"Odù Ifá kìlọ̀ fún gómìnà Ademola Adeleke kò fi ọgbọ́n yanjú wàhálà ìjọba ìbílẹ̀ l‘Osun, kò ṣọ́ra gidi kó má ba à sọ ipò gómìnà nù"

Akori fun ọdun isẹse ti ọdun 2025 ni ìpínlẹ̀ Osun ni ‘Bi Ọọdẹ o dun, bíi igbẹ nilu n ri.’
Eleyi lo se afihan bi orílẹ̀èdè Naijiria ṣe ri lasiko yii.
Eekan kan lara awọn oníṣẹ̀ṣe nipinlẹ Osun, Oloye Ifagbenusola Atanda, to jẹ Asiwaju Awo Agbaye, ti fidi akori naa mulẹ pé, bi ile ko ba dun iluu ko le dùn, bi iluu ko ba dun ipinlẹ ko le dun ati pe, bi ipinlẹ ko ba dun orile-ede ko le dun.
Oloye Atanda, tun tẹsiwaju pe, ọpọlọpọ ile lo ti di ahoro latari bi ipinlẹ ati orile-ede ṣe ri lasiko yii.
Bẹẹ si ni ọpọ awọn ọlọmọge lo tí di aṣẹwo latari bi orile-ede ko ṣe rọrùn.
Ninu ohun ti ifa sọ fun ọdun isẹse ọdun 2025 yii ni pe, ki a mọ fi ẹran ikun sọ ẹran Agbonrin nu.
Gẹgẹ bii odu ifa ṣe sọ wi pe, ki Gomina Ademola Adeleke Ìpínlẹ̀ ọsun ko fi ọgbọ́n yanju wahala ọrọ ijọba ibilẹ ti o wa niwaju rẹ bayii.
Ifa tun tesiwaju pe, ki Gomina Ademola Adeleke ko sọra gidigidi ko mọ ba padanu ipo rẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ ọsun.
Ko si mọ le ẹran ikun ko mọ ba sọ ẹran agbonrin nu.

"Àwa oníṣẹ̀se kìí se pidánpidán, àwọn eléré itage ló sọ wá lórúkọ tí kìí se tiwa"
Awọn onisẹse ipinlẹ Kwara ti pariwo sita o, wọn ni awọn kii se pidanpidan, pe awọn elere ori itage ni wọn sọ awọn lorukọ ti kii se tawọn.
Wọn sọ eyi fun BBC Yoruba, lonii ogunjọ, oṣù kẹjọ bi wọn ṣe n se ayajọ ọdun iṣẹse jakejado agbaye.
Ni ilu Ilorin, Yeye Ajesikemi Omolara Olokun, sọ pe ẹṣin alaafia ni Isẹse, sugbọn awọn elere itage ati sinima agbelewo lo n fi ere wọn si awọn eeyan lọna nipa awọn.
O rọ awọn eeyan ki wọn ma ṣe tabuku awọn mọ, ki wọn si bu ọwọ fun awọn naa gẹgẹ bi wọn ṣe n se fun awọn ẹṣin yoku.

"Awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi ni wọn n lo awọn elere itage tako Isẹse"
Bakanna nilu Shao, Obarisa ipilẹ naa, Obalowu Omotayo Jagun, sọ pe awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi ni wọn lo awọn elere itage tako Isẹse.
O ni ṣe ni wọn n gbowo fun wọn lati ba Isẹse lorukọ jẹ.
O ni sugbọn gbogbo awọn to n se bẹẹ, ni wọn yoo kabamọ rẹ ni kopẹ kopẹ.
"Awọn elere itage to n se bẹẹ ko lẹbi, awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi ni wọn n gbe owo fun wọn lati ma fi bawa lorukọ jẹ.
"Sugbọn elere itage kan to ba tori tọrọ kọbọ tako orirun ẹ, yoo lẹhin, nitori Isẹse ni ipinlẹ gbogbo wa.
"Ko si oosa kan ti wọn n fi eeyan bọ, ẹni to ba ri ikan ko sọ sita, ẹṣin alaafia ni Isẹse.
Wọn rawọ ẹbẹ si ipinlẹ Kwara, pe ki jọwọ jare fun awọn onisẹse ni Kwara ni isinmi ni gbogbo ogunjọ oṣu kẹjọ, gẹgẹ bi awọn ijọba ṣe ṣe fhn awọn ilẹ Yoruba yoku.

