, lo kede bẹẹ l'Ọjọruu, lori ileeṣẹ redio ipinlẹ Anambra.

Bakan naa ni awọn ajọ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan kaakiri orilẹede yii ti dide pẹlu, lati ri i pe ọmọbinrin ti wọn fiya jẹ ko jiya gbe.

Ki ni ileeṣẹ NYSC sọ?

Bakan naa ni ajọ Agunbanirọ lorilẹede yii naa ti bu ẹnu atẹ lu iwa awọn fijilante naa.

"Ajọ NYSC ka iwa yii si eyi to lodi si ọmọniyan, a ko si faramọ iru rẹ rara."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ti Caroline Embu, Adele Agbẹnusọ fun ajọ naa fi sita sọ.

O ni awọn nigbagbọ pe awọn ọlọpaa yoo wadi iṣẹlẹ naa finni-finni, abọ iwadii wọn yoo si jẹ ki Agunbanirọ ti wọn fiya jẹ, gba idajọ ododo, pẹlu awọn to ba tun kan.

Lori idi ti awọn fijilante naa fi yabo ọgba Agunbanirọ, iroyin sọ pe wọn ni awọn gbọ pe jibiti ori ayelujara ni awọn ọdọ naa n lu ninu ile ọhun.

Eyi ni wọn tori rẹ fi iya jẹ obinrin to n sinru ilu naa.

Aworan to ṣafihan awọn fijilante mẹjọ naa, wọn kọyin sita, kọju si olu ileeṣẹ wọn nipinlẹ Anambra.

Oríṣun àwòrán, Anambra Broadcasting Service

Àkọlé àwòrán, Awọn fijilante mẹjọ naa ree

Bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe waye rèé

Fidio kan to ti gbalẹ kaakiri lo ṣafihan bi awọn ikọ fijilante Agunechemba to n gbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Anambra, ti wọn dihamọra ogun pẹlu ibọn, ti ja wọ ọgba awọn agunbanirọ.

Ninu fidio naa la ti ri ọmọge kan to jẹ Agunbanirọ, ti wọn n ti siwaju, sẹyin, titi wọn fi ya asọ lara rẹ, ja si ihooho, ti wọn si lu ni alubajẹ.

Iroyin ni inu ile ti wọn pese fawọn agunbanirọ ni obinrin naa wa, ki awọn fijilante naa to ya wọnu ile naa.

Ọpọ eeyan lo koro oju si iṣẹlẹ naa, ti wọn si bẹrẹ si bu ẹnu atẹ yii ati bi aabo ko se si fun awọn obinrin mọ.

Gbogbo ẹbẹ ti Agunbanirọ naa n bẹ wọn ni wọn ko dahun si, wọn ṣe e baṣubaṣu

Ninu fidio iṣẹlẹ yii, ikọ fijilante naa ja wọ ọgba awọn agunbanirọ to n sinru ilu nipinlẹ Anambra.

Ile awọn Agunbanirọ naa wa ni Oba, nijọba ibilẹ Guusu Idemili.

Ọmọbinrin Agunbanirọ to jọ pe wọn kọkọ pade ninu ọgba naa ni wọn si ṣina iya fun.

Wọn lu u, wọn ja a si ihooho, wọn si n ti i kiri laaarin ara wọn ki wọn too ti i sita gbangba.

Gbogbo ẹbẹ ti Agunbanirọ naa n bẹ wọn ni wọn ko dahun si, wọn ṣe e baṣubaṣu.

Bo tilẹ jẹ pe oṣu Keje ọdun yii ni iṣẹlẹ naa ti waye, aṣiri naa ko tete de etigbọọ awọn to le gbe igbesẹ lori rẹ.

Ninu oṣu Kẹjọ yii ti fidio naa tan kalẹ lo di ohun ti ijọba Anambra ṣiṣe le lori.

Pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí náà, ikọ̀ fijilanté Agunechemba ṣì ń ṣiṣẹ́ takuntakun - Gomina Soludo

Loju iwoye tirẹ, Gomina ipinlẹ Anambra, Ọjọgbọn Chukwuma Soludo, sọ pe ikọ fijilante Agunechemba ṣi n ṣe akọ iṣẹ lori aabo Anambra, bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ yii ti ọwọ wọn wa.

Gomina Soludo sọrọ yii lori eto kan nileeṣẹ tẹlifiṣan Arise, l'Ọjoruu.

"Awọn eeyan yii n ṣiṣẹ gidi gan-an lati ri i pe aabo wa fun wa, wọn si n wa bi alaafia yoo ṣe wa l'Anambra.

"Mo ro pe awọn araalu naa gba pẹlu mi pe wọn n ṣiṣẹ takun-takun lati ri i pe Anambra jẹ ọkan lara awọn orilẹede to ni alaafia ju ni Naijiria."

Bẹẹ ni Soludo wi.

O ni ohun to kan ṣe pataki ni lati jẹ ki wọn mọ ohun to jẹ ojuṣe wọn ati eyi ti wọn ko le ṣe.

Bakan naa lo fi kun un pe, awọn ikọ naa jẹ akọṣẹmọṣẹ, bẹẹ ni wọn si n gba idanilẹkọọ loorekoore bo ṣe yẹ.

A ti mọ àwọn tó ṣiṣẹ́ náà, iwadii ti bẹrẹ, a ko si ni i fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iṣẹlẹ ifiyajẹni - Ọlọ́pàá

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Anambra naa ti da si isẹlẹ ọhun.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ipinlẹ Anambra ṣe wi, wọn ni awọn ti mọ awọn to lọwọ ninu ifiyajẹni naa.

Wọn fi kun un pe ikọ fijilante Agunechemba lo huwa naa loṣu Keje.

Alukoro ọlọpaa Anambra, SP Tochukwu Ikenga, fidi eyi mulẹ ninu atẹjade rẹ.

O ni idi ti igbesẹ ko ṣe tete waye lori iṣẹlẹ yii ni pe obinrin ti wọn lu naa ko si nitosi.

Ikenga sọ pe iwadii ti bẹrẹ, awọn ko si ni i fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iṣẹlẹ ifiyajẹni.

Bakan naa ni ọlọpaa kilọ fun awọn ẹgbẹ fijilante lati ṣọra fun ifiyajẹni, ki wọn si ma ṣi agbara lo.