"Ayẹyẹ ọdún Ìṣẹ̀ṣe, ìṣọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ló le gbé ẹ̀sìn ìbílẹ̀ lékè"
Ipinlẹ Oyo ko gbẹyin nínú ọdún Ìṣẹ̀ṣe pẹlu bii àwọn ẹlẹṣin abalaye jakejado Ipinlẹ naa ti kórajọpọ ninu gbagede papa ìṣere Lekan Salami Adamasigba to wa ní agbegbe Dugbe nilu Ibadan.
Lara awọn eto ti wọn ya sọtọ ni yiyan bi ológun ti awọn ijọ ati lẹgbẹ lẹgbẹ to jẹ ti awọn oniṣẹṣẹ kaakiri Ipinlẹ Oyo ṣe.
Ninu ọrọ rẹ Alagba Omikunle Egbelade tíì ṣe ààrẹ íṣẹṣe ti ilu Ibadan ṣalaye wi pe, awọn oniṣẹṣe jakejado ilẹ kaarọ oojire lo jẹ eeyan alafia.
O tẹsiwaju wi pe pẹlu bi ijọba ti yan ọjọ kan sọtọ lati ṣe ayajọ ọdun awọn oniṣẹṣe, eyi yoo mu ki wọn maa fi oju ọ̀tọ̀ wo awọn ẹlẹṣin abalaye.
Oloye Onifade Olanipekun to jẹ Asiwaju Awo ti Oyo wa pe fun Ìṣọ̀kan laarin awọn oniṣẹṣe jakejado agbaye.
Olanipekun ni ibaraẹnisọ̀rọ ati igbọraẹniye ṣe pataki ki igbalarugẹ le ba ẹṣin abalaye.
O rọ awọn ẹlẹ́ṣin ibillẹ lati ifowosowopo pẹlu awọn to jẹ olórí, to si pe fun ọgbọn atinuwa, ironilagbara ati lilo oye imọ ayelujara lati gbe ẹṣin abalaye lárugẹ.

Ipatẹ oniruuru Ade ti Ewi tilu Ado Ekiti máa n de, ko gbẹyin nibi ayẹyẹ ọdún Udiroko lásìkò àyájọ́ Ìṣẹ̀ṣe
Pọpọ sinsin Ayẹyẹ ọdun Udiroko ti gberasọ laafin Ọba Rufus Adejugbe, Aladesanmi kẹta , Ewi tilu Ado Ekiti.
Ọkan o jokan awọn ọmọ bibi ilu Ado Ekiti , l'ọkunrin l'obinrin, ọmọde ati agbalagba ni wọn ti wa nikalẹ.
Wọn wọ aṣọ alarambara ati ilẹkẹ ati bata to joju ni gbese sọrun, wọle sinu aafin naa ni kẹtikẹti.
Ipatẹ oniruuru Ade ti Ewi tilu Ado Ekiti máa n de ko gbẹyin nibi ayẹyẹ ọdún Udiroko naa to n waye lapa kan.

"Iṣẹṣe ni wọn fi tẹ ilẹ Yoruba do, ẹyin Yoruba, ẹ gbọdọ bọwọ fun Iṣẹṣe"
Awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ondo kora jọ si Adegbemile n'ilu Akure lati sajọyọ Ọdun Iṣẹṣe tọdun yii.
Awọn oniṣẹṣe yii darapọ mọ awọn ojugba wọn jakejado ilẹ kaaro-oojiirelati se ayajọ Isẹse.
Wọn wa sapejuwe ayajọ naa gẹgẹ bi ohun to pọn dandan lati se fun gbogbo ọmọ Yoruba, nitori Iṣẹṣe lagba.
Awọn oniṣẹṣe naa ti wọn pejọ si Adegbemile bẹrẹ iwọde kaakiri ilu Akure.
Iwọde naa gberasọ lati gbongan Adegbemile, ti wọn si gba Ọba Adesida, ki wọn to fi ori irin naa sọlẹ si Democracy Park, Ọja Ọba n'ilu Akure.
Ọpọ awọn oniṣẹṣe naa ti wọn n kọ orisirisi orin Iṣẹṣe, ni wọn satẹnumọ rẹ pe, Iṣẹṣe ni wọn fi tẹ ile Yoruba do, ti gbogbo awọn Yoruba si gbọdọ bọwọ fun Iṣẹṣe.

Gbogbo eto lo ti to fun ti ayẹyẹ ọdun iṣẹṣe ṣe n lọ kaakiri agbaye, paapaa lawọn ẹkun Iwọ-Oorun ilẹ Naijiria loni ogunjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2205.
Bi wọn ṣe n ṣayẹyẹ ọdun iṣẹṣe naa lawọn ipinlẹ bii Eko, Oyo, Osun, Ekiti, Kwara ati Ondo, naa ni wọn n ṣe e nipinlẹ Ogun.
Ijọba ipinlẹ Eko, Ogun, Osun ati Oyo ni wọn ti kede saaju pe isinmi lẹnu isẹ yoo wa lonii lati sami ọdun isẹse.
Awọn akọrin BBC News Yoruba si ti n lọ kaakiri lati maa mu iroyin wa fun yin nipa bi ọdun Isẹse se n lọ yika ilẹ Yoruba.

Awọn onisẹse ni ipinlẹ Ogun bọ Oke Olumọ ni ayajọ Isẹse, seto idije ere idaraya laarin ẹlẹsin Islam, Kristẹni ati Ibilẹ
Lara awọn alakalẹ eto gẹgẹ bi wọn ti ṣe maa n ṣe e lọdọọdun ni bibọ Oke Olumọ to wa niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti n ṣe iwure, eyi to waye lọjọ Iṣẹgun to kọja.
Eto naa tun gbọna ọtun yọ pẹlu bi idije ere idaraya ṣe waye laarin awọn ẹlẹsin mẹtẹẹta, iyẹn Ẹlẹsin ibilẹ, Kristẹni ati Isilaamu nipinlẹ Ogun.
Ayẹyẹ tọdun yii ti wọn pe akori rẹ ni "Titọju awọn ohun-ini ati awọn aṣa wa".
Bakan naa, ni oni ni idanilẹkọọ yoo waye fun gbogbo ọmọ Kaarọ-o-jiire nipa bi wọn ko ṣe nii sọ awọn ohun ajogunba wọn nu, ti aṣa ati iṣẹṣe ko si ni lọ soko igbagbe.
Ni bayii, gbogbo awọn oniṣẹṣe jakejado ipinlẹ Ogun, paapaa niluu Abẹokuta to fi mọ awọn alawọ funfun lati ilẹ Brazil, Portugal ati awọn miran, ni wọn ti wa ni Oke-Abọla to wa lagbegbe Kugba niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti maa n ṣe ọdun naa.
Bi ajọdun naa se n lọ nipinlẹ Ogun, laa maa mu wa fun yin.

Ki ni itumọ ayajọ ọjọ Isẹse?
Ìṣẹ̀ṣe Day jẹ ayajọ ọjọ asa ati ẹsin tawọn ọmọ Yoruba to n se ẹsin ibilẹ jake jado agbaye, maa n sami rẹ ni ọdọọdun.
Lara awọn orilẹede to maa n kopa ninu rẹ yatọ si awọn ipinlẹ to wa lẹyin iwọ oorun guusu Naijiria ni orilẹede Brazil, Portugal ati ilẹ olominira Benin.
Ọjọ Isẹse yii si ni wọn ya sọtọ lati bu ọla fun awọn orisa ati ẹsin ibilẹ lọna ati daabo bo asa ati ohun ajogunba iran Yoruba, ko maa ba parun.
Koda, awọn ipinlẹ kan nilẹ Yoruba bii ipinlẹ Eko, Osun, Oyo ati Ogun si ti ya Ogunjọ osu Kẹjọ ọdọọdun sọtọ gẹgẹ bi ayajọ ọjọ Isẹse.
Bakan naa, awọn ipinlẹ yii ti kede ọjọ Isẹse bii ọjọ isinmi lẹnu isẹ jake jado ipinlẹ koowa wọn.















